Ìpolongo ìtakò Kérésìmesì ìlú China mú yíyan àjọyọ̀ le fún ọmọ-ìlú

Ohun tí a kọ sí ojú pátákó: “Gbé Ìgbésẹ̀ kí o sì kọ àjọ̀dún Òyìnbó” àti ” Ṣe ìgbélárugẹ àṣà ìbílẹ̀, kọ àjọ̀dún Òyìnbó”. Àwòrán láti Weibo.

Kérésìmesì ń sún mọ́ dẹ̀dẹ̀ ṣùgbọ́n kàkà kí inú àwọn tí ó ń gbé ní orí-ilẹ̀ ìlú China ò dùn, ọ̀pọ́ ti fi ẹ̀hónú-u wọn hàn lórí ìpolongo tí ó tako ayẹyẹ Kérésìmesì tí ó kà á sí àjọ̀dún Òyìnbó.

Ní ọdún 2017, ìgbìmọ̀ àgbà àti àjọ ìpínlẹ̀ lábẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú Communist ìlú China kọ ìwé àṣẹ kan tí a pe àkọlée rẹ̀ ní “Ìmọ̀ràn lórí imúdiṣíṣẹ iṣẹ́ ìgbélárugẹ àti ìdàgbà àṣà ìbílẹ̀ China dé ibi gíga “. Wọ́n la àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìsọjí àṣà bíi Ọdún Òṣùpá Tuntun àti Àjọ̀dún Àtùpà sílẹ̀, láì pa ìyìókù tì, gẹ́gẹ́ bí ìpàgọ́ tí ó jẹ mọ́ ti àṣà tí ó lákaakì.

Kí òfin yìí lè di àmúṣẹ, ìjọba China ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ètò ìpolongo kéékèèké mélòó kan fún ìkọ̀yìn sí àwọn ayẹyẹ tí kì í ṣe ti ìbílẹ̀ China. Ọdún nìín, ọjọ́ díẹ̀ sí Kérésìmesì, ìjọba ní àwọn ìlú ńlá bíi Langfang, ní agbègbèe Hebei, ti pa á ní àṣẹ fún ìsọ̀ gbogbo láti yọ ẹ̀ṣọ́ ọdún Kérésìmesì kúrò lójú títí àti fèrèsé.

Ọ̀rọ̀ àlùfànṣá tí ó dá lórí ìtako àjọ̀dún Òyìnbó ti gba ẹ̀rọ-alátagbà ìlú China kan, èyí mú kí yíyan ayẹyẹ Kérésìmesì láàyò le koko fún àwọn tí ó rò wípé ní ìkọ̀kọ̀ ni ayọ̀ àwọn gbọdọ̀ wà.

Ònlo Weibo Long Zhigao ya àwòrán ìròyìn orí WeChat ti rẹ̀ ní orí Weibo ní ìfihàn àríyànjiyàn. Kókó ìròyìn àkọ́kọ́ 1. Àjọ̀dún Òyìnbó ń bọ̀ lọ́nà dẹ̀dẹ̀. Kí a ṣe àjọyọ̀ àbí kí á máà ṣe é, ìbéèrè ni ìyẹn. 2. Ọmọ China ni mí n kò sì kí ń ṣe àjọyọ̀ Òyìnbó. 3. Sọ pé rárá fún ìṣàjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó nínú ọgbà ilé-ìwé. 4. Ẹgbẹ́ òṣèlú-ìpínlẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí àjọ̀dún Òyìnbó. Àjọyọ̀ àjọ̀dún ti wa di ọ̀rọ̀ ìṣèlú.

Láfikún-un Kérésìmesì, àkàsílẹ̀ àwọn àjọ̀dún Òyìnbó kò yọ Àyájọ́ Ọjọ́ Olólùfẹ́, Àjíǹde àti Halowíìnì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí ẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ka àjọ̀dún sí “ìgbógunti àṣà” tàbí “ìrẹ̀sílẹ̀ ìlú”.

Fún àpẹẹrẹ, ọ̀kan tí ó ràn ká bí ìgbà tí iná bá ń jó pápá inú ọyẹ́ sọ wípé:

如果一个民族的群体热衷于另一个民族的节日,这说明文化入侵已是极其严重了。党员干部如果认识不到这点,那就是丧失政治敏锐性,也失去了先进性。

Bí àwọn ènìyàn ìlú kan bá mú àjọyọ̀ àjọ̀dún ìlú mìíràn ní òkúnkúndùn ju bí ó ṣe yẹ, èyí fi hàn wípé orílẹ̀-èdè náà ń jẹ ìyà ìgbógunti àṣà. Bí ẹlẹ́gbẹ́ olóṣèlú kò bá mọ èyí, a jẹ́ wípé wọn kò ní ìkọbiarasí ìṣèlú wọ́n sì ti pàdánù ìlọsíwájúu wọn.

Awuyewuye náà tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá Eight-Nation Alliance, ẹgbẹ́ ìṣọ̀kan tí a dá ní ìdáhùnsí Tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun Akànṣẹ́ ní China láàárín-in ọdún 1899 àti 1901 nígbàtí àwọn àgbẹ̀ rokoroko fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba amúnisìn, ètò ìṣèlú ní ìlànà Krìstẹ́nì àti àṣà. Síwájú sí i, ó ní wípé ọjọ́ ìbíi Mao Zedong, bàbá ìsàlẹ̀ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti Èèyàn-an China, ni ó yẹ kí a kà sí Kérésìmesì ìlú China:

中国人民共和国第一任主席毛泽东,是他拯救人民与水火之中,我们应该将他的诞辰定为中国的圣诞节,拒绝洋节,从自己做起!

Alága àkọ́kọ́ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti China Mao Zedong ti yọ àwọn ènìyàn nínú ìṣòro. A gbọdọ̀ sọ ọjọ́ ìbíi rẹ̀ di Kérésìmesì China. Gbé ìgbésẹ̀ kí o kọ àjọ̀dún Òyìnbó.

Àmọ́ àwọn ènìyàn kan lórí Weibo kò rí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n kankan nínú àríyànjiyàn wọ̀nyí. Ẹnìkan sọ pé:

洋人过春节,中国人自豪,叫传统文化振兴……
中国人过个洋节,怎么又叫外来文化入侵了呢?
年轻过个洋节,只是图个热闹,又拉动消费,哪里不好?
有些人,把过个圣诞节和160年前的民族耻辱又扯上了,何必呢? ​

Bí àwọn Òyìnbó bá ń ṣe àjọyọ̀ Ọdún Òṣùpá Tuntun, àwọn aráa China á gbéraga wọ́n á sì rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìdàgbà ìsọjí àṣà ìbílẹ̀ China … Bí àwọn aráa China bá ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó, kí ni ìdí tí a fi kà wọ́n sí ìgbógunti àṣà? Àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó nítorí àríyá àti fún ayọ̀. Àwọn àjọ̀dún wọ̀nyí lè mú ìkóúnjẹjẹ gbòòrò, kí ni ó burú nínú ìyẹn?
Àwọn kan gbèrò wọ́n fẹ́ gbé àjọyọ̀ Kérésìmesì fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìrẹ̀sílẹ̀ ìlú tí ó wáyé ní 160 ọdún sẹ́yìn. Fún kí ni?

Ẹgbẹ́kíkó, ìkóraẹni-níjàánu

Àgbàrá òdì ọ̀rọ̀ sí Kérésìmesì ti ṣàn gba orí ẹ̀rọ-alátagbà ó sì ti mú kí àwọn òǹlò kan ó kó ara wọn ní ìjánu. Ònlo Weibo kan fi ẹ̀hónú hàn:

快圣诞了,朋友圈里的洋节反对派和反反对派又开始刚上了。爱过过不爱过拉倒呗,没必要非逼着别人认同自己的看法,所有人都站一边不挤啊?真要都站一边了,本来站在中间的我们为了保持平衡就只能站到另一边去了。

Kérésìmesì ń bọ̀ lọ́nà dẹ̀dẹ̀. Ní agbo ọ̀rẹ́ẹ wa, àgọ́ alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó àti alòdìsí alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó ń ṣe àríyànjiyàn. Kò kan ẹnikéni bóyá èèyàn féràn àjọyọ̀ tàbí kò fẹ́, kí ni ó dé tí àwọn ènìyàn ṣe fẹ́ràn láti máa fi túláàsì mú ẹlòmíràn gba èròńgbà ti wọn? Ojú kan tí gbogbo ènìyàn dúró sí ti kún. Fún àwa tí a wà láàárín, kí a ba mú un dọ́gba, a ní láti dúró sí ẹ̀gbẹ́ kejì.

Ìkìlọ̀ lórí ìtako àjọ̀dún Òyìnbó ní inú ọgbà ilé-ìwé. 

Awuyewuye ti kọjáa ti gbàgede orí ẹ̀rọ-alátagbà, ó kàn dé ilé-ìwé àti àjọ ìlú.

Àwọn òǹlo Weibo kan ti pín ìkìlọ̀ ilé-ìwé ti a fún akẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀kan nínú ìkìlọ̀ náà (ọ̀tún) ń tọ́ka sí òfin “Ìmọ̀ràn” ó sì rọ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ láti kọ àyájọ́ tí ó fi ara jọ ti Òyìnbó sílẹ̀.

Bákan náà ni ìkìlọ̀ rọ akẹ́kọ̀ọ́ láti fọ́n iṣẹ́-ìjẹ́ òdì-ọ̀rọ̀ ìgbógunti àṣà Òyìnbó ká sí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ lórí WeChat àti lórí àwọn irinṣẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ ẹ̀rọ-alátagbà mìíràn.

Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún ìyá kan nígbàtí ọmọọ rẹ̀ kọ ẹ̀bùn Kérésìmesì. Ìyá kọ sórí Weibo:

?:宝宝,你想要什么?圣诞礼物?
?:我不过洋节,因为圣诞节不是我们中国人自己的节日!

好吧,
果然是党和人民的好宝宝

Ìyá: Ọmọ mi, ẹ̀bùn wo lo fẹ́ fún Kérésìmesì?
Ọmọ: Èmi ò ní ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó kì í ṣe àjọ̀dún ìlúu China.
Ó dáa, dájúdájú onígbọràn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn ará ìlú ni ọ́.

Síbẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ṣe àròjinlẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ìbéèrè lórí òfin ilé-ìwé lórí Weibo:

学校范围内不让出现一切和Christmas有关的东西,不能互赠礼物,不能有装饰物,不让过所谓的“洋节”,这到底是要弘扬传统文化,还是对自己文化的一种不自信

Ilé-ìwé ti gbé ẹsẹ̀ lé ìṣẹ̀ṣọ́ọ Kérésìmesì nínú ọgbà ó sì ti sọ pàṣìpàrọ̀ ẹ̀bùn di èèwọ̀ ní ìpolongo ìtako àjọ̀dún Òyìnbó. Ǹjẹ́ fún ìdàgbàsókè àṣà ilẹ̀ China ni gbogbo ọ̀nà yìí tàbí àmì ìpàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ ẹni?

Àwọn kan ti yan ìṣàjọyọ̀ àjọ̀dún náà ní ìkọ̀kọ̀. Òǹlo Weibo kan sọ:

公司不让过“洋节”,人事小姐姐提前偷偷给发的平安果。预祝平平安安。

Ilé-iṣẹ́ ti sọ ayẹyẹ àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó di èèwọ̀. Ṣùgbọ́n akọ̀wé láti ẹ̀ka ètò-òṣìṣẹ́ ti fi òró Kérésìmesì (ẹ̀bùn Kérésìmesì tí ó wọ́pọ̀) fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹ jẹ́ kí a fẹ́ àlàáfíà.

Òǹlo Weibo mìíràn fi èròńgbàa rẹ̀ hàn pẹ̀lú ohun tí ó fẹ́ fún Kérésìmesì:

圣诞快乐!上帝我爱你!请圣诞老人给我一只大大的袜子,里面装着自由。

Ẹ kú ọdún Kérésìmesì! Mo nífẹ̀ẹ́-ẹ̀ rẹ olúwa! Bàba Kérésìmesì, jọ̀wọ́ fún mi ní ìbọsẹ̀ nílá gbàngbà pẹ̀lú òmìnira nínúu rẹ̀.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.