Fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ẹ̀tọ́ àti imúdiṣíṣẹ ìbéèrè wọn lábẹ́ òfin, ìwọ́de Afẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo wáyé ní Lahore, Pakistan, lọ́jọ́ 29 oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ìlúu nì, àwọn Abódiakọ-akọ́diabo kò bẹ̀rù láti jáde síta nínú ibi ìkòkọ̀ wọn àti fún ìjọba láti mú òfin Ààbò Ẹ̀tọ́ Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn ọjọ́ 24, oṣù Èbìbì 2018.
With changing times even Pakistan is becoming more accepting towards transgender! First ever transgender march in Pakistan took place in Lahore on Dec 29, 2019. I hope this will continue and maulvis won’t give out fatwas against it. https://t.co/Z0xM8vbCCq
— Nusrat Sohail (@NusratSohail1) January 2, 2019
Ìwé òfin ìlú Pakistan sọ wípé “A kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìgbé ayé tàbí òmìnira du ẹnikẹ́ni ní ìbámu òfin,” tí ó wà lábẹ́ Àwọn Ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú. Síbẹ̀, Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn ní ìtàn mìíràn láti sọ bí ó bá kan ti ẹ̀tọ́ àti ìgbé ayé; wọ́n ti jìyà oró, ìfipábánilòpọ̀, dáná sun wọ́n ní ààyè, bẹ́ wọn lórí àti yin ìbọn pa wọ́n, ìjọba kò fi torí gbogbo èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú pé Ìjọba ti tari òfin Ààbò Ẹ̀tọ́ Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn wọlé nínú oṣù Ẹrẹ́nà ọdún 2018.
Jannat Ali, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Lahore's Trans Diva, ni olùdásílẹ̀ Abódiakọ-akọ́diabo Track Transgender àti Olùdarí Ètò fún Ilé-iṣẹ́ Sathi tí ó ṣe àgbékalẹ̀ Ìwọ́de Afẹ́ náà. Àwọn Abódiakọ-akọ́diabo mìíràn àti àwọn tí kì í ṣe Abódiakọ-akọ́diabo àmọ́ tí ó jẹ́ alátìlẹ́yìn náà kó ipa nínú ìyíde náà àti àṣeyọríi rẹ̀. Ilé-iṣẹ́ ìpìlẹ̀ Sathi jẹ́ ilé-iṣẹ́ fún àlàáfíà àti ìmójútó ààbò ẹgbẹ́ abódiakọ-akọ́diabo ní Pakistan.
Ènìyàn Abódiakọ-akọ́diabo tí ó tó bí 250 láti agbègbè jákèjádò ìlú Pakistan. Gbajúmọ̀ nínú wọn ni Kami Sid, Bebo láti Sindh, Nadra láti KPK, Anmol láti Agbègbè Sahiwal, Nayab láti Okara, Sunaina Khan (Oníjó ìbílẹ̀), Naghma àti Lucky (Akọrin Coke Studio), Laila Naz àti Neeli Rana. Ìpàdé oníròyìn ni a fi bẹ̀rẹ̀ ètò ní Ilé Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn ní Lahore níbi tí wọ́n ti fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn; lẹ́yìn náà ni wọ́n yide kiri dé Ilé Àṣà Al Hamra níbi tí wọ́n ti jó, kọrin lọ́nà, kí wọn ó tó fọ́nká lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán.
Pẹ̀lú pé ìpàdé fún oníròyìn wáyé ní Ilé Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn Lahore, Ìyíde Ìgbéraga náà ó jáde nínú ìròyìn. Bíótilẹ̀jépé àwọn alágbèékalẹ̀ fi ìwé pe aláṣẹ ìlú, bí i Punjab MNA Saadia Sohail láti Pakistan Tehreek e Insaf, àwọn aláṣẹ kò yọjú. Ìyíde ọ̀hún fa awuyewuye lórí ẹ̀rọ-alátagbà níbi tí àwọn ènìyàn gbé oríyìn fún ìyíde kiri náà nígbà tí àwọn ènìyàn kan fẹ́ mọ ìdí tí ilé iṣẹ́ oníròyìn kò ṣe rò nípa rẹ̀.
https://t.co/2JEBMDkqSR
Why is there a media blackout regarding the Trans Pride march in Lahore, Pakistan?— Nem (@NemmyDDS) January 6, 2019
This is wonderful ❤️ Pakistan’s first transgender pride march. It’s a shame that no one really reported on it, most likely because it doesn’t fit the narrative of a country defined simply by religious extremism. What defines it is it’s diverse people just like any other place. https://t.co/cKxlaerFHy
— Basit Mahmood (@BasitMahmood91) December 30, 2018
Ni ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ alágbèékáa Jannat Ali ní:
The aim was to show positive and progressive image of Pakistan and how the country is slowly accepting us and we are gaining more space in the society. Pakistan is not only about terrorism and a conservative society there is more to us. We promoted our march along with our KhawajaSara (transgender) culture and traditions it was not the same type of march as it is held in US.
Ìyíde náà tún tẹnu mọ́ ìlọsíwájú àti ìbáṣepọ̀ rere láàárín ẹgbẹ́ abódiakọ-akọ́diabo; bákan náà ni ó tẹnu mọ́ ìyàsọ́tọ̀ àti rògbòdìyàn. Nítorí wípé kò sí iṣẹ́ fún wọn, àwọn abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn kò ní ṣíṣe ju kí wọn ó ṣe òwò nọ̀bì láti rí oúnjẹ òòjọ́. Látàrí ìbálòpọ̀ tí kò ní ààbò, ọ̀pọ̀ l'ó ti kó àrùn kògbéwékògbègbó HIV àti AIDS. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣe kókó fún àjọ ọlọ́pàá àti oníṣègùn nítorí àwọn ni kì í mú ayé rọrùn fún Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn tí ó bá ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ tàbí nílò ìrànlọ́wọ́ ètò ìlera.
A ti fi ẹ̀tọ́ àwọn abódiakọ-akọ́diabo yí iyẹ̀pẹ̀. Láti ọdún 2015, abódiakọ-akọ́diabo tí ó tó 500 ni a ti rán lọ sí ọ̀run alakákeji ní Pakistan , Jannat Ali sì tún sọ wípé Abódiakọ-akọ́diabo 60 ni a dá ẹ̀mí wọn ní ẹ̀gbodò ní ọdún tí ó kọjá.
Asad Zaidi túwíìtì nípa ojú tí àwọn ènìyàn Pakistan fi wo ẹgbẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo:
RT'd a tweet about the trans pride march in Pakistan and lost a bunch of followers. Bye (:
— asad (@sad_zaidi) January 3, 2019
Nínú ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ ní TEDxLahore ní ọdún 2017, Jannat Ali ṣe àlàyé ìrìnàjòo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abódiakọ-akọ́diabo ní Pakistan lẹ́yìn ìgbà tí ó fi irú ènìyàn tí òun ń jẹ́ han ẹbí àti àwọn ènìyàn.
Òfin Ẹ̀tọ́ Ààbò Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn ọdún 2018 tí a bu ọwọ́ lù nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fi àṣẹ fún ọmọ ẹgbẹ́ náà láti gba ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà, ìwé ìrìnnà, ní ẹ̀tọ́ láti pààrọ ìṣẹ̀dá ẹni nínú àkọsílẹ̀ ìlú àti Àjọ Ìforúkọsílẹ̀ (NADRA), ìfòpinsí ìjìyà, àyè láti kàwé, iṣẹ́ nínú káràkátà àti ètò ìlera láì sí ìyàsọ́tọ̀.
Òfin náà ní ìjọba yóò pèsè àyè ilé ààbò fún Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn, ètò ìlera àti ohun èlò ẹ̀kọ́ àti ilanilọ́yẹ. Wọ́n máa lè jẹ ogún àti ẹ̀tọ́ láti di ìbò.
Pakistan ti ń sún kẹ́rẹ́ ní ti ìgbé ayé Abódiakọ-akọ́diabo. Díẹ̀ lára àwọn abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn du ipò ìjọba nínú Ìbò ọdún 2018 fún ìgbà àkọ́kọ́. Ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ìbílẹ̀ kan gba Abódiakọ-akọ́diabo àkọ́kọ́ sí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí atọ́kùn; Coke Studio, ètò orin, àwọn Abódiakọ-akọ́diabo méjì ni ó ti kópa ní orí ètò náà. slowly starting to make strides when it comes to transgender visibility.
Bí nǹkan ṣe ń ṣe ẹnu ire fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo a sì ń gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, ìrìnàjò náà kò yàrá. Síbẹ̀, ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó ní ìgbàgbọ́ wípé àyípadà ọ̀tún ń bọ̀ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti gbé ìgbé ayé ìfọkànbalẹ̀ nígbà tí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn gbogbo ní ìlú á wà ní ọ̀gbọọgba ní ojú àwọn ènìyàn àti ní abẹ́ òfin.