Ìrìn-àjò: Ìpẹ̀kun eré-ìdárayá fún Ọmọ-adúláwọ̀

Àwòràn olójìjì láti ọwọ́ọ Natasha Sinegina (CC BY-SA 4.0). Àwòrán ojú-ewé ìwé ìrìnnà látọwọ́ọ Jon Evans (CC BY 2.0). Àtúntò àwòrán-an látọwọ́ọ Georgia Popplewell.

Ní ọdún-un 2019, a kò fún Tèmítáyọ̀ Ọlọ́finlúà, òǹkọ̀wé àti ọ̀mọ̀wé ọmọbíbí orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, ní ìwé ìrìnnà láti lọ sí Àpérò Lórí Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní Éróòpù tí ó wáyé ní Edinburgh, UK. Ìgbìmọ̀ Àgbà Sórílẹ̀-èdè Britain ní Nàìjíríà sọ wípé àwọn kò “sí àrídájú” tí ó tẹ̀ àwọn lọ́rùn wípé Ọlọ́finlúà yóò fi UK sílẹ̀ lẹ́yìn tí ètó bá parí.

Òtítọ́ ni pé: Ó ti sú mi.

Ilé-iṣẹ́ UK Nílé pe àìfúni ní ìwé ìrìnnà náà padà. Ọlọ́finlúà lọ, ó bọ̀ padà sí Nàìjíríà, kò b'ọmọ jẹ́.

Àwọn mìíràn kò rí àǹfààní báyìí. Nínúu oṣùu Igbe ọdún-un 2019, àwọn aláṣẹ ìwé ìrìnnà UK kò jẹ́ kí ọmọ adúláwọ̀ 24 nínúu àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ 25 tí ó ń ṣiṣẹ́ lóríi àrùn àkóràn ó darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ẹ wọn níbi àpérò London School of Economics Africa Summit. Àwọn onímọ̀ tí wọ́n lakakì tí wọ́n sì ní ìmọ̀ pípé láti kojúu àrùn tí ó ń bá ilẹ̀ adúláwọ̀ fínra, kò rí ìwé ìrìnnà tí yóò mú wọn kópa nínúu àpérò nípa “ìpèníjà ìpọnmisílẹ̀-de-oǹgbẹ àjàkálẹ̀ àrùn” gbà.

Ètò àpérò LSE Ilẹ̀ adúláwọ̀ kò ní wáyé ní London àmọ́ yóò wáyé ní Belgium nítorí ó rọrun fún Ọmọ-adúláwọ̀ láti rí ìwé ìrìnnà gbà wọ̀lú, àti nítorí pé ọ̀pọ̀ Ọmọ-adúláwọ̀ kò fẹ́ẹ́ ṣe wàhálà asán láti ṣe ìbéèrè fún ìwé ìrìnnà. https://t.co/Q3WfiHS7Ja

‘O kò ní padà!’

Kékeré nìkan kọ́ ni ìdójútì tí àìfàyègba Ọmọ-adúláwọ̀ láti wọ àwọn illú kan ń mú dání — bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń tọ́ka sí ìgbékalẹ̀ ẹlẹ́yàmẹyà tí ó ń ṣe àtillẹ́yìn fún ìgbàgbọ́ wípé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ Ọmọ-adúláwọ̀ àti alátinúdá ò ṣe é fi ọkàn tàn lọ títí ni ti ìbọ̀wọ̀ fún òfín dé.

Abala13 ti Ìkéde Káríayé Fún È̩Tó̩ O̩mo̩nìyàn wípé “E̩nì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti kúrò lórìlẹ̀‐èdè yòówù kó jẹ́, tó fi mọ́ orílẹ̀‐èdè tirẹ̀, kí ó sì tún padà sí orílẹ̀‐èdè tirẹ̀ nígbà tó bá wù ú.” Òtítọ́ ibẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀, bí kò bá sí ìwé-àṣẹ-ọmọìlú-fún-ìrìnnà àti ìwé ìrìnnà tí ó wúlò, kò rọrùn láti lò. Ìrọ̀rùn ni ìbéèrè fún ìwé ìrìnnà ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, kò sì rí bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀-èdè mìíràn. Ní oríi 2019 Henley Passport Index, Japan àti Singapore ni orílẹ̀-èdè tí ó rọrùn fún jù lọ láti ríwèé gbà wọ̀lú oríṣìíríṣi, nígbàtí Angola, Egypt àti Haiti wà ní ìsàlẹ̀.

Òǹkọ̀wée ọmọbíbíi Kenya Ciku Kimeria ṣe àlàyé gbígbé láìsí iyì “ẹ̀tọ́ sí ìwé-ẹ̀rí-ọmọìlú-fún-ìrìnnà”. Obìnrin náà sọ wípé ìwé ìrìnnà nìkan kò gbé ènìyàn wọ orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí pé “o ní láti dáhùn àwọn ìbéèrè bíi, ‘Kí ló wa síbí wá ṣe?” tí àwọn òṣìṣẹ́ ibodè yóò béèrè, bí èsì ìbéèrè kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn, arìnrìn-àjó lè bá ara rẹ̀ ní ẹnu ìloro àlọ.

A ní láti wá nǹkan ṣe sí ti ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú yìí. Àsìkó ti tó láti sọ̀rọ̀ nípa bù fún mi kí n bù fún ọ #visareciprocity. Bí o bá lo òfin yìí fún àwọn ọmọbíbí orílẹ̀-èdè Uganda ti ó ń ṣe ìrìnàjò lọ sí òkè òkun. Ó yẹ ki òfin yìí ó de àjòjì tí ó fẹ wọ Uganda náà. Ó ti tó gẹ́. Ilẹ̀-Adúláwọ̀, àsìkó ti tó fún wa láti gbé àwọn ohun tí a máa ń béèrè bí a bá fẹ gba ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú ara wa tì pic.twitter.com/aiX0tsALSe

Fún àwọn Ọmọ-adúláwọ̀ tí ó fẹ́ ṣe ìrìnàjò jáde lọ sí orílẹ̀-èdè tí kìí ṣe ti adúláwọ̀, ìbéèrè fún ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú máa ń dà bíi ṣíṣe ẹbọ fún òòṣà tí ebi ń pa. Adéṣínà Ayẹni (Ọmọ Yoòbá), alákòóso Ohùn Àgbáyé ní èdèe Yorùbá, sọ ìríríi rẹ̀ nígbà tí ó ṣe ìbéèrè fún ìwé ìrìnnà ìwọ̀lúu Lisbon, Portugal, fún àpéròo àwọn alátinúdá 2019 Creative Commons Summit:

It was the greatest news of my life when I received a mail to deliver a keynote address at the 2019 CC Summit in Lisbon. . . . On April 18, 2019, some days to my birthday, I submitted my visa application to attend the Lisbon summit at the VFS Global office in Lekki, Lagos. The summit was slated for May 9-11, 2019, but visa processing takes a minimum 15 days.

On the day I was to depart for Portugal, I still [hadn’t] received my passport. . . . 11 days after the summit elapsed, I received a text from the VFS for collection of my passport. My people say, inú dídùn l’ó ń mú orí yá (you cannot be at your best when sad). It is one thing that I was not given a visa to attend the summit, another is that the huge scholarship grant to attend the summit went down the drain, wasted. I am miserable because I have not been able to refund the scholarship due to the Central Bank of Nigeria’s policy on wire transfers. It is excruciatingly painful that my right to associate as a free citizen of the global village was violated. I was stripped of my voice!

Ìdùnnù ǹlá gba ọkàn-an mi nígbà tí mo gba ìròyìn tẹl mí lọ́wọ́ wípé n ó máa sọ̀rọ̀ àkórí ètò níbi Àpérò CC ọdún-un 2019 ní Lisbon. . . . Lọ́jọ́ 18 oṣù Igbe, 2019, ọjọ́ díẹ̀ sí àyájọ́ ọjọ́ ìbíì mi, mo kó àwọn ohun tí wọn béèrè fún ìwé ìrìnnà láti wọ̀lúu Lisbon ki n ba kópa nínúu àpérò náà sílẹ̀ ní ilé-iṣẹ́ẹ VFS Global ní ìdádò Lekki, ní Èkó. Ọjọ́ 9 sí 11 ọdún-un 2019 ni àpérò náà ṣùgbọ́n ọjọ́ márùnúndínlógún ni yó gbà fún ìwé ìrìnnà láti jáde fún gbígbà. 

Lọ́jọ́ tí ó yẹ kí n kúrò nílé fún Portugal, n kòì tí ì rí ìwé-ẹ̀rí-ọmọìlú-fún-ìrìnnà mi gbà padà. . . . ọjọ́ mọ́kànlá lẹ́yìn tí àpérò ti di àfìsẹ́yìn ti eégún aláré ń fiṣọ, mo gba iṣẹ́-ìjẹ́ kí n wá gba ìwé-ẹ̀rí-ọmọìlú-fún-ìrìnnà mi ní VFS. Awọn àgbá bọ̀, inú dídùn l’ó ń mú orí yá. Ìṣòro kan ni ti àìrí ìwé ìrìnnà gbà, òmíràn ni ti owó ìrìnàjò ọ̀fẹ́ gọbọi tí ó wọlẹ̀ nítori n kò le è lọ si àpérò. Ìbànújẹ́ gba ọkàn mi poo látàríi àlàálẹ̀ Ilé-Ìfowópamọ́ Àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò mú ìfowó ránṣẹ́ sí òkè òkun rọrùn; n kò le è dá owó ìrìnàjò ọ̀fẹ́ tí ó pọn dandan láti dá padà padà fún àwọn tí ó ni owó. Ó dùn mí wọ akínyẹmí ara wípé wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ọ mi gẹ́gẹ́ bí olómìnira láti darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ẹ̀ mi. Wọ́n pa ohùn mọ́ mi lẹ́nu! 

ṣòro: Fún àwọn Ọmọ-adúláwọ̀ tí ó ń ṣe ìrìnàjò nínúu Ilẹ̀-adúláwọ̀

ṣòro fún ọmọ-adúláwọ̀ láti ṣe ìrìnàjò jáde kúrò ní Ilẹ̀-adúláwọ̀ — ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ náà ni ó nira láti ṣe ìrìnàjò nílẹ̀ náà. Àwọn ọmọ onílùú àìmọye orílẹ̀-èdè tí ó wà ní Àríwá àgbáńlá ayé lè ṣe ìrìnàjò lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀-adúláwọ̀  láì ní ìwé ìrìnnà, tàbí pẹ̀lú hìhámọ́ tí ò tó nǹkan, àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọmọ-adúláwọ̀ ni ó nílòo ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú láti ṣe ìrìnàjò sí ìdajì àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù.

Aládàásí Ohùn Àgbáyé ọmọbíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Rosemary Àjàyí ṣe àpèjúwe “ìlàkàkà àwọn ọmọ-adúláwọ̀ tí ó ń ṣe ìrìnàjò ní àárín ilẹ̀-adúláwọ̀”:

I am happy that we, and many others, are highlighting the challenges Africans face getting Western visas. This doesn't annoy me as much as the struggles of Africans travelling within Africa. At RightsCon in Tunis, and GlobalFact in Cape Town, I took the time to ask Africans if they had needed visas. Just this weekend, I learnt of a Nigerian journalist who was unable to attend GlobalFact because he didn't have a visa. Let's not talk about how most of the African delegates at RightsCon had to fly out of Africa first, in order to get to Tunis. Last month, I met an East African journalist applying for a visa to Nigeria. He was asked to supply the driver's license of the professional driver picking him up from the airport!

Inúu mi dùn nítotí wípé à ń gbé ọ̀ràn ohun tí ojú àwọn ọmọ-adúláwọ̀ máa ń rí ní wọ́n bá béèrè fún ìwé ìrìnnà wọ Orílẹ̀-èdè òyìnbó àti ohun ti ó tan mọ́ ọn yè wò. Èyí kò gbé mi lọ́kàn bíi ti ìlàkàkà àwọn ọmọ-adúláwọ̀ tí ó ń ṣe ìrìnàjò nínúu ilẹ̀-adúláwọ̀. Ní RightsCon tí ó wáyé ní Tunis, àti GlobalFact tí ó wáyé ní Cape Town, mo bi àwọn Ọmọ-adúláwọ̀ bóyá wọ́n ti nílòo ìwé ìrìnnà. Ní ọjọ́ ìsinmi tí a wà yìí, mo gbọ́ wípé oníṣẹ́-ìròyìn ọmọ Nàìjíríà kan kò le è wà níbí GlobalFact nítorí wípé kò ní ìwé ìrìnnà. Kí a máà sọ ti àwọn ọmọ-adúláwọ̀ tí ó fò kúrò nílẹ̀-adúláwọ̀ kí wọn ó tó lè wọ Tunis. Ní oṣù ti ó kojá, mo ṣe alábàápàdé oníṣẹ́-ìròyìn tí ó wá láti Ìlà-oòrùn Ilẹ̀-adúláwọ̀ tí ó ń ṣe ìbéèrè fún ìwé ìrìnnà wọ Nàìjíríà. Wọ́n ní kí ó pèsèe ìwé-ẹ̀rí ìwákọ̀ọ ti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ awakọ̀ tí yóò wá gbé e bí ó bá balẹ̀ ní pápá-ọkọ̀-òfuurufú!

Bí Rosemary ti sọ, ìrìnàjò nínúu ilẹ̀-adúláwọ̀ máa ń gba ṣíṣèrìnàjò kúrò ní ilẹ̀-adúláwọ̀ kí aṣèrìnàjò ó tó le è dé ibi tí ó ń lọ ní àárín Ilẹ̀-adúláwọ̀. 

Ní ibi àpérò òṣìṣẹ́ ọkọ̀-òfuurufú agbègbè tí Àjọ Ìgbókègbódò Ọkọ̀-òfuurufú Àgbáyé (IATA) gbé kalẹ̀ tí ó wáyé ní Accra nínúu oṣù Òkúdù, Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdèe Ghana, Oníṣègùn Mahamudu Bawumia pohùnréré-ẹkún látàríi wípé “ó yẹ oníṣòwò láti Freetown [Sierra Leone], fún àpẹẹrẹ, láti ṣe ìrìnàjò fún ọjọ́ méjì gbáko láti lọ sí Banjul (nípasẹ̀ẹ orílẹ̀-èdè kẹ́ta) fún ìrìnàjò tí kò ju wákàtí kan lọ.

Ìpòyì lórí òfuurufú náà gbọ́mọ pọn pẹ̀lú owó kanangú fífò lókè láàárín Ilẹ̀-adúláwọ̀.

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ó ṣeéṣe kí mọ-adúláwọ̀ ó máà padà wálé? 

Iṣẹ́ ìdóòlà-ẹ̀mí ní oríi omi Erékùsù Canary ní 2006. Àwòrán láti ọwọ́ọ Noborder Network. (CC BY 2.0)Ni àárín-n ọdún-un 2010-2017, àwọn aṣípòkiri láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà lábẹ́ Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara ni ó ṣepò tí ó tẹ̀lé Syria gẹ́gẹ́ bí ìlú tí ó ní ènìyàn tó pọ̀ jù nínú àwọn aṣípòkiri lágbàáyé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọmọ-adúláwọ̀ ń sá kúrò nílùú nítorí ebi àti rògbòdìyàn, láti wábi forípamọ́síeek, didi ogúnlémidébí tàbí didi agbélùú ní Àréwá Amẹ́ríkà tàbí ní Éróòpù. Àbájáde Ìwádìí Pew ọdún-un 2018 sọ wípé iye àwọn aṣípòkiri  láti Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara “ti fi ìdá 50 lọ sókè  tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní àárín-in ọdún-un 2010 àti 2017, ju gbogbo rẹ̀ lọ wọn ju ìdá 17 lọ káríayé ní àsìkò kan náà.”

Awọn ọmọ-adúláwọ̀ tí ó wá láti Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara náà ń ṣí kiri orílẹ̀-èdè jákèjádò àgbáyé. Ní ọdún-un 2014, ó tó aṣíkiri 170,000 tí ò ní ìwé-àṣẹ lábẹ́ òfin ni ó ń wọ ọkọ̀ gba orí òkun Mediterranean lọ sí orílẹ̀-èdè Italy. Ọ̀gọ̀rọ̀ ló wá láti àwọn Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara. Ní oṣù Ọ̀pẹ ọdún-un 2018, Ọlọ́pàá Brazil dóòlà ẹ̀mí èèyàn 25 ọmọ-adúláwọ̀ tí ó wá láti Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara “tí ó ti wà lọ́rí omi òkun Atlantic fún oṣù kan gbáko”. Àwọn arìnrìnàjòó san “ẹgbẹlẹmùkù owó lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan” fún ìrìnàjò láti Cape Verde. Ní oṣù Òkúdù ọdún-un 2019, US Customs Àjọ Aṣọ́bodè àti Ààbò Ibodè US ní Del Rio, Texas, USA, fi ọwọ́ọ ṣìkún òfin mú àwọn ọmọ-adúláwọ̀ 500 tí ó wà láti Ilẹ̀-olómìnira Congo, Democratic Republic of Congo, àti Angola, tí wọn ń fẹ́ gba omi Odò Rio Grande wọ USA.

Onírúurú ìròyìn ni ó ti rò ó wípé Ilẹ̀-adúláwọ̀ ni àárín-ín gbùngùn òtòṣì àti ogun, síbẹ̀síbẹ̀, Marie-Laurence Flahaux àti Hein De Haas, àwọn onímọ̀ láti Ifásitì ti Oxford àti Ifásitì ti Amsterdam, ní ṣísẹ̀ntèlé, kò gbà pé bẹ́ẹ̀ ní ó rí.

Flahaux àti De Haas jiyàn wípé kò rí bí ìròyín ti e rò ó sí etígbọ̀ọ́ ọmọ aráyé pàápàá “àwọn ilé iṣẹ́ àti olóṣòlú” àti àwọn ọlọ́gbọ́n náà. Iṣẹ́ ìwádìí fi yé wípé àwọn ìṣípòkiri láti Ilẹ̀-adúláwọ̀ kò déédéé wáyé, ohun tí ó fà á ni “ìlànà ìdàgbàsókè àti ìyípadà àwùjọ” èyí tí ó ń mú ṣíṣíkiri lọ sí àwọn agbègbè àgbáyé wu Ọmọ-adúláwọ̀ — tí kò yàtọ̀ sí aṣípòkiri láti ibòmìíràn lágbàáyé. 

Àwọn ìròyìn abanilórúkọjẹ́ wọ̀nyí, ni ó ń fa sábàbí ìlànà-iṣẹ́ ìwé ìrìnnà: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni ó nígbàgbọ́ wípé gbogbo arìnrìnàjò tí ó bá jẹ́ Ọmọ-adúláwọ̀ ni kò ní padà sí orílẹ̀-èdèe rẹ̀, àfi bí arìnrìnàjó bá ní ẹ̀rí tí ó yanrantí tó ni ó lè rí ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú gbà.

Kò rọrùn láti ṣí ojú àwọn tí kì í ṣe ọmọ-adúláwọ̀ lójú nípa orúkọ búburú tí wọn ti sọ orílẹ̀-èdè tí ó wá láti Ilẹ̀-adúláwọ̀. Níbàyìí, àwọn orílẹ̀-èdè Ilẹ̀-adúláwọ̀ níṣẹ́ láti ṣe sí ètò lílọ-àti-bíbọ̀ àwọn ọmọadúláwọ̀. Ìwé-ẹ̀rí-ọmọìlú-fún-ìrìnnà kan  ṣoṣo fún gbogbo orílẹ̀-èdè ní Ilẹ̀-adúláwọ̀ jẹ́ ọ̀nà àbáyọ — àmọ́ kò tó. Single African Air Transport market náà (SAATM), àti Continental Free Trade Agreement náà, tí a fi lọ́lẹ̀ lọ́dún tí ó kọjá, ti se àlàálẹ̀ ìgbésẹ̀ wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ìmúṣẹ ṣì kù díẹ̀ káàtó.

Lásìkò yìí, gẹ́gẹ́ bíi Ọmọ-adúláwọ̀, ìyànjú láti rìnrìnàjò ni láti ní ìrírí ìrẹnisílẹ̀ tí àwọn tí ó ń se ìrìnàjò lọ sí òkè-òkun ń rí — tàbí jẹ́ títají nínú àlà ìsọ̀kan Ilẹ̀-adúláwọ̀ tí kò sí. Èyí kéyìí tí ò báà jẹ́, òòsà ìwé ìrìnnà ń béèrè ẹbọ sí i, tí kọ̀ sì yé é gbẹbọ.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.