Ilé ẹjọ́ gíga Tanzania pa á láṣẹ fún ìfòpinsí ìsoyìgì láàárín àgbàlagbà àti ọmọdé láì wo ti ìgbésẹ̀ ìmúpadàa rẹ̀

Àwọn Ọmọiléèwé ọmọdébìnrin ní Tanzania dúró fún àwòrán lọ́jọ́ 10 oṣù Agẹmọ ọdún-un, 2007. Fanny Schertzer ni ó ya àwòrán, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ láti Wikimedia Commons, CC BY 2.0.

Nínú oṣù Ọ̀wàrà 2019, ilé ẹjọ́ gíga Tanzania ṣe ìdímú ṣinṣin ìdájọ́ ọdún-un 2016  tí ó pàṣẹ ó kéré jù, ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin gbọdọ̀ pé ọmọ ọdún méjìdínlógún kí ó tó ṣe ìgbéyàwó.

Àjọ ọba orílẹ̀ èdèe Tanzania gbéègbésẹ̀ láti ṣe ìmúpadà ìpinnu yìí, nítorí wípé àwọn ọmọdébìnrin ń yára bàlágà àti wípé ààbò ni ìgbéyàwó jẹ́ fún ọ̀dọ́bìnrin aláboyún. Àmọ́ ní ọjọ́ 23 oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2019, ìjọba orílẹ̀ èdèe Tanzania pàdánù ẹjọ́ọ kòtẹ́milọ́rùnun rẹ̀ tí àṣẹ ilé ẹjọ́ gíga ṣì dúró: akọ àtabo gbọdọ̀ pé ọjọ́ orí méjìdínlógún kí wọn ó tó ṣe ìgbéyàwó, tí èyí sì ń fi agbára kún ìgbẹ́sẹ̀ ìsoyìgì ọmọdé ní Tanzania. 

Gẹ́gẹ́ bí United Nations Population Fund (UNFPA) ti ṣe wí, Tanzania ni ìsoyìgì ọmọdé pọ̀ sí jù lọ lágbàáyé. 

Àwọn ọmọ orí ayélujára ṣíra láti fi ìdùnnúu wọn hàn lóríi ìdájọ́ náà. Àwọn kan kí Rebeca Z. Gyumi, aláfisùn àti ẹni tí ó lé wájú nínú ọ̀ràn ìsoyìgì àwọn ọmọdé náà. Gyumi ni olùdásílẹ̀ àti alákòóso àgbà Msichana Initiative (Ètò fún àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin), iléeṣẹ́ tí kì í ṣe tìjọba tí ó ń ró àwọn ọmọdébìnrin lágbára nípasẹ̀ ti ẹ̀kọ́ ìwé.

#supadada tòótọ́!!! Hongera @RebecaGyumi @Advocate_Jebra àti ikọ̀ọ rẹ̀. Mo rántíi wípé ìrìnàjòo rẹ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún-un 2016, mo jẹ́ ẹlẹ́rìí sí ìboríì rẹ àkọ́kọ́, ó sì n ja ìjà ìfòpinsí ìsoyìgì ọmọdé #endchildmarriage Tokomeza #NdoaZaUtotoni
?????? pic.twitter.com/Rel6fwFs0R

— supadada (@tulanana) October ọjọ́ 23 oṣù Ọ̀wàrà, ọdún-un 2019

Mohammed Dewji, oníṣòwò àti olóṣèlúu nígbà kan rí, gbóríyìn fún ìpinnu náà gẹ́gẹ́ bí ìborí fún àwọn obìnrin ní Tanzania:

Ìjáwé olúborí fún àwọn ọmọdébìnrin Tanzania ni èyí! Ilé Ẹjọ́ọ Kòtẹ́milọ́rùn #Tanzania náà ti di ìdájọ́ ọdún-un 2016 ti Ilé Ẹjọ́ Gíga tí ó sún ọjọ́ orí tí ó kéré jù lọ fún ìsoyìgì fún obìnrin láti 14 sí 18! Hongera kwa wasichana wote wa Tanzania ?? #AChildIsNotAWife #EndChildMarriage. pic.twitter.com/flpILFeNTq

— Mohammed Dewji MO (@moodewji) Ọjọ́ 23, oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2019

Ọmọ orí ayélujára Lydia Charles pè é ní “ìpinnu tí ó dára jù lọ láti ṣe”:

Ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìsoyìgì ọmọdé ní Tanzania

Lọ́dún-un 2016, Gyumi na ọwọ́ ìka àbùkù sí agbára Òfin Ìgbéyàwó; Law of Marriage Act, 2002 (LMA) tí ó gba obìnrin tí kò tó ọmọ ọdún méjìdínlógún láyè láti ṣe ìgbéyàwó.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí nípa ìlera Tanzania Demographic and Health Survey (TDHS) ṣe ti ṣàlàyé, ìdá 36 obìnrin tí ọjọ́ oríi wọ́n wà ní 25-49 ní í ṣe ìgbéyàwó kí wọn ó tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, tí àwọn akẹgbẹ́ẹ wọn lọ́kùnrin sí jẹ́ ìdá 5.

Òfin LMA fi àyè gba ọmọdébìnrin tí ọjọ́ oríi wọn kò ju ọdún mẹ́rìnlá lọ láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ìlọ́wọ́sí ilé-ẹjọ́, ìlọ́wọ́sí òbí fún ọmọ ọdún márùn-ún-dínlógún, nígbà tí ọdún méjìdínlógún jẹ́ ọjọ́ orí tí ó kéré jù lọ fún ọmọkùnrin.

Nípasẹ̀ àwọn aṣojú rẹ̀, Gyumi ṣàlàyé wípé àlàálẹ̀ LMA kọ iyán obìnrin kéré nítorí pé ó fún àwọn ọkùnrin ní àǹfààní ju àwọn obìnrin lọ. Nítẹ̀síwájú, wọ́n sọ wípé àlàálẹ̀ náà fi ẹ̀tọ́ dídọ́gba ọmọ ènìyàn yí ẹrẹ̀fọ̀ àti pé wọn fi ẹ̀tọ́ àǹfààní sí ẹ̀kọ́ ìwé dun àwọn ọmọdébìnrin.

Gyumi rọ Ilé-ẹjọ́ Gíga láti gbé àlàálẹ̀ LMA tì sẹ́gbẹ̀ẹ́.

Ilé-ẹjọ́ Gíga kò ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ wọ́n rí i lóòótọ́ wípé kò bá òfin mu wọ́n sì fún ìjọba lọ́dún kan láti ṣe àtúnṣe sí ohun tí kò tọ̀nà nínú àlàálẹ̀ LMA. Nípasẹ̀ aṣojú àgbà àwọn adájọ́, a pa ìjọba láṣẹ láti gbé ọjọ́ orí ìgbéyàwó sí ọdún méjìdínlógún fún obìnrin àti ọkùnrin.

Síbẹ̀, aṣojú àgbà àná banújẹ́ sí ìdájọ́ náà ó sì kọ ìwé àtúnpè-ẹjọ́ sí Ilé-ẹjọ́ Gíga náà:

Nínú oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún-un 2017, Masaju pe ẹjọ́ọ kòtẹ́milọ́rùn ní ìtako ìdájọ́ ọdún-un 2016.

Pẹ̀lú ìfọwọ́sí àṣẹ ìjọba: mo ti gba ìwé àtúnpè-ẹjọ́ lóríi ẹjọ́ #childmarriage. Ẹjọ́ òǹkaye 204 ti oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún-un 2017.

Àyè fún àtúnpè-ẹjọ́

Láàárín oṣù mẹ́rin ìgbẹ́jọ́, ìjọba gbèrò láti ṣe àtúnpè-ẹjọ́ ọdún-un 2016 tí yó ṣe àtúnṣe sí àlàálẹ̀ LMA èyí tí ó fi àyè gba ọmọdébìnrin ọlọ́jọ́-orí márùn-úndínlógún gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti bàlágà fún ìgbéyàwó. Atẹ́jọ́pè, tí ó jẹ́ aṣojú àwọn adájọ́ ìpínlẹ̀, Mark Mulwambo àti Alesia Mbuya, ṣe àgbékalẹ̀ ìyàtọ̀ ìwà ẹ̀dá obìnrin àti ọkùnrin tí wọ́n sì fi àṣà ìbílẹ̀ àti òfin ẹ̀sìn Ìmàle gbá àtúnpè-ẹjọ́ náà nídìí.

Ms. Mbuya sọ wípé ìyàtọ̀ ìwà ẹ̀dá fi ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin sí “ìsọ̀rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀” àti pé, òfin fi ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò wọ́n. Ó sọ síwájú sí i wípé nítorí àwọn ọmọdébìnrin máa ń tètè bàlágà ju ọmọdékùnrin lọ ni òfin fi la àlàálẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ó sọ wípé ìgbéyàwó lè fi ààbò bo ọmọdébìnrin tí kò sí nílé ọkọ tí ó ti di abaraméjì láì tó ọjọ́ orí tí ó tọ́.

Ó sọ síwájú sí i wípé ilé ẹjọ́ kùnà bí ó ṣe “ṣe ìmúdọ́gbandọ́gba ọjọ́ orí ọmọ àti ọjọ́ orí tí ó yẹ fún ìgbéyàwó”, èyí tí ó túmọ̀ sí wípé ọ̀tọ̀ ni ti tọ́lú ọ̀tọ̀ ni ti tọ́lùú wò, ọ̀tọ̀ ni ó yẹ kí ilé ẹjọ́ ó là kalẹ̀ fún ọjọ́ orí ìgbéyàwó ọkùnrin àti obìnrin.

Àwọn ọmọ orí ayélujára ti yára bu ẹnu àtẹ́ lu ìdí tí àtẹ́jọ́pè fi sílẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́.

Dídọ̀gba abo atakọ

Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà jẹ́ atọ́ka sí ìfòpinsí àwọn àṣà tí ó ń mú ìpalára bá àwọn ọmọdébìnrin àti onírúurú ẹlẹ́yàmẹyà tòun ìfọwọ́rọ́sẹ́yìn àwọn ọmọdébìnrin ní Tanzania. Ní ti àjọ United Nations, kí a tó lè yege níbi ti dídọ́gba abo atakọ ní ọdún-un 2030, ìjọba ní láti ṣe àyípadà òfin ìyàsọ́tọ̀ọtọ̀ àti ṣíṣe àmúlò ìṣòfin tí yóò mú ìmúdọ́gba tí à ń sọ wáyé.

Àbájáde ìwádìí ṣe àfihàn-an rẹ̀ wípé ọjọ́ orí tí ó tọ́ láti ṣe ìgbéyàwó bá ìpele ìwé tí ènìyàn kà àti ọrọ̀ tí ènìyán ti kó jọ (TDHS 201) tan.  Ní Tanzania, ó ní ìyàtọ̀ ọdún mẹ́fà tí ó wà láàárín ọmọdébìnrin tí kò lọ sí ilé ìwé àti àwọn tí ó ka ìwé gíga tàbí ìwé gíga jù lọ.

Ní Tanzania, ohun tí kò bá òfin mu ni kí a fẹ́ tàbí fún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin lóyún, ẹ̀wọ̀n ọgbọ̀n ọdún ni ẹní bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sófin yóò fi gbára. Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tí ó bá lóyún kì í padà sí ilé ìwé pàápàá tí ó bá bímọ tán.

Ìfòfinde ìsoyìgì pẹ̀lú ọmọdé máa ń fi ààbò fún àwọn ọmọdébìnrin, láì ro bí wọ́n ṣe wọ ilé ìwé. Ní Tanzania, ìgbéyàwó ọmọdébìnrin kì í jẹ kí ọmọdébìnrin ó kàwé tí wọn kò sì ní àǹfààní láti parí ẹ̀kọ́ọ wọn, gẹ́gẹ́ bí èsì ìwádìí láti Tanzania National Survey, 2017 ṣe ní i lákọsílẹ̀.

Ìfòfinde ìsoyìgì yìí ṣe àgbékalẹ̀ ìgbé ayé tó dára fún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin láti parí ẹ̀kọ́ọ wọn láì sí ìdádúró. Pẹ̀lú bẹ́ẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tí ó bá fẹ́rakù ṣì ń kojú òfin tí ó ní wọn kò gbọdọ̀ padà wá sílé ìwé.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.