Àṣẹ̀sẹ̀tẹ̀jáde ìròyìn látọwọ́ọ Ọmọ Yoòbá láti Ṣẹẹrẹ, 2023
A lé òǹṣàmúlò TikTok Nekoglai láti Moscow padà sí Moldova pẹ̀lú àmì lúlù
“Orò ìjẹ̀bi àti ìtìjú” náà ni àwọn agbófinró orílẹ̀-èdè Russia pọwọ́lé lílò rẹ̀ láti fi “àbámọ̀” náà hàn ní gbangba àti ìpayà àwọn afẹ̀hónúhàn
‘Ìkòròdú bois’ ṣàfihàn bí àwọn gbàgede ẹ̀rọ-ayélujára ṣe ń ṣe ìgbélárugẹ àwọn eré àgbéléwò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà káàkiri àgbáyé
Pẹ̀lú irinṣẹ́ tí kò tó àti àwọn àmúlò irinṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, ikọ̀ ‘Ìkòròdù Bois’ ṣe ìsínjẹ àti àwàdà àwọn eré Hollywood àti Nollywood tí ó ti di èrò yà wá á wò ó kárí ayé lórí àwọn gbàgede ìbáraẹnidọ́rẹ̀ẹ́.
Orin ẹ̀hónú: àwọn ọ̀dọ́mọdé òǹkọrin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kọrin tako ìwà ìrẹ́jẹ láwùjọ
Àwọn ọ̀dọ́mọdé olórin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tẹ̀síwájú nínú àṣà kíkọ orin tako ìrẹ́jẹ láwùjọ. Èhónú #EndSARS ṣe ìtanijí ọkàn wọn sí ìkópa nínú ètò òṣèlú, eléyìí tí ó ti ń wòòkùn.