Ọjọ́ 23, oṣù kejì ọdún-un 2019 ni àwọn ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà gba ẹ̀ka ìdìbò lọ láti dìbò yan ààrẹ àti ọmọ ìgbìmọ̀ tuntun sípò. Àwọn méjì gbòógì òǹdíjedupò sí ipò ààrẹ, Ààrẹ tí ó wà lórí àléfà kó ìbò ẹgbẹẹgbẹ̀rún 15 tí ó mú u borí olórogún-un rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí, Atiku Abubakar, pẹ̀lú “àlàfo idà 56 sí ìdá 41.” A ṣe ìbúra fún Buhari fún sáà kejì ọlọ́dún mẹ́rin lọ́jọ́ 29, oṣù karùn-ún, 2019.
Kà sí i: #NigeriaDecides2019: Ohun gbogbo tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdìbò gbogboògbò ti ọdún nìí
Síbẹ̀, ohun gbogbo tí ó gbà ni wọ́n fi ṣe ìpolongo ìbò náà, láì yọ bíbẹ ẹ̀rọ alátagbà lọ́wẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin tòun ìwà ẹlẹ́yàmẹyà àti ìròyìn irọ́ ràn bíi pápá inú ọyẹ́ ní orí ẹ̀rọ ayélujára, pabambarì lóríi gbàgede Twitter.
Ìkórìíra Ẹ̀yà ní Nàìjíríà
Ẹ̀yà onírúurú – tí ó tó bíi 250 àti èdè 500 – ti fi ìgbà kan jẹ́ orísun àìbalẹ̀ọkàn dípòo ìfọ̀kànbalẹ̀. Èyí fi ojú hàn lásìkò ìbò nígbàtí àwọn olóṣèlú lo ẹlẹ́yàmẹ́lẹ́yá fi polongo ìbò. Láti ilẹ̀, ìtàkùrọ̀sọ lórí ayélujára ní Nàìjíríà kò lọ láì sí ìkórìíra.
Lásìkò ìbò ọdún-un 2015, fún àpẹẹrẹ, gbàgede Twitter ní orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà di ibi ìkorò àti ibi ìdíje ìjuwọ́ láàárín àwọn alátìlẹ́yìn àwọn òǹdíje méjì ìgbà náà, Goodluck Jonathan (PDP, ọmọ lẹ́yìn Krístì tó jẹ́ ọmọ Ijaw) àti Muhammadu Buhari (APC, Ìmàle, Hausa, Fulani). Twitter di irinṣẹ́ fún ìgbéròyìn ìkórìíra ẹ̀yà tẹ̀gbintẹ̀gbin jáde àti ohun èlò fún ẹgbẹ́ olóṣèlú.
Àwọn kan lérò wípé ọdún-un 2019 yóò yàtọ̀ nítorí pé Buhari ti ẹgbẹ́ẹ Àjọ Ìtẹ̀síwájú Gbogboògbò (APC) àti Abubakar láti Ẹgbẹ́ olóṣèlú Ìjọba-tiwantiwa Àwọn Ènìyàn (PDP) tí àwọn méjèèjì sì jẹ́ Hausa, Fulani Ìmàle, àmọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ ló rí. Àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn – Yẹmí Ọṣìńbàjò (APC), ọmọ Yoruba, àti Peter Obi (PDP), ọmọ Igbo, jẹ́ Ọmọ-lẹ́yìn-in-krístì — àmọ́ láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó fẹ́ jọ àtúnwáyé ìṣẹ̀lẹ̀ 2015 ṣùgbọ́n pẹ̀lú atakànàngbọ̀n mìíràn.
Ohun gbogbo nípa ìṣèlú Nàìjíríà wọṣọ ẹlẹ́yàmẹ́lẹ́yá ní 2017, ọdún méjì kí ìbò ó tó bẹ̀rẹ̀, tí ó sì fa àìgbàgbọ́ nínú ètò ìṣèlú. Ẹgbẹ́ ajìjàngbara ọmọ ìbílẹ̀ Biafra Indigenous People of Biafra (IPOB), tí ó jẹ́ àgbáríjọpọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà tí Nnamdi Kanu jẹ́ olórí, dá kún rògbòdìyàn tí ó ń rọ́ tìtì.
Ìdi-aṣálẹ̀-ilẹ̀ ní àríwá Nàìjíríà ló mú kí àwọn ọlọ́sìn-ẹran tí ó jẹ́ darandaran tí ó ń bá àwọn àgbẹ̀ jà ó wà sí apá gúúsù. Àwọn Ọmọ-lẹ́yìn-in-krístì kan “rí gbígba àwọn Fulani darandaran tí ó jẹ́ Ìmàle tọwọ́tẹsẹ̀ wọlé sí apáa gúúsù gẹ́gẹ́ bíi ìgbésẹ̀ láti ‘Sọnidìmàlè’ ní tipátipá.” Ìkọ̀jálẹ́ ìjọba Nàìjíríà láti ṣe ìwádìí sí àwọn ìkọlù tí ó ń wáyé àti “fífimú àwọn tí ó ṣẹ̀ sófin dánrin”, tí ìkọlù náà sì fa ikú àwọn ènìyàn tí ó tó bíi ẹgbẹ̀rún 4 láti ọdún-un 2015 sí 2018, gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ Amnesty International ti ṣe ní i lákọsílẹ̀.
Láti ìhín lọ, ẹlẹ́yàmẹyà ti ń peléke sí i kí ó tó di àsìkò ìbò ààrẹ ọdún-un 2019. Àìnígbàgbọ́ tí ó wà nílẹ̀ ló fi àyè gba ìgbéjáde ìròyìn irọ́ – lójúkorojú àti lórí ayélujára – lásìkò ìbò.
Ìbò àti ìgbàgbọ́ ọ̀rọ̀ orí ẹ̀rọ ayélujára ní Nàìjíríà
Iye àwọn òǹlò ẹ̀rọ ayélujára ní Nàìjíríà fò fẹ̀rẹ̀ sókè láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún 98.3 ní ọdún-un 2017 sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún 100.5 ní 2018. Facebook ló léwájú gẹ́gẹ́ bí i gbàgede ààyò ọ̀pọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà pẹ̀lú òǹlò ẹgbẹẹgbẹ̀rún 22, tí gbàgede àwòrán-àtohùn YouTube (ẹgbẹẹgbẹ̀rún 7 àti jù bẹ́ẹ̀ lọ) tẹ̀lé e, Twitter (ẹgbẹẹgbẹ̀rún 6) àti Instagram (ẹgbẹẹgbẹ̀rún 5.7).
Ọ̀dọ́ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùdìbò orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà. Lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún 84 àwọn olùdìbò tí ó forúkọsílẹ̀ fún Ìbò Àpapọ̀ ọdún-un 2019, tí ìdajì — ìdá 51 — jẹ́ ọ̀dọ́ òǹdìbò tí ọjọ́ oríi wọ́n tó ọdún 18 àti 35, tí ìdá 30 sì jẹ́ ẹni ọdún 36 àti 50. Àwọn ọjọ́-orí méjèèjì yìí, tí ó ní onímọ̀ nípa ìlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá àti àwọn aṣípò sórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá, ni ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn olùdìbòo Nàìjíríà.
Torí ìdí èyí, kò yanilẹ́nu wípé ẹ̀rọ ayárabíàṣá jẹ́ gbàgede kan gbòógì fún fífi ìpolongo ìbò ọdún-un 2019 sọta ìjà lura ẹni.
Látàrí èyí, ó mú u ṣòro láti gbọ́kàn tẹ àwọn ìròyìn orí ayélukára-bí-ajere lásìkò ètò ìdìbò tó wáyé lọ́dún-un 2019. Ìròyìn irọ́ tí kò ní gbọ́ngbọ́n nínú ni wọ́n polongo gẹ́gẹ́ ìhìn rere tòótọ́, tí àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ olóṣèlú méjèèjì tí ó gbajúmọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà sì lukoro rẹ̀: Àjọ Ìtẹ̀síwájú Gbogboògbò All Progressive Congress (APC) àti Ẹgbẹ́ olóṣèlú Ìjọba-tiwantiwa Àwọn Ènìyàn People's Democratic Party (PDP).
Gẹ́gẹ́ bí ìkíyèsí ẹ̀yà tí ó wáyé láàárín ọjọ́ 28 oṣù kẹwàá, 2018, àti ọjọ́ 29, oṣù karùn-ún 2019, ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹ̀yà tẹ̀gbintẹ̀gbin jẹ́ irinṣẹ́ fún ìròyìn tí kò ní gbọ́ngbọ́n ń'nú tí ó kún fún irọ́ láti sàkání ẹgbẹ́ olóṣèlú méjèèjì ní oríi Twitter ti Nàìjíríà lásìkò ìbò ààrẹ 2019. A ká àwọn ìkíyèsí yìí sílẹ̀ láti orí ayélujára ní àsìkò yìí.
Tí a bá sọ nípa ìròyìn irọ́ nípa ti ẹlẹ́yàmẹyà, àwọn agbárùkù ti ẹgbẹ́ olóṣèlúu APC yọ ẹnu ìwọ̀sí sí Obi lára nítorí pé ó dá àwọn ará òkè Ọya padà nígbà tí ó wà lórí ipò gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ Ìpínlẹ̀ Anambra, ní ìlà-oòrùn gúúsù orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà. Túwíìtì tàn kárí ilé kárí oko tí ó sọ pé àwọn ọmọ Yorùbá ń tiná bọ ìsọ̀ àwọn oníṣòwò tí ó jẹ́ ẹ̀yà Igbo ní Èkó. Irọ́ funfun báláwú ni àwọn ìròyìn wọ̀nyí, a ó gbé e yẹ̀ wò síwájú sí i nínú Apá kejì àròkọ yìí.
Fún àpẹẹrẹ òmíràn, a lo àwòrán kan báyìí lọ́nà tí kò yẹ. Lọ́jọ́ 28, oṣù kẹwàá, ọdún-un, 2018, Festus Keyamo, olùdarí ètò ìkéde àná fún Iléeṣẹ́ Ìpolongo fún Buhari, túwíìtì àwòrán kan (Aworan 1) ti igi kan tí ó ń wù láàárín ojú irin kan tí ó ti di àpatì: “Bí igí ṣe ń wù sí àárín ojú irin ní 1999 sí 2015… Báyìí, ‘Sáà Ìparí iṣẹ́’ rè é, àwọn ojú irin náà ti ń jí padà sáyé.” Ìjọba PDP ló ń tukọ̀ ètò ní 1999 sí 2015.
Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, òǹlò Twitter kan tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà tọ ipasẹ̀ẹ àwòrán náà sí túwíìtì kan lédèe Lárúbáwá (Àwòrán 2) tí ẹnìkan tari síta nínú oṣù yẹn. Túwíìtì náà jẹ́rìí wípé Lebanon ni àwòrán ọ̀hún ti ṣẹ̀ wá.
Ohun tí Keyamo fẹ́ ṣe ni láti fi hàn wípé ìṣàkóso ìjọba Buhari ti gbé ìgbésẹ̀ àtúnṣe sí àwọn ọ̀nà ọkọ̀ọ ojú irin tí ìjọba àná pa tì. Àmọ́ ṣá, àwòrán orílẹ̀-èdè mìíràn tí ó lò láti fi sọ “ìtẹ̀síwájú” náà, fọ́ gbogbo rẹ̀ lójú.
Ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹ̀yà tẹ̀gbintẹ̀gbin ṣẹ́ yọ kí ọjọ́ ìbò ó tó kò, lásìkò ìbò àti lẹ́yìn ìbò. Túwíìtì ẹlẹ́yàmẹyà kan (Àwòrán 3) Bashir El-Rufai, ọmọ Aláṣẹ Ìpínlẹ̀ Kaduna, wí pé ẹ̀yà Igbo ló fi ìbínú tan iná ọ̀tẹ̀ tí ó fa Ogun Abẹ́lée Nàìjíríà.
Láàárín 1967 sí 1970, orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ja ogun kíkorò kan pẹ̀lú ìlúu Biafra tí í ṣe àwọn ẹ̀yà Igbo tí ó wà ní apá ìlà-oòrùn gúúsù, tí ó ń gbèrò láti pín yà kúrò lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Nàìjíríà.
Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Bashir El-Rufai ti ṣe sọ, àbájáde ìbò ọdún-un 2019 tí ẹgbẹ́ẹ rẹ̀, APC, gbégbà-orókè. Ó yẹ kí a rí i bíi “ẹ̀san” láti apá ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Hausa, Fulani. Ó padà wá á tọrọ àforíjì, lẹ́yìn tí a ti bu ẹnu àtẹ́ lù ú, fún túwíìtì “tí ó lè dá wàhálà sílẹ̀” bí a ti rí i nínú Àwòrán. Bákan náà ni ó mú túwíìtì ìsọkúsọ náà wálẹ̀ (Àwòrán 3).
Ìròyìn irọ́ tí ó ti ara ẹlẹ́yàmẹyà wá lórí ẹ̀rọ-alátagbà lásìkò ìbò ṣe é pín sábẹ́ ẹ̀ka méjì: ìròyìn tí kò ní gbọ́ngbọ́n nínú àti ìròyìn irọ́.
Miroslav Tudjman àti Nives Mikelic, ọ̀mọ̀wé nípa ìtàkùrọ̀sọ ní Ifáfitì ti Zagreb, Croatia, túmọ̀ ìròyìn tí kò ní gbọ́ngbọ́n nínú sí “ìròyìn àmọ̀ọ́mọ̀ tari síta láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́kàn.” Ète títari ìròyìn irọ́ síta bí òtítọ́, ló ya ìròyìn tí ó ń ṣini lọ́kàn àti ìròyìn irọ́ sọ́tọ́.
Tudjman àti Mikelic sọ wípé ọ̀nà ìtànkálẹ̀ ìròyìn fẹ̀jú ju ìròyìn àmọ̀ọ́mọ̀ tari síta láti ṣini lọ́kàn tàbí ìròyìn irọ́ lọ. Ìdí ni pé ọ̀nà ìtànkálẹ̀ ìròyìn “máa ń yí ìhùwàsí ẹni padà” nípasẹ̀ “ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ kan tàbí ìgbésẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀ dá lásìkò ìtari ìtàkùrọ̀sọ [náà] síta.” Bí irú èyí, ọ̀nà ìtànkálẹ̀ ìròyìn máa ń tẹ̀sí apá kan tàbí àìpé ìròyìn fún àǹfààní ọ̀rọ̀ òṣèlú àti yíyí ìrònú padà níparí.
Ìbẹ̀rùbojo ọkàn bẹ́ sílẹ̀ látàrí ìbò ọdún-un 2019 nítorí ìròyìn irọ́ àti ọ̀nà ìtànkálẹ̀ ìròyìn ń ṣe àgbédìde àìbalẹ̀ ọkàn tí ó ti ọ̀rọ̀ ìbò bẹ̀rẹ̀ àmọ́ tí ó ń fa “ìdẹ́rùbà fún ìparí-ìjà tí ìbòó bá kásẹ̀ ńlẹ̀.”
Apá kejì àròkọ yìí yóò ṣe àgbéyẹ̀wò bí èyí ṣe wáyé lórí ayélujára, pàápàá lóríi gbàgede Twitter, pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan.
Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ara àtẹ̀jádé ìròyìn oníṣísẹ̀ntẹ̀lé tí ó ń ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣúsí pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ìlò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá nípa àwọn ìlànà bíi ìṣánpa ìṣàsopọ̀ ẹ̀rọ ayélukára-bí-ajere àti ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ lásìkò ètò ìṣèlú tí ó pọn dandan ní orílẹ̀-èdè méje ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀: Algeria, Ethiopia, Mozambique, Nàìjíríà, Tunisia, Uganda, àti Zimbabwe. Africa Digital Rights Fund àti The Collaboration on International ICT Policy for East and Southern Africa (CIPESA) ni agbátẹrù iṣẹ́ àkànṣe yìí.