Èyí ni àtúnkọ àròkọ láti ọwọ́ Saut Sok Prathna fún Ìròhìn VOD, iléeṣẹ́ oníròyìn òmìnira tí kò f'arakọ́ ìjọba ní Cambodia, tí Ohùn Àgbáyé sì tún un tẹ̀ jáde lábẹ́ àdéhùn àtúnpín-ìròyìn. Ògbufọ̀ láti àròkọ àtilẹ̀bá lórí VOD Khmer
Ó tó òṣìṣẹ́ ẹ̀wù 1,000 t'ó fi ẹ̀hónúhàn níta iléeṣẹ́ Phnom Penh lọ́jọ́ 25, oṣù kẹta, 2020, lẹ́yìn tí ẹni t'ó nílé iṣẹ́ náà kọ̀ jálẹ̀ láti san owó ọ̀yà wọn bí wọ́n ti ṣe máa ń gbà á, èyí tí iléeṣẹ́ náà fi yé wí pé nítorí àwọn òǹbárà kò sanwó ọjà lásìkò àjàkáyé àrùn COVID-19 t'ó ń jà rọinrọin ló fa sábàbí.
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀rọ aṣaṣọ ti iléeṣẹ́ Canteran Apparel (Cambodia) fi ẹ̀hónúhàn lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ náà kò san owó ọ̀yà wọn pé pérépéré fún ọ̀sẹ̀ méjì léraléra, òṣìṣẹ́ kan, Sann Sopha sọ fún VOD.
Ẹni tó ni ilé ẹ̀rọ aṣaṣọ náà fi àáké kọ́rí, kò ti ọwọ́ bọ ìwé àdéhùn ìlérí láti sanwó àjẹmọ́nú àwọn òṣìṣẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù t'ó ń bọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ́ ti ṣe fẹ́, Sopha sọ.
Workers will continue their strike to force the company to respect the condition to pay workers regularly from today onward. Workers asked the company to make a written promise with them but the company did not dare to make a contract with us. The company just gave excuses for this and that.
Àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa ṣe ìdaṣẹ́sílẹ̀ wọn lọ lójúná àti mú kí iléeṣẹ́ náà ó fi ọ̀wọ̀ òṣìṣẹ́ wọ àwọn òṣìṣẹ́ nípa sísan owó wọn láti òní lọ. Àwọn òṣìṣẹ́ wí fún iléeṣẹ́ náà kí ó ṣe àkọsílẹ̀ ìlérí tí ó ṣe fún àwọn àmọ́ iléeṣẹ́ náà kò ṣe àdéhùn kankan. Àwáwí oríṣìíríṣìí ni iléeṣẹ́ náà ń wí.
Sopha sọ wí pé ilé ẹ̀rọ aṣaṣọ náà kì í san owó àwọn òṣìṣẹ́ déédéé fún oṣù mẹ́rin. Ó sọ wí pé ọmọ orílẹ̀-èdè China ni ẹni t'ó ni iléeṣẹ́ náà, síbẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ orúkọ ti àwọn Àjọ Ẹ̀wù Títà ní Cambodia ní i l'ákọsílẹ̀ wí pé ọmọ orílẹ̀-èdè Malaysia ní i ṣe. GMAC sọ wí pé, òṣìṣẹ́ 935 ni iléeṣẹ́ náà gbà síṣẹ́.
Kim Bou, olórí ẹ̀ka ìpínfúnni ní iléeṣẹ́ náà, sọ wí pé iléeṣẹ́ náà ti pàdánù àwọn oníbàárà rẹ̀ látàrí òjòjò tí ó ṣe ètò ọrọ̀-ajé àgbá-ńlá-ayé tí í ṣe arapa ìtànká àrùn COVID-19, òkùnrùn ibi ètò ìmísínú-ìmísóde tuntun tí ó kọ́kọ́ di mímọ̀ ní orílẹ̀-èdè China nínú oṣù kejìlá ọdún 2019.
Bou sọ wí pé Canteran ní ìdojúkọ owó nítorí náà ni kò fi lè sanwó òṣìṣẹ́ lásìkò, àmọ́ ó sọ wí pé iléeṣẹ́ náà ń wá gbogbo ọ̀nà tí yóò fi san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́.
The company faces difficulties with the market, and buyers have also delayed transferring their payments because of the Covid-19 issue. Our company tried very hard to find a solution for our workers. However much money we have, we will pay with that and the owner will keep paying till they get full wages.
Iléeṣẹ́ náà ń rí ìnira ní ọjà, àwọn òǹbárà náà di owó tí wọ́n jẹ iléeṣẹ́ mú, wọn kò fi ránṣẹ́ nítorí àrùn Covid-19. Iléeṣẹ́ wa gbìyànjú láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣ'àdá fún àwọn òṣìṣẹ́ wa. Síbẹ̀síbẹ̀ a ó fi iye owó tí a bá ní san owó tí a jẹ àwọn òṣìṣẹ́ títí ẹni tí ó nílé iṣẹ́ yóò fi san àwọn owó ọ̀yà náà tán pátápátá.
Arapa COVID-19 lórí ìdàgbàsókè owó tó wọlé sí orílẹ̀-èdè Cambodia lè ju ìdá 1 lọ ní dídárajùlọ àti nǹkan bí ìdá 3 owó orílẹ̀-èdè ní èyí tí ó láàfì jù lọ, bí àfiyéni tí Ilé-ìfowópamọ́sí Ìdàgbàsókè Asia gbé sóde ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí. Ipa rẹ lè tó ìdá 4 owó tí ó wọlé sórílẹ̀-èdè ní ìgbà àbá-ìpìlẹ̀ tí àjàkálẹ̀ àrùn bá wáyé lórílẹ̀ èdè.
Iléeṣẹ́ Ètò Ìlera ti kéde wí pé ènìyàn 96 ló ti kó àrùn náà ní orílẹ̀-èdè náà láti inú oṣù kìníní (ní ìgbà tí ó di ọjọ́ 26 oṣù kẹta) ẹni 10 ti gba ìwòsàn lọ́wọ́ kòkòrò àìfojúrí náà.
Sopha sọ fún VOD wí pé àwọn òṣìṣẹ́ sọ wí pé nǹkan yóò nira fún wọn láti rówó ná lóòjọ́, fún àpẹẹrẹ owó ìyálégbé, ohun ìlò ilé, owó iléèwé àwọn ọmọ àti ẹ̀yáwó nílé-ìfowópamọ́sí bí agbanisíṣẹ́ kò bá sanwó ọ̀yà wọn pé, lásìkò t'ó tọ́.
Pav Sina, ààrẹ Ẹgbẹ́ Àpapọ̀ Ayédáadé Ìṣípòpadà àwọn Òṣìṣẹ́, sọ wípé iléeṣẹ́ náà ń tàpá s'ófin bí kò ṣe san owó ọ̀yà àwọn òṣìṣẹ́ pé.
Sina sọ pé kí Iléeṣẹ́ àwọn Òṣìṣẹ́ ó wá ọ̀nà àbáyọ ní kíákíá tí yóò ran àwọn òṣìṣẹ́ tí nǹkan ò dán mánrán fún lọ́wọ́.
We cannot let the employers give excuses to delay paying workers’ wages, because workers are in debt and they cannot make an excuse to delay their expenses. If [workers] cannot pay debts on the right date and time, they will be fined.
A kò leè jẹ́ kí àwọn agbanisíṣẹ́ ó wí àwáwí tí yóò fa ìfàsẹ́yìn fún owó ọ̀yà àwọn òṣìṣẹ́, nítorí àwọn òṣìṣẹ́ ti jẹ gbèsè, wọn kò sì gbọdọ̀ jáfara láti san owó wọn. Bí [àwọn òṣìṣẹ́] kò bá leè san igbèsè lọ́jọ́ tí ó yẹ lásìkò, wọn yóò san ìtanràn.
Pàbo ni gbogbo akitiyan láti bá Peng Phoeun, aṣojú olóyè ti Iléeṣẹ́ àwọn Òṣìṣẹ́ t'ó ń rí sí aáwọ̀ láàárín òṣìṣẹ́ ní gbólóhùn lásìkò àtẹ́jádé ìròyìn yìí jásí.