Àfilé iye owó fún gbígba ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà mú àwọn ọmọ Angola fi ẹ̀hónú hàn

Ní ibi ìfẹ̀hónúhàn ní Luanda, àmì náà sọ pé “30.500 Kwanzas kì í ṣe kékeré”. Àwòrán láti ọwọ́ọ Fernando Gomes, a gba àṣẹ láti lò ó.

Inú ń bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Angola látàrí iye owó ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà tuntun 30,500 kwanzas (ó tó 97 owó dollar) tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ polongo ní ọjọ́ 21 oṣù Ṣẹẹrẹ. 2500 kwanzas (owó dollar orílẹ̀-èdè US mẹ́jọ) ni ó jẹ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

Ní àfikún, ìjọba ti pín iye owó irúfẹ́ ìrìnàjò tí ó wà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó tò ó ní ẹsẹẹsẹ. Lábẹ́ ìlànà tuntun yìí ni ìjọba yóò ti máa gba 45,250 kwanzas fún ìwé ìwọ̀lú ìdúró-sí-ìlú; 21,350 fún ìwé ìwọ̀lú ìrìnàjò-afẹ́; 36,500 fún ìwé ìwọ̀lú àgbàníbodè; 38,125 fún ìsúnsíwájú ìwé ìwọ̀lú iṣẹ́; 15,250 fún ìwé ìwọ̀lú ọ̀rọ̀ ìlera ara; àti 30,500 fún ìwé pélébé ìgbélùú.

Agbẹnusọ fún Ẹ̀ka Ìjọba tí ó ń ṣe àbójútó ètò ìforúkọsílẹ̀, Valdemar José, sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ìbílẹ̀ Angola pé ìdíyelé fún ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú lásán-làsàn lọ sí òkè nítorí owó gegere ni ó ń jẹ láti ṣe ìwé náà:

(…) O governo ajustou o valor real do passaporte e deixou de subvencioná-lo, dando, por exemplo, prioridade à questão da água, luz e dos produtos de primeira necessidade. As cédulas para a emissão dos passaportes têm um custo elevado, por causa dos elementos de segurança usados nos documentos e, que até então o Estado subvencionava os custos do mesmo.

(…) Ìjọba rí i wípé ó tó àsìkò láti sún owó ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà, ó sì ti yọ ọwọ́ọ Kílàńkóo rẹ̀ kúrò nínú kíkó  owó lé e lórí, kí ó ba lè ṣe, fún àpẹẹrẹ, pèsè omi, ináa mànàmáná àti àwọn ohun amáyérọrùn mìíràn. Ohun èlò fún ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà máa ń gbọ́n owó mì, nítorí iṣẹ́ ìdáàbòbò oríi rẹ̀, tí àjọ ọba ń kówó lé lórí tẹ́lẹ̀ kí ó tó di ìgbà yìí.

Èyí jẹ́ ìrántí ohun tí ojú àwọn ọmọ Mozambique rí ní ìparí ọdún-un 2018, nígbàtí ìjọba pinnu láti fi owó kún ìwé àṣẹ gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ó bá ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà, tí ìdíyelée rẹ̀ fi ìdá 500 gbéwó lórí.

Àfilé iye owó náà ti dá awuyewuye sílẹ̀. Ìfẹ̀hónúhàn ọ̀dọ̀ tí ó tó bíi 100 wáyé ní ọjọ́ kẹ́rin oṣù Èrèlé, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìlú kan tí ó rí ìgbésẹ̀ ìjọba gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn fún ìrìnàjò ṣíṣe.

Ìfẹ̀hónúhàn náà 

Ìfẹ̀hónúhàn ní Luanda (ọjọ́ kẹrin oṣù Èrèlé). Àwòrán láti ọwọ́ọ  Simão Rossi, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Ní ọjọ́ kẹrin oṣù Èrèlé, Global Voices bá Fernando Gomes, ajìjàǹgbara ọmọ orílẹ̀ èdè Angola tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alátìlẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn náà tàkùrọ̀sọ, láti mọ ohun gbogbo tí ó rọ̀ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó sọ fún wa:

Essa forma encontrada para apelar a sensibilidade do executivo de João Lourenço, que esta não é a melhor fase para o aumento do preço, pois os cidadãos perderam o poder de compra de forma exponencial. (…) E que a tão aludida diversificação da economia angolana não pode passar exclusivamente pela elevação dos impostos direitos, visto que estes incidem apenas aos cidadãos, a classe política têm vários privilégios, que são custeados pelo cidadão de si já empobrecido”.

Èyí [ni ọ̀nà kan] fún ìpèsí àkíyèsí ìjọba João Lourenço, wípé àfilé ìdíyelé kò yẹ nírú àsìkò yìí, nítorí owó náà ti ṣe gegere ju fún àwọn ọmọ ìlú. (…) Àti pé “iṣẹ́ ìdàgbàsókè ọrọ̀ Ajé orílẹ̀-èdè Angola” kò lé wáyé nípasẹ̀ àfilé owó orí, nítorí wípé àwọn ọmọ ìlú ni ó ń fi orí kó o, àwọn tí ó wà ní ipò ìjọba ní àǹfààní tí ó pọ̀ ní ìkáwọ́ọ wọn, tí ó ṣe pé àpò ará ìlú tí ó ń rùnpà ni wọ́n ti ń mú owó tí wọ́n ń ná.

Àwọn alátakò ti sọ pé ó ṣe pàtàkì láti rántí wípé ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà dúró fún ìdánimọ̀ ọmọ ìlú ní òkè òkun, torí ìdí èyí, kò ṣe é yẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.

Vamos ficar todo mês de Fevereiro nas ruas da cidade capital, de forma intercalada, dia 4 de Fevereiro foi o arranque das manifestações, mas dia 7 voltaremos às ruas, e novamente estaremos no dia 11 e dia 13 faremos uma reunião de balanço, caso não haja recuo do executivo na aplicação do decreto presidencial.

A máa wà ní ojú òpópónà ní olú ìlú fún oṣù Èrèlé, ní àwọn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí a yàn, ọjọ́ kẹrin oṣù Èrèlé ni ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ní ọjọ́ kéje ni a máa padà sí ojú òpópónà, tí a óò tún wà ní ọjọ́ kankànlá, tí a ó sì jábọ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá, bí ìjọba kò bá yí ohùn padà.

Àwọn akọrin ewì-alohùn ráàpù, Lilo Kwanza àti Adérito Gonçalves, kọ orin kan, tí wọ́n sì ya àwòrán-an orin tí ó dá lóríi ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn yìí, “Ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà 30,000″ ni àkọlé orin náà, tí ó ń ṣe ẹ̀fẹ̀ lórí iye owó tabua tí ọmọ-ìlú yóò san fún ìwé ìrìnnà.

Ó ku ọjọ́ díẹ̀ kí ìwọ́de náà ó kò, ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Angola Pedrowski Teca sọ wípé ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnná pọn dandan ju ìwé ìdánimọ̀ pélébé lọ, ó rọ àwọn ènìyàn láti kọ́wọ̀ọ́ rìn, nítorí àìkọ́wọ̀ọ́ rìn, ní í ṣe ikú pa ọmọ ejò:

Manifestação Internacional contra a subida absurda do preço dos Actos Migratórios.

OBS: O Bilhete de Identidade (B.I) só identifica o angolano dentro do território nacional. Fora de Angola, o B.I é inútil, pois o único documento de identificação válido é o passaporte.

Nós, dentro do país, vamos protestar e incentivamos os nossos compatriotas na diáspora a seguirem o mesmo caminho, pois o passaporte é mais útil para eles.

Àwọn àjọ àgbáyé ti dẹ̀yìn kọ Òfin Ìṣíkúrò tí ó pàṣẹ àfilé ìdíyelé tí ó gbéra nílẹ̀ fìrì tí ó sì lọ òkè lálá.

OBS: Ìwé ìdánimọ̀ pélébé (B.I) wúlò gẹ́gẹ́ bí àmì ìdánimọ̀ ní àárín ìlú Angola. Ní ẹ̀yìn odi ìlú Angola, pánda   tí kò wúlò ni ìwé ìdánimọ̀ pélébé, kò sí àmì ìdánimọ̀ kan tí ó wà bí kò ṣe ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà.

Àwa, tí a wà nínú ìlú, ni a ó fi ààbò bò tí a ó sì ké pe àwọn aráa wa ní òkè òkun, kí àwọn náà ó ké gbàjarè, nítorí ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà ṣe kókó fún wọn.

Kí ìròyìn náà ó ba hó ye létí àwọn ènìyàn, ajàfúnẹ̀tọ́ọ nì àti akẹ́kọ̀ọ́ Ifáfitì, David Mendes, kọ, ní ọjọ́ ìwọ́de náà, iṣẹ́-ìjẹ́ fún ààre orílẹ̀-èdè Angola João Lourenço:

Camarada presidente João Lourenço não foi pra isso que o povo angolano votou para o senhor em momento algum nas suas campanhas o senhor falou sobre a mudança de preços acerca dos documentos afinal de contas o quê que o senhor está pensar?

Onde é que fica a voz do povo? Já temos uma vida miserável com estás subidas de preçário o senhor tem noção da dificuldade que estás a criar neste povo? Sinceramente já não sabemos quem é o homem certo para governar a nossa Angola como é que fica o jovem que não tem um emprego de onde ele vai tirar o dinheiro para tratar os documentos?

Ọmọ-ẹgbẹ́ ààrẹ João Lourenço, kì í ṣe nítorí èyí ni àwọn aráa Angola ṣe yàn ọ́ sípò, kò sí ibi tí o ti sọ nínú ìpolongo ìléríi rẹ, o kò sọ pé ìwé ẹ̀rí yóò gbówó lórí, síbẹ̀ kí ni ò ń rò?

Kí ni ẹ fi ṣe ohùn àwọn mẹ̀kúnnù? A ti rí ìrora látàrí àwọn àfilé ìdíyelé, ǹjẹ́ o mọ ìṣòro tí ó ń fà fún àwọn ará ìlú? A kò tilẹ̀ mọ ẹni náà tí ó tọ́ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Angola, báwo ni ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ tí kò lábọ̀ yóò ṣe rí owó gba ìwé ẹ̀rí?

Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀, ìjọba kò ì tíì sọ tó, tàbí kí ó kéde láti sọ bóyá òun yóò mú ìdíyelé náà wálẹ̀.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.