Ọmọ Yoòbá · Ṣẹẹrẹ, 2020

Àṣẹ̀sẹ̀tẹ̀jáde ìròyìn látọwọ́ọ Ọmọ Yoòbá láti Ṣẹẹrẹ, 2020

Ilẹ̀-Adúláwọ̀ rí àbọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owóo dollar láti ọ̀dọ̀ Ilé-ìfowópamọ́sí ńláńlá fún ìgbéfúkẹ́ Iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá

  31 Ṣẹẹrẹ 2020

“Nítorí àìtó ìdókoòwò ń'nú iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá àti àṣà, Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò sí ń'nú ọjà iṣẹ́ ọpọlọ, àti ìdáraáwò ní àgbáyé," Benedict Oramah, ààrẹ Afreximbank ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ní Kenya àti Ethiopia, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ríran ‘àwòrán-ìtọ́nà’ àt'ọ̀run wá láti gbẹ́ ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀

  16 Ṣẹẹrẹ 2020

Láti ayébáyé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti ní kò sí ẹ̀rí tí ó dájú wípé ìran àt'ọ̀run wá ni àwọn irú àlá báwọ̀nyí, tí wọn ń dẹ́jàá ìlera ọpọlọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ tó pé òún ríran lójú àlá. Àmọ́ àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn Ìmàle, Júù àti Onígbàgbọ́ gbogboó ti jẹ́rìí sí ìran láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ent tí ó wá lójú àlá fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.