Wọ́n fagi lé ìfìwépè Adarí iléeṣẹ́ tó ń ṣètò Ìṣàjò-papọ̀-wa-ọkọ̀-kí-n-wa-ọkọ̀ sí iléeṣẹ́ tẹlifíṣàn Russia lẹ́yìn tí olóòtú ètò rí i pé obìnrin ni

Àgékúrò àwòrán adarí iléeṣẹ́ náà, Irina Reyder ní ọ́fíìsì iléeṣẹ́ BlaBlaCar ti Russia. Àwòrán láti orí Ojú ewé. Facebook

Irina Reyder tí ó jẹ́ adarí iléeṣẹ́ BlaBlaCar ní Russia ní wọ́n fagi lé ìfìwépè òun sí ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ kan pẹ̀lú iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán-an ti ìjọba, Channel One lẹ́yìn tí olóòtú náà rí i pé obìnrin ni òun.

Reyder kọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà sójú ìwé Facebook rẹ̀. Ó ní òun gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìpè olóòtú ètò náà pẹ̀lú aṣojú ilé iṣẹ́ BlaBlaCar fún ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwùjọ tí òun sì gba ohùn-un wọn sílẹ̀:

Р (редактор передачи “Доброе утро”): Формат будет такой: корреспондент едет за рулем и берет интервью у вашего эксперта.

PR (PR – менеджер BBC): Да, отлично.

Р : А кто будет спикером?

PR: Наш генеральный директор Ирина Рейдер.

Р : Ой….у вас же был замечательный парень ..

С: Да, у нас был генеральный директор Алексей Лазоренко, а сейчас Ирина Рейдер.

PR : Да, я знаю, что в прошлом году у вас сменился генеральный директор. Но Ирина как спикер не подходит. Понимаете, у зрителя есть стереотипы… Ну, там, хороший юрист – это мужчина. Или автомобильный эксперт – мужчина, но не женщина. Может быть вы, Сергей, сможете дать нам интервью?

E (Olóòtú ètò “Ojúmọ́ Ire”): Báyìí ni a ṣe gbèrò láti ṣe é; akọ̀ròyìn-in wa á máa wa ọkọ̀ bí yóò ṣe máa fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ lẹ́nu alámọ̀dájúu yín.

PR (Aṣojú iléeṣẹ́ BlaBlaCar fún ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwùjọ): Bẹ́ẹ̀ ni, Ìyẹn dára

E: Ta ni yóò wá jẹ́ alámọ̀dájú náà?

PR: Adarí iléeṣẹ́ wa ni, Irina Reyder

E: Ẹ̀n… Ẹ ti fìgbà kan ní ọkùnrin tó dára ní ipò náà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

PR: Bẹ́ẹ̀ ni, a ti ní Alexey Lazorenko gẹ́gẹ́ bí Adarí,  Irina Reyder ni nísẹ̀yín.

E: Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa àyípadà tí ó wáyé nínú ìdarí iléeṣẹ́ yín lọ́dún tó kọjá. Ṣùgbọ́n Irina kò ní le è wúlò gẹ́gẹ́ bí alámọ̀dájú, ó nírú ẹni tí àwọn olùgbọ́ọ wa máa ń nífẹ̀ẹ́ sí. Fún àpẹẹrẹ, tí a bá ní agbẹjọ́rò gidi kan. Ó ń láti jẹ́ ọkùnrin. Tàbí ẹni tí ó mọ̀ nípa ọkọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ – ọkùnrin ni, kó má jẹ̀ ẹ́ obìnrin. Bóyá kí ìwọ Sergey ó ṣe ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ náà?

Lẹ́yìn tí aṣojú iléeṣẹ́ náà fún ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwùjọ, Sergey sọ fún olóòtú ètò náà pé kò sí alámọ̀dájú ọkùnrin kankan ní iléeṣẹ́ naa, ó ní olóòtú ètò náà ṣe ìlérí láti padà wá lẹ́yìn tí ó bá ti bá olóòtú àgbà ètòo wọn sọ ọ́. Nínú ìpè kan lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n sọ fún aṣojú iléeṣẹ́ BlaBlaCar pé ètò náà ti yí padà, pé àwọn á máa ṣe ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn oníbàáràa wọn dípò wọn.

“Kí lẹ rò? Ṣé àwọn alámọ̀dájú tuntun yìí á mọ̀ dájú dánu? Reyder ń béèrè ìbéèrè ìkẹ́gàn náà lọ́wọ́ àwọn èèyàn-an rẹ̀.

Nínú èsì kan sí TJournal, tí ó jẹ́ iléeṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àti ìròyìn ẹ̀rọ alátagbà àti orí ayélujára. Ẹ̀ka ìròyìn Channel One ò fi òtítọ́ ìtàkùrọ̀sọ yìí pamọ́, ṣùgbọ́n wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀rọ̀ náà kò ṣègbè lẹ́yìn akọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlàyé wọn kò fìdí èyí múlẹ̀ tó:

Два корреспондента — молодой человек и девушка – планируют продемонстрировать мужской и женский подход к экономии. При этом девушка советуется с мужчинами-экспертами, а молодой человек — с экспертами-женщинами. Поскольку девушка планирует экономить на поездках, ей предстоит разговаривать с представителем сервиса поиска попутчиков (да, по задумке этого сюжета, а не из-за гендерного неравенства, он должен быть мужчиной).

Akọ̀ròyìn méjì, ọkùnrin àti obìnrin kan ń gbèrò láti ṣàfihàn ìyàtọ̀ tí ó wà nínúu bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń hùwà sí ìfowópamọ́. Akọ̀ròyìn lóbìnrin á ní láti fọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú alámọ̀dájú ọkùnrin kan nígbà tí Akọ̀ròyìn lọ́kùnrin á ní ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin. Nítorí pé èròńgbà Akọ̀ròyìn obìnrin yẹn ni láti wo bí wọ́n ṣe ń tọ́jú owó bí wọ́n bá gbé ọkọ̀, a nílò láti bá aṣojú iléeṣẹ́ tó ń ṣètò ìrìnnà-papọ̀-wa-ọkọ̀-kí-n-wa-ọkọ̀ kan sọ̀rọ̀ (bẹ́ẹ̀ ni, nítorí àlàkalẹ̀ ètò náà ni, kì í ṣe nítorí àìfẹ́dọ̀ọ́gba akọ àtabo, ó ní láti jẹ́ ọkùnrin).

Channel One ò sọ bí ìyàtọ̀ ṣe wà láàárín bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń ronú sí ìfowópamọ́. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ tako ìhùwàsí iléeṣẹ́ tẹlifíṣàn yìí.

Adarí iléeṣẹ́ BlaBlaCar, Irina Reyder sọ pé wọ́n fagi lé ìfìwépè òun wá sórí ètò Ojúmọ́ Ire lórí Channel One lẹ́yìn tí olóòtú rí i pé obìnrin ni òún jẹ́. Ó yani lẹ́nu pé àwọn ohun kan ṣì wà nínú ìyírí àwọn Channel One tí a kò mọ̀.

Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ burúkú tí Channel One gbọ́ lórí ayélujára, Russia sì ní iṣẹ́ ńlá láti ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìbádọ́gbà akọ àti abo. Russia wà ní ipò 75 nínú àwọn orílẹ̀-èdè 149 tí Àjọ tó-ń-ṣètò-ọrọ̀-Ajé Lágbàáyé ṣàyẹ̀wò fún lọ́dún 2018 nínú Ìjábọ̀ Àlàfo tó wà láàárín Akọ àti Abo Lágbàáyé, ó ń ṣe dáadáa ní ti ìbádọ́gbà nínú rírí ètò ìlera àti ètò ẹ̀kọ́ lò fún àwọn obìnrin, ṣùgbọ́n wọ́n ń fà sẹ́yìn nínú ètò ìṣòfin láti jà fún ẹ̀tọ́ọ wọn. Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ abo ní Russia máa ń sábàá lo gbàgede ẹ̀rọ alátagbà àti ẹ̀fẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ìhùwàsí àti ìṣe àwọn tí ó ń ṣègbè lẹ́yìn ẹ̀yà ènìyàn kan.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.