Lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án ogun abẹ́lẹ́ tó gbóná girigiri, ètò ìlera ní orílẹ̀-èdè Syria ò ṣe bẹ́ẹ̀ gbópọn mọ́. Ní àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìsàkóso Ààrẹ Bashar al-Assad, àwọn Aláṣẹ wọn ti tako ìṣẹ̀lẹ̀ àrun COVID-19.
Gẹ́gẹ́ bí Fáfitì John Hopkins ̣ti sọ, orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti sàwárí ìsẹ̀lẹ̀ 439 pẹ̀lú ikú ènìyàn 21 títí di ọjọ́ 15 osù Agẹmọ. Ṣùgbọ́n àwọn ìròyìn tí ó wà nílẹ̀ báyìí tí ṣe àfihàn bí ilẹ̀ náà ṣe takú wọnle tí wọ́n sì ń ṣẹ́ ìdánilójú pé àrùn COVID-19 wà lóòótọ́
Walid Abdullah ọmọ ọdún 23, sọ ọ́ di mímọ̀ pé ìlẹ̀ yìí tilè ṣe é débi pé wọ́n ń dába gbígba ẹ̀mí àwọn aláàárẹ̀ tí wọ́n bá funra sí pé wọ́n ní COVID-19. (Ohùn Àgbáyé ń lo orúkọkórúkọ láti dààbò bó.) Nínú ìtàkùrọsọ pẹ̀lú Ohùn Àgbáyé lórí aago, Abdullah ṣe é ní àlàyé pé ní ọjọ́ 13 ọsù Èbìbí, òun pé Ilé ìwòsàn Àpapọ̀ ti Dara'a ní ìha gúúsù ilẹ̀ Syria láti fi ìṣẹ̀lẹ̀ ààrun kòrónà kan tó wọn létí. Gẹ́gẹ́ bí Abdullah ṣe sọ, nígbà tí ó bèèrè ìgbésè tí ó yẹ ní gbígbé, òṣìṣẹ́ ìjọba tí ó gbé ìpè náà sọ pé “ Yìnbọn pà á, a kò ní ìwòsàn fún”
Ó yára fi òpin sí ìpè náà. Dájú, kò sí ọ̀rọ̀ nínú yíyin ìbọn pa ẹni tí a fura sí pé ó ní àrun COVID-19. Abdullah sọ fún Ohùn Àgbáyé pé “Ikú nípasẹ̀ COVID-19 sàn ju dídá ẹsẹ̀ wọ ilé ìwòsàn ìjọba lọ”
Èrí ìbanilọ́kanjẹ́ eléyìí tún kín in lẹ́yìn láti àwọn orísun mìíràn. Àtẹ̀jáde ọjọ́ 10 oṣù Ẹrénà kan ti The Voice of the Capital, ìwé ìròyìn Olómìnira kan ní ilẹ̀ Syria sọ di mímọ̀, pé àwọn elétò ìlera láti Ilé-iṣẹ́ Ètò Ìlera ilẹ̀ Syria sọ pé “iṣẹ́ ìmọ̀-ọ́n-mọ̀ṣekúpani ń wáyé ní ilé ìwòsàn ìjọba Al-Mujtahid ní olú ìlú ilẹ̀ náà, Damascus, fún àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé wọ́n ní ààrùn ọ̀hún ní tòótọ́, nípa fífún wọn ní àpọ̀jù oògùn tí ó máa ń rani níyè.”
Èyí pẹ̀lú fi ara hàn ní orí ìkànnì alátagbà:
معلومات أنه في سوريا يتم تصفيه مرضى كورونا في مشفى المجتهد بعد ساعات من تشخيص المرض…
— Qهارون (@Q56048602) March 11, 2020
Awuyewuye wí pé ní Syria, pípa ni wọ́n ń pa àwọn tí ó lu gúdẹ àrùn ọlọ́jẹ̀ korona ni ile-iwosan al-Mujtahid ni kété tí wọ́n kẹ́fin àrùn náà …
Ẹlòmìíràn láti ilé ìwòsàn Mouwasat ni Damascus ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún jẹ́ dídì mọ́ ọwọ́ nínú àtẹ̀jáde kan náà tí ó sọ pé “iṣẹ́ ìmọ̀-ọ́n-mọ̀ṣekúpani ń wáyé ní ibi kọ́lọ́fín pátápátá, àwọn dókìtà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìtọpinpin àrùn ọ̀hún ni wọ́n sì ń ṣe é.”
Ìgbésẹ̀ Sáà ìṣèjọba Assad sí ìdẹ́kun àrun COVID-19 yìí burú jáì, ó fi ara jọ ète tí wọ́n lò nígbà Ogun abẹ́lé Assad tí ó gba èmí ènìyàn tí ó lé díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún 586, tí ẹgbẹ̀rún 100 tí ó wà látìmọlé parẹ́ síbẹ̀, tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún 5.6 sì di ogunléndé káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè àgbááyé
Àwọn iléeṣẹ́ akọ̀ròyìn tí ó fẹ́ ti Assad náà wí bákan náà nínú ìkọ̀ròyìn wọn nípa àrùn ọlọ́jẹ̀ kòrónà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn náà, Firas al-Ahmad, tí ó jẹ́ àjábọ̀ ìròyìn ní ìkànnì amóhùnmáwòrán ti ìpínlẹ̀, Syrian News channel (al-Ikhbariyah Syria) ṣe àtẹ̀jáde kan tí ó dáyà já ‘ni sórí ojúewé Facebook rẹ̀ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn tí ó kọ̀ láti to t sílé lásìkò kónílégbélé:“وهلأ شو رأيكن بالحكي ضروري ننصب قناصات لتنضب الناس ببيوتا، لك افهمو يا ناس افهمو” في تهديد مباشر منه للناس للالتزام بمنازلهم بالقوة.”
“Ní báyìí kí ni ó tànmáàn [nípa èrò yìí]? Ǹjẹ́ a nílò láti kó àwọn ayìnbọnpani síta kí àwọn ènìyàn ó tó fìdìí mọ́lé wọn? Ẹ̀yineèèyàn ẹ lóye, ẹ lóye!”
Àtẹ̀jáde di píparẹ́, àmọ́ àwòrán rẹ̀ wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.
Ìbẹ́sílẹ̀ Àjàkálẹ̀ Ààrun àti Ìtèsíwájú Ìsèjọba
Sáà ìṣèjọba Assad yìí ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tí ó yí i ká sínú ìdààmú tí ó fi mọ́ orílẹ̀-èdè Iran náà, pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé ilẹ̀ Syria ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tí ó yí i ká fi ń mí.
Ní osù èrèlé, orílẹ̀-èdè Iran di ọ̀kan nínú àwọn orílè-èdè tí Covid-19 ti ṣọṣẹ́ jùlo, ìbi tí àrùn náà gbà wọ ilẹ̀ wọn ni ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ Lebanon, Iraq àti Syria, níbi tí ìfarayíra ti ṣelẹ̀ nípasẹ̀ àjọṣepọ̀ àwọn Ológun. Ní àfikún, àwọn Arìnrìnàjò-ẹ̀sin àti àwọn Arìnrìnàjò-ìgbafẹ́ láti Iran náà tẹ̀síwájú láti máa ṣe àbẹ̀wọ̀ sí àwọn ojúbọ ní Damascus títí di ọ̀ṣẹ̀ kíní osù Ẹrénà gẹ́gẹ́ bí Zaki Mechy tí ó jẹ́ ara àwọn Òǹkòwé March Study ti London School of Economics and Political Science (LSE) ṣe sọ.
Síbẹ̀, Ìṣèjọba Assad ń tẹpẹlẹ mọ́ sísọ òfegè ìròyìn àti irọ́ lórìṣirísi bẹ́ẹ̀ ni ó tún ṣe àdínkù iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ní COVID-19.
Ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka ìròyìn ìjọba ilẹ̀ Syria ní ọjọ́ 13 Osù Ẹrẹ́nà. Mínísítà ètò ilera ilẹ̀ náà Nizar Al-Yaziji kọ̀jálẹ̀ lórí pé kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ COVID-19 ní ilẹ̀ Syria, ó sọ pé “A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àwọn Ẹ̀ka Ológun ti fọ ilẹ̀ Syria mọ́ kúrò lọ́wọ́ àrùnkarùn:”
Mínísítà ètò ilera ilẹ̀ Syria kò tilẹ̀ kéde ìṣẹ̀lẹ̀ àrun COVID-19 àkọ́kọ́ ilẹ̀ náà títí di ọjọ́ kejìlélógún Osù Ẹrẹ́nà (March 22), èyí si ń fa ìbínú àti ìtutọ́sókè fojú gbà á ní àárín àwọn ọmọ ilẹ̀ Syria tí wọ́n ṣe àkíyèsí pé ìṣèjọba Assad ń parọ́, ó si ń tako ìròyìn ododo. Nínú ìwé àpilẹ̀kọ tí wọ́n fi sí orí ẹ̀rọ alátagbà-oníròyìn Syria 24 ní ilẹ̀ náà, ọ̀kan nínú àwọn ará ìlú fèsì sí ọ̀rọ̀ Yaziri, ó sọ pé “ṣé o kò sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo ààrun ni ó ti jẹ́ fífọ̀ kúrò ni?”
Síbẹ̀ náà ìṣèjọba yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí ní sí ṣe àdíkù òǹkà iye àwọn tí wọ́n ní àrun náà nínú àtẹ̀jáde wọn.
Nínú àtẹjáde kan tí ọjọ́ kíní osù Igbe (April 1) Àjọ tí ó pè fún àtúnṣe ìṣejọba àti àwọn ẹgbẹ́ alátakò késí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé láti fíná mọ́ ìṣejọba ọ̀hún, pé kí wọn ó gbé òótọ́ òǹkà iye àwọn tí wọ́n ní àrun náà jáde.
Ó gbé èrò rẹ̀ jáde lórí iye tí ó yẹ kí ó jẹ́ òótọ́. Ó kọ báyìí pé:
” إن المعلومات الميدانية التي تصلنا، تؤكد تفشي الفيروس بأعداد هائلة، بحيث بات من الصعب السيطرة على هذا الوباء”
Ohun tí a rí gbọ́ ni wí pé àrùn ọlọ́jẹ̀ náà ń jà rọ̀ìnrọ̀ìn, tí ó sì nira láti kápa àjàkálẹ̀ náà.
Ètò ilera tí ó ti dẹnu kọlẹ̀
Gbígbà pé àjàkálẹ̀ ààrun yìí wà lóòótọ́ bu ìsejọba Assad kù nítorí pé òhun ni yóò jẹ́ kí àwọn aláṣe wọn ó fi tipá gbà lóòtọ́ pé wọn kò ní èka ètò ìlera.
Gẹ́gẹ́ bí London School of Economics and Political Science (LSE) ṣe sọ, àpapọ̀ iye àwọn aláàárẹ̀ COVID-19 tí wọ́n le wò ní ilẹ̀ náà kò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ààbọ̀ lọ (6500) nínú ọ̀gọ̀rọ̀ èníyán tí ó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún àbọ̀ (17.5 million) tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Ó ní bí iye àwọn aláàrẹ́ bá ti ju iye yìí lọ, ipá orílè-èdè náà ti pin nìyẹn, omi sì le tẹ̀yìn wọ̀gbín lẹ́nu.
Ní àsìkò ogun abélé náà, àwọn ológun ti ṣe ìkọlù tí ó lágbára sí ẹ̀ka ètò ìlera wọn. Àkọsílẹ̀ láti ọdọ̀ Àjọ́ WHO àti Ilé-iṣẹ́ ètò ilera ilẹ̀ Syria sọ ọ́ di mímọ̀ pé méjìdínlọ́gọ́ta (58) nìkan ni ètò iṣẹ́ rẹ̀ pé nínú ilé ìwòsàn ìjọba ọ̀kànléláàádọ́fà (111) tí ó wà ní ilẹ̀ náà.
Àkọsílẹ̀ yìí tún fi hàn pé ó tó ìdá àádọ́rin (70) nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ilẹ̀ náà tí wọ́n ti kúrò láti di àtìpó àti ogúnléndé sí ilẹ̀ ibòmìíràn.
تقرير حقوقي: نظام الأسد قتل 669 من الكوادر الطبية بينهم 83 قضوا بسبب التعذيبhttps://t.co/sXWWtjrdVs#سوريا #روسيا #PYD pic.twitter.com/DOkV2kGsIP
— الائتلاف الوطني السوري (@SyrianCoalition) May 9, 2020
Àtẹ̀jáde Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn: òṣìṣẹ́ elétò ìlera 669 ni ó kú ní sáà Assad, pẹ̀lú àwọn 83 tí ó gbẹ́mìí mì látàrí ìjìyà oró.
COVID-19 nínú àjálù tí ó ń kujú ọmọnìyàn
Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé ohun tí ó jẹ́ ìdojúkọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Syria jùlọ ni bí àwọn àjálù yìí ṣe rọ́ lu ara wọn; ogun, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn. Àjọ Ìsọ̀kan Àgbáyé ṣe ìkìlọ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n osù Okudù (june 26) pé Syria ń fojú winá eebi àpafẹ́ẹ̀ẹ́kú, ìgbẹ́sẹ̀ níkíá sì nílò láti dèènà ìtànkálẹ̀ COVID-19.
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Elétò Ounjẹ Àgbáyé ṣe sọ, òwọ́ngọ́gọ́ bá ounjẹ pẹ̀lú ìdá mọ́kànlá (11) iye rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní oṣù Èbìbí (May) yàtọ̀ sí ti oṣù Igbe (April), ó sì wọ́n sí i ní ìwọ̀n mẹ́tàléláàádóje (133%) nígbà tí wọ́n gbé e wò sí ti ọdun 2019. Iléeṣẹ́ Àjọ Ìsọ̀kan Àgbáyé tí ó ń rí sí Ìsètò Ọ̀ràn Ọmọnìyàn (OCHA) fi ìdí ìsẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ ní ọjọ́ 12 osù Okudù:
#سوريا :
?نقص في معدات الحماية الشخصية
?أزمة جوع لا مثيل لها
?جيل جديد لا يعرف إلا الدمار والحرمان
?ونقص كبير في التمويل..-اقرأ ما صرحت به الوكالات الأممية عن الوضع الإنساني في سوريا?@WFP_Syria @WFP_MENA @UNOCHA_ar @OCHA_Syria @WHOSyria https://t.co/8HxfcXxVNx
— أخبار الأمم المتحدة (@UNNewsArabic) June 29, 2020
Àìsí ohun-èlò ààbò fún ènìyàn. Iyàn tí ó kọjá bẹ́ẹ̀. Ìran òde òní kò mọ ohun mìíràn bíkòṣe ìparun àti ìfẹ̀tọ́dunni. Owó kò tó. Ka ohun tí àjo UN sọ nípa bí ọ̀ràn ọmọnìyàn ṣe wà ní Syria.
Gẹ́gẹ́ bí ètò ọrọ̀ ajẹ́ wọ́n ṣe dẹnukọlẹ̀. Ali al-Ahmed ọmọ ọdún 28 (orúkọkórúkọ ni èyí náà, gẹ́gẹ́ bí ẹni yìí ṣe bèèrè fún ìdáàbòbò orúkọ rẹ̀) láti ìlu Daraa sọ fún Ohùn Àgbáyé ní orí aago pé “nǹkan burú jáì, kò sí irú iṣẹ́ tí o lè ṣe, kódà kí wọn ó máa san ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá 10,000 SYP owó ilẹ̀ Syria [láàrin Dọ́là $1 kan sí márùn-ún $5 USD] fún ènìyàn, kò le tóó ná” Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn erù ni àwọn ènìyàn ti kọ̀ sílẹ̀ láìgbà látàri ọ̀wọ́ngógó owó ìgbẹrù.
Lásìkò tí ètò ìlera wọn ti dẹnikọlẹ̀ yìí látàrí ewu ogun tí ó wu wọ́n tí ètò ọ̀rọ̀ ajé tí ó forí sánpọ́n sì ti sọ ọ̀pọ̀ ọmọ ilè Syria di Akúṣẹ̀ẹ́, Àjàkálẹ̀ ààrùn tí ò jà kiri yìí tún ti ti ìlú yìí sínú ewu àìkàsí àti ìdibàjẹ́.