Ilé-iṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ìbílẹ̀ Fagilé Ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn ajìjàǹgbara LGBT lẹ́yìn ìhalẹ̀mọ́ sí olóòtú

Àwọn ajìjàǹgbara ní Madrid fi ẹ̀hónú hàn lórí ìrúfin ẹ̀tọ́ LGBT ní Russia // gaelx, lábẹ́ CC NÍPA-SA 2.0

Ilé-iṣẹ́ Echo ti Moscow ní Yaroslavl tí ó jẹ́ ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Echo ti Moscow ìsopọ̀ tí ó ti dá dúró fún ìgbà pípẹ́ ní Russia fagi lé ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn ajìjàǹgbara LGBT lẹ́yìn tí wọ́n gba ìhalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kórìíra-ìbálòpọ̀-láàárín-akọ-àti-akọ, olóòtú ilé-iṣẹ́ náà Lyudmila Shabuyeva sọ̀rọ̀ nínú àkọsílẹ̀ Facebook kan:

Вчера поступили угрозы в адрес наших сегодняшних гостей и нас, если мы проведем эфир на тему ЛГБТ.

Я отменяю эфир.

Ní àná, a gba ìhàlẹ̀ kan tí ó ń lérí mọ́ àwa àti àwọn àlejòo wa tí a bá tẹ̀síwajú pẹ̀lú ètò ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ọ wa nípa LGBT.
Mò ń fagi lé ètò náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn tí ò sí ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba  Novaya Gazeta ti ṣe sọ, ó yẹ kí ètò náà tí yóò ṣe àfihàn àwọn ajìjàǹgbara LGBT ní Yaroslavl wáyé ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú 23, ní oṣù Ṣẹẹrẹ. Àwọn ajìjàǹgbara yìí kan náà ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀hónú hàn ní gbàgede ìlú láti tako ìfìyàjẹ àwọn aṣe-ìbálòpọ̀-akọ-àti-akọ ní Russia, pàápàá jùlọ ní orílẹ̀ Chechnya. Ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà pè wọ́n láti fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò nípa ìfẹ̀hónúhàn àti ìrírí wọn fún jíjáde sí gbangba gẹ́gẹ́ bíi aṣe-ìbálòpọ̀-akọ-àti-akọ ní ẹ̀ka-ìlúu Russia.

Ìkéde Shebuyeva àkọ́kọ́ nípa ètò náà fa ẹgbẹlẹmùkù èébú ìkórìíra-ìbálòpọ̀-láàárín-akọ́-àti-akọ nínú àwọn èsì, tí èsì sì wá láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ọba kan bákan náà, ṣùgbọ́n ìyẹn ò mú ọkàn-an rẹ̀ kúrò, ó sọ fún Novaya Gazeta.
Ṣùgbọ́n ní alẹ́ ọjọ́ tí ètò náà ku ọ̀la, Shabuyeva sọ̀rọ̀ pé òun gba ìpè àjèjì láti orí òpó ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ kan tí kò ṣe é dámọ̀, ẹni náà sì sọ fún òun pé bí òun bá tẹ̀síwajú pẹ̀lú ètò náà bí ó ṣe ti pinnu, wọ́n máa fi igi ìgbábọ́ọ̀lù-afọwọ́jù pàdé àwọn àlejò rẹ ní ìta ilé-iṣẹ́ náà. Òun náà sì lè kojúu wàhálà, onípè àjèjì náà léríléka. Nítorí ìbẹ̀rù fún ààbò àwọn àlejòo rẹ̀, Shabuyeva fagilé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà tí ó sì fi ètò mìíràn rọ́pòo rẹ̀.

Ìfẹ̀hónúhàn tí ó wáyé ní gbàgede ìlú wà lára ìkéde gbogboògbò #saveLGBTinRussia tí wọ́n fi ń polongo ìyà tí ó rorò tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ènìyàn aṣe-ìbálòpọ̀-akọ-àti-akọ ní orílẹ̀ Chechnya. Àwọn ìwọ́de àti ìfẹ̀hónúhàn irú èyí wáyé ní àwọn ìlú mìíràn ní Russia.

Ìlú ń ké pe àwọn ọmọ rẹ̀ (àwọn ọmọ ìlú) láti dojú ìjà kọ ìwà elẹ́yàmẹyà àti ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní Russia òde-òní. Jẹ́ kí ìpèe rẹ̀ ta ọ́ jí!
[àmì náà ń sọ pé: Ẹ̀KA ÌṢÈDÁJỌ́ TI ORÍLẸ̀-ÈDÈE RUSSIA Ò RÍ ÀWỌN AṢE-ÌBÁLÒPỌ̀-AKỌ-ÀTI-AKỌ NÍ CHECHYA. WỌ́N WÀ NÍBẸ̀: NÍNÚ ÀWỌN ỌGBÀ Ẹ̀WỌ̀N ÀTI IBOJÌ-ÒKÚ.
#SAVELGBTINRUSSIA Ẹ̀TANÚ ÌBÁLÒPỌ̀-LÁÀÁRÍN-AKỌ-ÀTI-AKỌ = ÌJỌBA AFIPÁMÚNI

Nínú oṣù Igbe 2017, Novaya Gazeta jábọ̀ pé àwọn aláṣẹ ní Chechnya, ti ìlú oníjọba Ìmọ́lẹ̀ tí ó ń rí ìdààmú jù ní gúúsù Russia tí ajagun fẹ̀yìntì Ramzan Kadyrov, ń ṣe olóríi rẹ̀, ń ṣe ìpolongo tí ó rorò tí ó ń tako ìtẹ̀mọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn tí í ṣe LGBT tí ó ń gbé nínúu rẹ̀. Ìròyìn tí ó jáde ní àìpẹ́ sọ pé “ìfọ̀mọ́” náà le gidi gan-an ni, pẹ̀lú ikú èèyàn méjì ó kéré tán àti ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ó wà ní àtìmọ́lé tí ó lòdì sí òfin.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.