Olóyè yìí nírètí wí pé àwọn ọmọ Yorùbá yóò tẹ́wọ́ gba ‘alífábẹ́ẹ̀tì t'ó ń sọ̀rọ̀’ tí òun hu ìmọ̀ rẹ̀

Olóyè Tolúlàṣẹ Ògúntósìn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba ilẹ̀-Yorùbá káàfàtà, Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀, lórí ìjókòó. Olóyè Ògúntósìn ló yànda àwòrán.

Lẹ́yìn ìpolongo kárí ayé nípa Ọdún Èdè Ìbílẹ̀ Àgbáyé ní ọdún 2019 àti ìkéde Ọdún mẹ́wàá Èdè Ìbílẹ̀ Àgbáyé 2022-2032, púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àkànṣe iṣẹ́ tó ní ṣe pẹ̀lú ìdàgbàsókè àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀.

Lílo àyálò ìlànà Látíìnì fún kíkọ èdè Yorùbá yóò di àfìsẹ́yìn tí eégún aláré ń fiṣọ láì pẹ́ ní èyí tí ọmọ Káàárọ̀-o-ò-jí-ire kan, Olóyè Tolúlàṣẹ Ògúntósìn, ẹni tí ó ń gbé ní Ilẹ̀ Olómìnira Bẹ̀nẹ̀, Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀, ti hu ìmọ̀ ìlànà tí a ó máa lò fún kíkọ èdè Yorùbá.

Alífábẹ́ẹ̀tì Yorùbá tuntun náà ti ń gbàlú kan pẹ̀lú ìrètí wí pé yóò pààrọ ti Látíìnì tí ó ti jẹ́ lílò fún ọgọ́rùn-ún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Ògúntósìn ti ṣe rò fún Ohùn Àgbáyé nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí WhatsApp, ojú àlá ni alífábẹ́ẹ̀tì àràmàndà wọ̀nyí ti f'ara hàn sí òun. Ní báyìí, níṣe ni ó máa ń ṣe ìrìnàjò jákèjádò Ilẹ̀-Yorùbá — láti Bẹ̀nẹ̀ títí dé Nàìjíríà — láti polongo “alífábẹ́ẹ̀tì tí ó ń sọ̀rọ̀” rẹ̀ bí àwọn alálẹ̀ ti ṣe fi rán an.

Olóyè Ògúntósìn nígbàgbọ́ wí pé Odùduwà, tí ó jẹ́ bàbá-ńlá ìran Yorùbá lo alífábẹ́ẹ̀tì náà ní ayé àtijọ́ — àmọ́ ó ti di ohun ìgbàgbé. 25 ni gbogbo àwọn àmì wọ̀nyí lápapọ̀.

Àwọn onímọ̀ nípa èdè ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ sọ wí pé kí ìlọsíwájú ó tó dé bá Ilẹ̀ Adúláwọ̀, ó pọn dandan kí ó ní ìlànà ìṣọwọ́ kọ èdè tàbí ìlànà kíkọ tí ó jẹ́ tirẹ̀. Èdè tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí Niger-Congo tí ó jẹ́ èdè ìran tí ó ti wà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ tí ó sì lajú bí èdè Yorùbá ò gbọdọ̀ gbọ́kàn tẹ ìlànà àyálò fún kíkọ èrò àti ìmọ̀ ìrírí ayé rẹ̀.

Ní ọdún 1843, Àlùfáà Sámúẹ́lì Àjàyí Crowther òṣìṣẹ́ Ẹgbẹ́ Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ (CMS) ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà ìṣọwọ́kọ èdè Yorùbá nípa yíya ìlànà Látíìnì lò pẹ̀lú àfikún àwọn àmì ohùn — tàbí àmì ìró ọ̀rọ̀. Láti ìgbà náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé ti jẹ́ títẹ̀ jáde ní èdè Yorùbá nípasẹ̀ lílo ìlànà kíkọ Látíìnì dípò Ajami, tí í ṣe ìlànà ìṣọwọ́kọ Lárúbáwá tí ó ti jẹ́ lílò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́ rí fún kíkọ èdè Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀ bí i èdè Yorùbá àti Haúsá kí ó tó di 1843.

Àwọn alágbàwí èdè gbà wí pé lílo ìlànà Látíìnì, tí ó jẹ́ ìṣọwọ́kọ láti ilẹ̀ òkèèrè, fún kíkọ àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ sílẹ̀, fi ilẹ̀ náà sínú ipò ẹrú.

Ìpolongo ìlànà ìṣọwọ́kọ tuntun yìí wáyé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìṣọwọ́kọ ayébáyé Ilẹ̀-Adúláwọ̀, bí i hieroglyphics ti Íjípìtì, Àkójọ Adrinka ti ìran Akan ní Ghana, Ge'ez ti Ethiopia, ìṣọwọ́kọ ìyàwòrán Nsibidi ti Àárín Gbùngbùn Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀ tí ó ti wà fún bí 5000 ọdún k'á tó bí Jésù, àti alífábẹ́ẹ̀tì Vai ni Ilẹ̀-Adúláwọ̀ jẹ́ orísun wọn.

Ìṣàyèwò ‘alífábẹ́ẹ̀tì tó ń sọ̀rọ̀’

Alákòóso Ohùn Àgbáyé lédè Yorùbá, Ọmọ Yoòbá fi ọ̀rọ̀ wá Olóyè Ògúntósìn lẹ́nu wò, nípasẹ̀ iṣẹ́-ìjẹ́ ohùn lórí ẹ̀rọ iìtàkùrọ̀sọ WhatsApp, láti mọ̀ sí i nípa bí ó ti ṣe rí alífábẹ́ẹ̀tì tuntun yìí.

Olóyè Ògúntósìn, tó jẹ́ ọmọ ọdún 43 báyìí, ṣàlàyé wí pé òun kò lè ka ju ilé gíga lọ lẹ́yìn ìpapòdà bàbá òun ní ọdún 1997, tí òun sì ní láti ṣe ojúṣe bí bàbá gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí láti tọ́jú àwọn àbúrò rẹ̀.

Síbẹ̀, bí olóyè Yorùbá tí ó jẹ́, iṣẹ́ ìgbélárugẹ àṣà rẹ̀ dá lórí ìṣọ̀kan àwọn ọmọ Odùduwà jẹ́ ohun tí ó gbé e lọ́kàn gidi gan-an, tí ó sì ń ṣe bí olùlàjà láàárín wọn.  Bí iṣẹ́ ìgbélárugẹ àṣà yìí ṣe ń gbòòrò sí i, kò tẹ́ ẹ lọ́rùn tó bí ó ṣe fẹ́.

Lọ́dún 2011, ó fi eéjì kún eéjì, ó fi ẹẹ́ta kún ẹẹ̀ta, ó gba oko aláwo lọ. Babaláwo náà, Olókun Awópẹ̀tu, wí fún un pé kí ó lọ sí ojúbọ ìdílé rẹ̀ tí ó wà ní agbègbè Farasìnmí ní Àgbádárìgì (Badagry), Ìpínlẹ̀ Èkó, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, wí pé yóò rí atọ́nà tí yóò tọ́ka sí ohun tí Elédùmarè rán an wá ṣe láyé ní ojúbọ náà.

Ní ojúbọ náà, ó rí “nǹkan àjèjì” kan tí ó mú padà sí ilé rẹ̀ ní Porto-Novo, Bẹ̀nẹ̀. Nígbà tí ó délé, òkùnkùn bo iyàrá birimùbirimù. Kò sí iná amọ́roro nínú yàrá ìgbàlejò, ìmọ́lẹ̀ ìtànṣán ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán ni ó máa ń fi ríran. Ó gbé nǹkan àjèjì náà sí orí àga ìgbénǹkanlé, ó sì tan ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán, kàyéfì ló jẹ́ fún un, ohun tí ó gbé sórí àga di àwátì. Ó tú gbogbo ilé kí ó tó wá rí i ní kọ̀rọ̀ ilé.

Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó fi nǹkan àjèjì náà sábẹ́ ìgbèrí sùn. Ó sọ fún Ohùn Àgbáyé:

… Mo lálàá wí pé mo lọ sí inú oòrùn. Nígbà tí mo débẹ̀, ó òkùnkùn ṣú bolẹ̀, a sì fi alífábẹ́ẹ̀tì náà hàn mí ní àpẹẹrẹ ìmọ́lẹ̀. Ìgbàkúùgbà tí mo bá sùn, àlá yìí kan náà ni ní ọ̀nà àrà, mò ń lọ láti agbègbè kan sí agbègbè mìíràn, tí mo sì ń kọ́ àwọn ènìyàn bí a ti ṣe ń lo ìṣọwọ́kọ tuntun náà…

Fún ọdún mẹ́ta, kò yé lálàá nípa alífábẹ́ẹ̀tì náà, kò yé ríran léraléra, síbẹ̀ kò ṣe nǹkankan sí i.

Lásìkò yìí, ní ọdún 2016, mo tún lọ sí inú oòrùn, mo ṣalábàápàdé ọkùnrin kan, Lámúrúdu, tí ó kọ́ mi ní ìró alífábẹ́ẹ̀tì náà, tí ó sì pa á láṣẹ fún mi pé kí tan ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ kíkọ àti kíkà àmì ìṣọwọ́kọ̀ náà kárí ayé. Mo máa ń jọ arúgbó lójú àlá — tí yóò sì rẹ̀ mí — bí mo bá jí lójú oorun.

Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí ní di ẹ̀rù fún Olóyè Ògúntósìn —  ó ń rẹ̀ ẹ́ látinú wá, ó wí fún Ohùn Àgbáyé.  Ó pinnu láti rọ́ àwọn àlá náà fún Oníkòyí, Alájàṣẹ́ ti Àjàṣẹ́ ní Port-Novo, ẹni tí ó là á lóye pé kí ó ṣe bí a ti pa á láṣẹ lójú àlá.

Látàrí ìdí èyí, ó ń ṣe ìrìnàjò láti agbègbè kan dé òmíràn ní Ilẹ̀-Yorùbá láti tan ìmọ̀ alífábẹ́ẹ̀tì Odùduwà náà.

Àwòrán-àtohùn àwọn olùkọ́ni tí ó kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí a ti ṣe ń kọ alífábẹ́ẹ̀tì Odùduwà ní yàrá-ìgbẹ̀kọ́ kan ní Bẹ̀nẹ̀:

Ìgbélárugẹ alífábẹ́ẹ̀tì Yorùbá náà

Lọ́dún 2017, Olóyè Ògúntósìn, pẹ̀lú àwọn ọba Aláṣẹ igbá-kejì òrìṣà Ilẹ̀-Yorùbá nílé àti lẹ́yìn odi, ṣe àbẹ̀wó to sí Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá, ẹni tí ó fi ìgbà kan rí jẹ́ alákòóso Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní olú ìpínlẹ̀ náà th Òṣogbo, e one- èdè Nàìjíríà, láti béèrè fún àtìlẹ́yìn fún alífábẹ́ẹ̀tì Odùduwà tuntun náà. Arẹ́gbẹ́ṣọlá ni Mínísítà fún Ètò Abélé fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní sáà ti a wà yìí.

Ìwé tí a kọ ránṣẹ́ sí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ìrántí àwọn ìpinnu kíkọ́ alífábẹ́ẹ̀tì tuntun náà tí kò tíì wá sí ìmúṣẹ.

Ọdún mẹ́ta ti lọ, ó bani lọ́kàn jẹ́, ìlérí tí gómìnà àná Arẹ́gbẹ́ṣọlá ṣe láti rí dájú wí pé alífábẹ́ẹ̀tì tuntun náà jẹ́ kíkọ́ ni àwọn iléèwé tí ó ń bẹ ní Ìwọ̀-oòrùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà kò tíì di múmú ṣẹ.

Lójúnà kí alífábẹ́ẹ̀tì Odùduwà náà ó ba di ìlúmọ̀ọ́ká, Olóyè Ògúntósìn ti kọ ìwé kan, ó sì ti ká àwòrán-àtohùn alálàyé kan tí ó tú pẹrẹpẹ́ẹ̀rẹ̀ ìṣọwọ́kọ alífábẹ́ẹ̀tì tuntun náà sílẹ̀ — fún mùtúmùwà láti wò ní abalaabala lórí ayélujára — bákan náà ni ẹ̀patìrì iṣẹ́ akọ́nilọ́gbọ́n kàtúùnù fún àwọn èwe tí kò s'ówó láti parí i rẹ̀ náà ò gbẹ́yìn.

Olóyè Ògúntósìn ń lo gbàgbé YouTube, WhatsApp àti Ẹgbẹ́ orí Facebook: “Ẹ̀kọ́ Aèébáèjìogbè Odùduwà” àti “Alífábẹ́ẹ̀tì Odùduwà” fi ṣe ìgbélárugẹ àti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó nífẹ̀ẹ́ sí kíkọ́ ìlànà ìṣọwọ́kọ náà.

Ó rọ gbogbo ẹni tí ọ̀ràn kan láti dìde sí ti ìgbélárugẹ àwárí tí yóò gbá ìlànà ìṣọwọ́kọ Àmúnisìn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ tí yóò sì fún ìran Yorùbá ní ìdánimọ̀ tí ó tọ́ tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìdàgbàsókè èdè.

Ọkùnrin onínúure kan, Sunday Adéníyì, ṣe agbátẹrù ìtẹ̀jáde 1,000 ẹ̀da ìwé ìgbẹ̀kọ́ “Alífábẹ́ẹ̀tì Aèébáèjìogbè Odùduwà” fún àwọn ọmọ iléèwé alákọ̀ọ̀bẹ̀rẹ̀.

Ẹ̀da ìwé ẹ̀kọ́ alífábẹ́ẹ̀tì náà wà ní èdè Igbo, Hausa, English, àti Faransé lẹ́sẹẹsẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, àtìlẹ́yìn kì í pọ̀ jù fún ìpínkárí alífábẹ́ẹ̀tì náà.

Ìgbésẹ̀ tí ó mú ìwúrí dání ni alífábẹ́ẹ̀tì Odùduwà náà. Ṣùgbọ́n, sísún láti ìlànà Látíìnì sí ìlànà tuntun ni yóò mú ìpèníjà ńlá lọ́wọ́.

Kò jẹ́ bó ṣe jẹ́, ohun tí yóò mú ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè bá èdè Yorùbá ni alífábẹ́ẹ̀tì Odùduwà — ohun tí ìran Yorùbá yóò pè ni tiwa-ń-tiwa.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.