Burundi: Kọ Ìkọkúkọ sórí àwòrán Ààrẹ — kí o wẹ̀wọ̀n

Ààrẹ Jacob Zuma bẹ Burundi wo ní 25, oṣù Èrèlé ọdún 2016. Orísun àwòrán: ìjọba ZA. Flickr, àṣẹ CC.

Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà di ẹni àtìmọ́lé lọjọ́ Ìṣẹ́gun 12, oṣù Ẹrẹ́nà ní agbègbè Kirundo ní Àríwá Ìlà-oòrùn Burundi fún ẹ̀sùn-un kíkọ ìkọkúkọ sórí àwòrán Ààrẹ Pierre Nkurunziza nínú àwọn ìwé ìkọ́ni márùn-ún. Wọ́n fi ẹ̀sùntíta àbùkù bá Ààrẹ orílẹ̀-èdè” kàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ẹgbẹ́ Àwọn Àjọ tí ó ń ṣe Àmójútó ìwàlálàáfíà Àwọn ọmọdé ní Burundi (FENADEB) jábọ̀ pé wọ́n ti fi akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá sílẹ̀ lẹ́sẹkẹsẹ̀ nítorí pé ó ṣì kéré, kò sì tí ì tó ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Wọ́n jábọ̀ pé wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta lọ́jọ́ Ẹtì, 15 oṣù Ẹrẹ́nà ṣùgbọ́n àwọn mẹ́ta yòókù ṣì wà ní àtìmọ́lé. Àwọn ọmọ náà tí wọn kò ju ọmọ ọdún 15 sí 17 yóò ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún bí wọ́n bá jẹ̀bi ẹ̀sùn ìtàbùkù bá Ààrẹ orílẹ̀-èdè. Ìwé ìròyìn iwacu jábọ̀ pé àwọn ìdílé tí ọ̀rọ̀ náà kàn wà nínú ìdààmú gidi.

“Ìkọkúkọ [lórí àwòrán Ààrẹ] jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mú ìjìyà dání lábẹ́ òfin ilẹ̀ Burundi gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ ìwádìí Reuters kan ṣe sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́-orí àwọn ọ̀daràn náà lè jẹ́ ìdí fún ṣíṣe àdínkù ìjìyà ẹ̀sẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí.

Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kan tí kò dárúkọ araa rẹ̀ ṣe sọ, wọn kò yẹ àwọn ìwé ìkọ́ni wọ̀nyí wò fún àìmọye ọdún, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì máa ń pín in lò ni, fún ìdí èyí ó nira láti mọ ẹni tí ó kọ nǹkan sí i ní pàtó.

Ìṣẹ̀lẹ̀ tó fara jọ èyí ṣẹlẹ̀ ní 2016, lẹ́yìnin rògbòdìyàn sáà kẹ́ta Ààrẹ náà, nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ kọ ìkọkúkọ sórí àwòrán (Ààrẹ) Nkurunziza nínú ìwé ìkọ́ni. Àwọn aláṣẹ rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀sí gidi tí wọ́n sì lé ọgọọgọ̀rún akẹ́kọ̀ọ́ kúrò ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ lóríṣìíríṣi káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá ni wọ́n fẹ̀sùn ìtàbùkù bá adarí ìlú àti “ìhàlẹ̀ mọ́ ààbò ìlú” kàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n padà dá wọn sílẹ̀.

Wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà yìí gidigidi. Zeid Ra'ad Al Hussein, tí ó jẹ́ aṣàkóso fún ẹ̀ka ìjàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn lábẹ́ United Nations gbé àkọsílẹ̀ kan jáde ní 29, oṣù Òkúdù 2016:

Ẹ̀rù ń bà mí pẹ̀lú àwọn ìròyìn tí mò ń gbọ́ nípa lílé tí wọ́n ń lé àwọn ọmọ ní ilé-ẹ̀kọ́ àti bí wọ́n ṣe ń tì wọ́n mọ́lé nítorí ìkọkúkọ tí wọ́n kọ sórí àwòrán Ààrẹ nínú àwọn ìwé ìkọ́ni.

Nkurunziza,’ Adarí ayérayé tó ga jù’

Ààrẹ Pierre Nkurunziza ti Burundi. Àwòrán láti ọ̀dọ̀ Eric Miller / Àjọ ọrọ̀-ajé àgbáyé, ìpéjọ Adúláwọ̀ ní 2008, Cape Town, 3 sí 6, oṣù Òkúdù 2008. Àwòrán lọ́dọ̀ Flicker (CC NÍPA-NC-SA 2.0).

Pierre Nkurunziza ti jẹ ààrẹ ilẹ̀ Burundi láti ọdún 2005. Ní ọdún 2015, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlúu rẹ̀ tún gbé e sípò fún sáà kẹ́ta lórí oyè.

Ní oṣù Ẹrẹ́nà ọdún tó kọjá, Nkurunziza gba orúkọ tuntun lọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlúu rẹ̀, Àjọ Agbèjà Òmìnira Àwọn Ológun – Fún Ìgbéga Ìjọba Oníbò (CNDD-FDD). Wọ́n pè é ní “adarí ayérayé tó ga jù”.

Akọ̀wé gbogboògbò fún CNDD-FDD, Evariste Ndayishimiye ṣàlàyé ìdí tí orúkọ náà ṣe di ti Nkurunziza:

Olùdaríi wa ni, kò sí eni tí a lè fi wé e nínú ẹgbẹ́ẹ wa. Òun ni òbíi wa, òun ni ó ń gbà wá nímọ̀ràn. Ìdí nìyí tí mo ṣe ní kí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pọ́n ọn lé nítorí pé ojúkójú ni ẹnikẹ́ni lè fi wo ilé tí kò ní olórí. Ní tiwa, olórí tó dára jù ni a ní.

Bí àwọn CNN-FDD ṣe gbé oyè náà ní yẹpẹrẹ tó ipò agbára Nkurunziza gẹ́gẹ́ bí adarí ayérayé tó ga jù ti jẹ́ kí ó nira fún ẹnikẹ́ni láti kọ ohunkóhun tí ó bá yàn láti ṣe, títí mọ́ ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti ṣe àyípadà òfin sáà méjì fún ipò adarí tí ó wà nínú ìwé òfin orílẹ̀-èdè náà. Èyí ń ṣe àfihàn àdálò tí ẹgbẹ́ òṣèlú tó wà lórí oyè ń dá agbára lò pẹ̀lú Nkurunziza àti àwọn alátìlẹyìn-in rẹ̀ pẹ̀lú bí ẹgbẹ́ òṣèlú náà ṣe ń darí àwọn ìdásílẹ̀ ìjọba.

Àwọn oníkọkúkọ ní ìṣọ̀kan

Àwọn ọmọ ìlú tí wọ́n ń ṣàmúlò ayélujára ti bẹ̀rẹ̀ ìkọkúkọ sórí àwòrán ààrẹ Nkurunziza nínú ìfẹ̀hónúhàn pẹ̀lú àmì ìdámọ̀: #Nkurunziza àti #Burundi:

Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ẹ̀wọ̀n fún kíkọ ìkọkúkọ sí orí àwòrán Ààrẹ #Nkurunziza.

Ìfòfinlíle mú àtakò

Ìjọba Burundi ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìkanra mú ìwà àtakò láti ọdún 2015, lẹ́yìn ìjákulẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ kan, ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ adìtẹ̀ kan, àtakò lórí ìlòkulò ẹ̀tọ́, òfin kànńpá, ìnira pẹ̀lú ètò ọrọ̀-ajé àti rògbòdìyàn àwọn asásàálà. European Union pẹ̀lú United Nations tako ìgbésẹ̀ Nkurunziza fún sáà kẹ́ta, wọ́n sì béèrè fún ìdápadà ìlọdéédé kí àsìkò ìdìbò ó tó dé. Pẹ̀lú àwọn ìdojúkọ wọ̀nyí, “ipò náà” le sí i. Àwọn aláṣẹ sì ń fi ìkanra mú gbogbo ìhàlẹ̀ tí wọ́n ń rí.

Ìjábọ̀ pàtàkì ti àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn ṣe ní oṣù Èbìbí 2018 rí i pé àwọn èṣọ́ aláàbò ní Burundi, àwọn afòyeṣiṣẹ́ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà nípò, àwọn ẹgbẹ́ Imbone… ń kọlu àwọn alátakò àti àwọn ẹni tí wọ́n fura sí gẹ́gẹ́ bí alátakò pẹ̀lú ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn àti akọ̀ròyìn. “Wọ́n pa èèyàn tó tó 1700, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń fi ipá lé àwọn ẹlòmíìn, wọ́n ń fi ipá bá wọn ní ìbálòpọ̀, wọ́n ń fi ìyà jẹ wọ́n, wọ́n ń tì wọ́n mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń dẹ́rùba àìmọye àwọn mìíràn”.

Èyí ti dá wàhálà ìsásàálà sílẹ̀, a ti rí àwọn ará Burundi tí wọ́n sá lọ sí Tanzania, Rwanda, Congo àti Uganda. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti padà sílé. Alákòóso United Nations fún ìsásàálà ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn asásàálà tí ó wá láti Burundi tí wọ́n lé ní 347,000 ní oṣù Èrèlé 2019, UNHCR fìdí ẹ̀ múlẹ̀:

…Làásìgbò nínú òṣèlú Burundi le sí i ní ọdún 2015 lẹ́yìn tí ààrẹ́ kéde èròńgbàa rẹ̀ láti lọ fún sáà kẹ́ta. Ìfẹ̀hónúhàn àwọn èèyàn láti tako èròńgbà fa ìkọlura, ọgọọgọ̀rún àwọn èèyàn sì sá lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè ìtòsí láti fi oríi wọn pamọ.”

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, ìjọba Burundi ti ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn lábẹ́ United Nations tí wọ́n sì sọ pé àwọn kò nílòo wọn mọ́. Ìjọba náà ń bínú sí alákòóso tẹ́lẹ̀-rí ẹ̀ka náà, Zeid Ra'ad Al Hussein tí ó ṣàpèjúwe Nkurunziza ti Burundi gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára “àwọn apanilẹ́kúnjayé ènìyàn tí ó ń gbèrú sí i láìpẹ́ yìí” ní oṣù Èrèlé 2018.

Àtipa àwọn Ilé-iṣẹ́ Akọ̀ròyìn, ìyọlẹ́nu àwọn alátakò, ìfòfinlíle mú àwọn ìdásílẹ̀ tí kì í ṣe ti ìjọba (NGOs) àti ìdiwọ́ fún àwọn mìíràn láti sọ̀rọ̀ tàbí ṣe àfihàn ara wọn ní ààyè òṣèlú.

Fún àpẹẹrẹ, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélọ́gbọ̀n fún ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn Germain Rukiki fún “ìdarapọ̀ mọ́ ìgbìyànjú ìrúlùú, “jíjin ètò ààbò ìlú lẹ́sẹ̀, àti ìṣọ̀tẹ̀” ní 2018 nítorí pé ó ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀nà tí ìjọba Nkurunziza ń gbà fìyà jẹni. Àwọn àìṣedede kan dá ìgbẹ́jọ́ Rukiki dúró, ó sì wáyé ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú àríyànjiyàn ìdìbò abófinmu náà.

“Ọ̀rọ̀ ìkọkúkọ” náà ń ṣe àfihàn ìdúróṣánṣán ìjọba náà tí kò yẹ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ẹ̀tọ́ọ wọn, títí mọ́ ṣíṣe ìgbéyàwó kànńpá fún àwọn tọkọtaya tí wọ́n ń gbépọ̀ láìṣe ìgbéyàwó ní 2017: ìfòfinlíle mú òwòo panṣágà àti agbe ṣíṣe.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.