Àṣẹ̀sẹ̀tẹ̀jáde ìròyìn látọwọ́ọ Ọmọ Yoòbá láti Òkúdù , 2019
China fi ọwọ́ọ ṣìnkún òfin mú ayàwòrán eré orí ìtàgé nítorí pé ó tún àwòrán ìgò ọtí-líle kan tí ó ń tọ́ka sí Ìpanìyànnípakúpa Tiananmen pín
Ààmì ara ìgò náà ní àwòrán "Ọkùnrin ọkọ̀-ogun" tí a kọ "Máà ṣe gbàgbé, máà ṣe sọ̀rètí nù"
Ojúṣe láti ṣe ìrántí: ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn Tiananmen
Ní 1989, ikọ̀ ogun orílẹ̀-èdè China ṣíná bolẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn àtúnṣe ètò ìjọba àwarawa tí ó fa ìpaninípakúpa nínúu Gbàgede Tiananmen Square ní ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù. Fún 30 ọdún, a ṣe ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn àti arapa wọn.