Ààrẹ orílẹ̀-èdèe Amẹ́ríkà Donald Trump ti ré sí ipò ìsàlẹ̀ lójú àwọn ènìyàn kárí ayé látàrí àwọn òfin rẹ̀ àti bí ó ṣe ń ṣe ìṣàkóso ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ orílẹ̀-èdèe òkèèrè — àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Nàìjíríà.
Ní kò pẹ́ kò pẹ́ yìí ni ìwádìí àyẹ̀wò tí Pew Research Centre ṣagbátẹrùu rẹ̀ fi hàn wípé ọ̀gọ̀rọ̀ ọmọ Nàìjíríà “fi Ògún-un rẹ̀ gbárí” wípé Trump “yóò gbé ìgbésẹ̀ tí ó lààmìlaka nípa ti ọ̀ràn àgbáyé.”
Orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ojúkorojú ni Gallup – iléeṣẹ́ aṣàgbéyẹ̀wò fínnífínní àti iléeṣẹ́ olùdámọ̀ràn tí ó wà ní Washington, DC fi gba èsì jọ nínú ìwádìí àyẹ̀wò èrò àwọn ènìyàn-an fún Pew.
Àgbéyẹ̀wò Tweepsmap kan tí ó dá lóríi iye àwọn tí ó ń tẹ̀lé Trump lóríi ẹ̀rọ alátagbà Twitter ṣe òfófó wípé ipò karùn-ún ni Nàìjíríà dúró sí nínú àwọn orílẹ̀-èdè márùn-ún lágbàáyé:
Àfi bí a bá fẹ́ tanra wa jẹ, Trump gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ta ní Nàìjíríà. Kíyèsí i, mi ò kí ń ṣe olólùfẹ́ẹ rẹ̀ ṣùgbọ́n òtítọ́ pọ́nbélé ni pé àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́-ẹ rẹ̀ pọ̀ bíi kàá sí nǹkan.
— Omadi (@iamtenseven) Ọjọ́ 10 Oṣù kìíní, ọdún-un 2020
Bí-ó-ti-wù-kí-ó-rí, èyí kò ṣàlàyé ìdí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan án fi gba ti Trump.
Òǹkọ̀wé tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà Adaobi Tricia Nwaubani làdíi rẹ̀ fún àgbáyé lórí ètò ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan tí ó jẹ́ àbáṣepọ̀ pẹ̀lú BBC, wípé ìrísíi Trump gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin alágídí” mú kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ènìyàn jù lọ ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ó fẹ́ràn-an rẹ̀ dé góńgó:
Àwọn ènìyàn fẹ́ràn-an ìhùwàsí alágídíi rẹ̀ àti pé àìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n-ọn rẹ̀ dùn ún gbọ́ sétí. Àwọn ọmọ Amẹ́ríkà rí i bí àkàndá ènìyàn. Ìhùwàsíi rẹ̀ kò bá tayé mu. Kì í ṣe ẹni tí wọ́n sọ pé ó jẹ́. Àmọ́ irú olórí tí kì í lọ́ra sọ̀rọ̀ bí ó ti wù ú kò jẹ́ tuntun sí wa. Torí ìdí èyí, ìhùwàsíi rẹ̀ kò bàjẹ́ tó bẹ́ẹ̀ bí àwọn ọmọ Amẹ́ríkà ṣe ń rí i.
Ìdí mìíràn ni ẹ̀sìn. Àwọn Ọmọ lẹ́yìn-in Krístì nífẹ̀ẹ́ẹ Trump
Cheta Nwanze, Olórí Ìwádìí ní SBM Intelligence sọ fún Ohùn Àgbáyé:
Ó hùn mí láti mọ IBI tí wọ́n ti ṣe ìwádìí-àyẹ̀wò yìí ní Nàìjíríà, tí ó ṣàlàyé ìfẹ́ tí ọmọ Nàìjíríà ní sí Trump. Mo mọ̀ dájú wípé kì í ṣe káríi gúúsù orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn olólùfẹ́ẹ rẹ̀ l'ó jẹ́ Onígbàgbọ́, tí wọ́n ń gbójú sókè wò ó bí àwòkọ́ṣe rere.
Nàìjíríà, pẹ̀lú iye ènìyàn ìlú tí ó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún 200 èèyàn, ní ẹ̀sìn méjì tí àwọn ènìyàn-án ń ṣe jù: ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ àti Ìmàle. Ìmàle àti Ìgbàgbọ́ kó ìdá 50 àti ìdá 48 iye gbogbo ènìyàn t'ó ń gbé Nàìjíríà.
Ìlànà ìwádìí náà fi hàn wípé “iléeṣẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ tí wọ́n sì pín àwọn ènìyàn sí agbègbè” ni wọ́n ti ṣe ìwádìí àyẹ̀wò yìí. Bí ó ti wù kíó rí, kò sí ohùn àwọn Adamawa, Borno, àti ìpínlẹ̀ Yobe ní àríwá ìlà-oòrùn Nàìjíríà nínú àbájáde ìwádìí náà nítorí ọ̀rọ̀ ààbò.
Nàìjíríà ní ìjọba ìbílẹ̀ 774, tí í ṣe ẹ̀ka aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀. Bákan náà ni ó ní ẹ̀ka àkóso mẹ́fàá: Àárín gbùngbùn Àríwá, Àríwá Ìlà-oòrùn, Àríwá Ìwọ̀-oòrùn, Àjìǹdò-gúúsù, Ìwọ̀-oòrùn gúúsù, àti Ìlà-oòrùnun gúúsù.
Ọ̀rọ̀ọ Nwanze pé àwọn Onígbàgbọ́ ní gúúsù Nàìjíríà ló pọ̀ jù lọ nínú ìwádìí àyẹ̀wò Pew Research kò ṣe é má gbàgbọ́. Ìwádìí àyẹ̀wò náà tún fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọmọ lẹ́yìn Krístì ní Nàìjíríà “rí orílẹ̀-èdèe US bí ìlú tí ó dára (ìdá 69) ju bí àwọn Ìmàlé ṣe rí i lọ (ìdá 54).”
Lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdèe Amẹ́ríkà pa Ọ̀gágun ọmọ Iran Qasem Soleimani, ọ̀gá ọlọ́pàá tẹ ìkéde ìṣọ́ra ẹni jákèjádò orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà jáde kí ó ba ti ilẹ̀kùn “ogun.”
Ẹgbẹ́ Ẹ̀sìn Ìmàle ní Nàìjíríà ṣàpèjúwe ikú oró òjò ọta ìbọn láti òkè wá tí US fi pa Soleimani gẹ́gẹ́ bí “ìpè ogun sí Ìran.”
A ti ṣe àpèjúwe Trump gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kan lára àwọn olórí àgbáyé sáà tí a wà yìí tí ó ní ọkàn líle.”
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló fẹ́ràn-an Trump.