Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà ni àwọn ọlọ́pàá fi sí àtìmọ́lé, tí ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀dàlẹ̀ ní Papua, orílẹ̀-èdè Indonesia, látàrí bí wọ́n ṣe gbé àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ sókè níbi Gbàgede Eré-ìdárayá Cenderawashih ní ìlú Jayapura, tí wọ́n sì ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí olú ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá ti Papua ní ọjọ́ kìnínní oṣù Kejìlá ọdún 2021. Ìjọba orílẹ̀-èdè Indonesia ti ka nína àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ sókè l'éèwọ̀ fún awọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà. Àsíá yìí ni ó dúró fún ìgbéraga orílẹ̀-èdè Papua tí ó ń jì'jà-n-gbara láti gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè olómìnira Indonesia fún ọjọ́ pípẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ lẹ́nu Suara Papua, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́jọ náà tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tẹ̀léra wọn nínú ẹ̀mí ìfẹ̀hónúhàn, tí wọ́n sì ń fi àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ ọwọ́ wọn, pẹ̀lú pátákó pélébé ní ọwọ́, tí ó sọ wípé “Ìpinnu Ara-ẹni fún Ìwọ̀ Oòrùn Papua! Ìfimọ ìfipáṣèjọba ọmọ ogun ní Ìwọ̀ Oòrùn Papua. Fífàyègba Aṣojú àjọ UN Àgbà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Ìwọ̀ Oòrùn Papua,” tí wọ́n sì f'orílé olú ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá Papua.
Àwọn Ọlọ́pàá gbá wọn sí atìmọ́lé nígbà tí wọ́n dé àgọ́ ọlọ́pàá náà, tí wọ́n sì ń jẹ́jọ́ ìhùwà ọ̀tẹ̀. Ní orílẹ̀-èdè Indonesia, ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni tí wọ́n bá ẹ̀sùn ìhùwà ọ̀tẹ̀ kàn yóó fi jura.
1/12/21 Jayapura, Ìwọ̀ Oòrùn Papua
A fi ọwọ́ ṣìkún òfin mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà DT, EM, LS, MY, AM, MY nítorí wípé wọ́n na àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ tí a gbẹ́sẹ̀lé sókè. Wọ́n lè fi ẹ̀wọ̀n gbére gbára bí a bá fi ẹ̀sùn ìhùwà ọ̀tẹ̀ kàn wọ́n.
Àyájọ́ òní ni a ta àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ sókè ní ọdún 1961. pic.twitter.com/d200w6ti7H
— Veronica Koman 許愛茜 (@VeronicaKoman) December 1, 2021
Ọjọ́ kìnínní, oṣù Kejìlá, ọdún 2021 tí àwọn ènìyán kà sí Ọjọ́ Òmìnira orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Papua, sàmì àyájọ́ ọgọ́ta ọdún tí a kọ́kọ́ ta àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ ní ìgbésẹ̀ láti gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn Dutch. Láti ìgba yìí, ni gbogbo àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Papua kárí ayé ti ń gbé àsíá náà gẹ̀gẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ kìnínní oṣù Kejìlá láti fi bu ọlá fún èrò ati ìgbésẹ̀ wọn láti gba òmìnira fún Papua.
Àwọn ọmọ Papua tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè Australia ni wọ́n na àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ wọn sókè, àmì tí ó lágbára fún akitiyan wọn láti gbòmìnira lọ́wọ́ ìjọba Indonesia, àti láti sàmì àyájọ́ ọgọ́ta ọdún tí ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ títa sókè ní ìlú náà tí àwọn Dutch tẹ̀dó nígbàkan rí https://t.co/htjxfbi5PG pic.twitter.com/1yuCCgz7gI
— Andreas Harsono (@andreasharsono) December 1, 2021
Emanuel Goal, tí ó jẹ́ Alákòóso Ìgbẹ̀jọ́ fún Egbẹ́ Ìgbófinró àti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní ìlú Papua, sọ fún ilé-iṣẹ́ ìròyìn Suara Papua wípé kòì tí ì sí ìyànda fún òun láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nítorí wípé wọn kòì tíì gbé wọn lọ sí ilé-ẹjọ́. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní :
A kòì tí ì lè ṣe ìrànwọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ náà tààrà látàrí wípé àwọn oníwàádìí kòì tí ì ṣe àfíkún ìwádìí wọn lórí ohun tí awọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ náà ṣe. Títí di àkókò yìí, àwọn ọlọ́pàá agbègbè Papua ti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Papua mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ náà tí ó gbé àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ kiri ní Gbàgede Eré-ìdárayá Jayapura sí àtìmọ́lé. Àtìmọ́lé àwọn ènìyàn mẹ́jọ wọ̀nyí kòì tí ì lórí.
Èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọn yóò síjú lé awọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú wọn hàn fún òmìnira Papua. Ní inú oṣù kẹjọ ọdún 2020, ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan lé akẹ́kọ̀ọ́ kan jáde kúrò nílé ìwé, a sì tún fi ẹ̀sùn ìhùwà ọ̀dàlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè ẹni kàn án látàrí wípé ó dara pọ̀ mọ́ àwọn olùfẹ̀hónúhàn fún orílẹ̀-èdè Papua. Bákan náà ni a fi ẹ̀sùn ìhùwà ọ̀dàlẹ̀ kan àwọn ajìjàngbara méje kan, tí a mọ̀ sí “Balikpapan Seven”, tí wọ́n sì lo ọdún kan l'ẹ́wọ̀n fún kíkópa nínú ìfẹ̀hónúhàn ìtako-ẹ̀yà ní Papua — èyí tí ó mú kí àwùjọ àgbáyé ó fi ojú sí ara Indonesia tí ìjọba orílẹ̀-èdè Indonesia sì gba súúná ibú.
Rògbòdìyàn l'óríṣiríṣi ni ó ti ń ṣẹlẹ̀ látàrí òjòjò ọrọ̀-ajé tí ó ti ara ajàkálẹ̀ àrùn COVID-9 jẹyọ, ìbísi ìpè fún ìṣèjọba ara-ẹni láti ọ̀dọ̀ àwọn ajì'jàngbara àti àwọn tí ó wọ́n jẹ́ ọmọ Papua, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìdúkokò àwọn ikọ̀ ọmọ ogun orí ilẹ̀ tòun ìwà ipá àwọn alákatakítí erékùṣù náà nígbàoogbo.
Gẹ́gẹ́ bí ilé-iṣẹ́ ìròyìn, Suara ti ṣe fi léde, ní ọjọ́ kan náà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ni àwọn ikọ̀ ọmọ ogun kan tí kìí ṣe t'ìjọba tí wọ́n ń pè ní The West Papua National Liberation Army (TPNPB), ẹgbẹ́ alákatakítí kan, t'iná bọ ilé-iṣẹ́ onígi gẹdú kan, (PT Build Irian Wood) tí ó wà ní agbègbè Sorong, ní ìwọ̀ Oòrùn Papua.
Ẹni tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún awọn ẹgbẹ́ náà sọ wípé àwọn ṣe ìṣàtì gbogbo ìdàgbàsókè ìlú Papua, awọn yóò sì gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ tako àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìlòdìsí èrò ati ìfẹ́ ọkàn àwọn ará ìlú.