Ọ̀nà wo ni àrùn COVID-19 ń gbà ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣèlú àti ẹ̀yìn-ọ̀la Orílẹ̀-èdè China lágbàáyé?

Àwòrán tó ń fi ààlà-ilẹ̀ orílẹ̀-èdè China hàn lórí ọmọ ọ̀rọ̀ mẹ́rin tí kíkà rẹ̀ jẹ́ 武汉肺炎 tí ó túmọ̀ sí “àrùn ẹ̀dọ̀fóró Wuhan” (tí ó ṣì jẹ́ lílo ní èdè Chinese), gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ àjàkálẹ̀ náà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ó tó yí orúkọ padà sí COVID-19. A gba àṣẹ láti lo àwòrán.

Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ nínú ọjà oúnjẹ inú odò, gẹ́gẹ́ bí i ọ̀ràn àìlera ìbílẹ̀, ti wá di nǹkan tó rànká Orílẹ̀-èdè China. Lẹ́yìn ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìjẹyọ kòkòrò àìfojúrí kòrónà ní Wuhan nínú Oṣù Kejìlá Ọdún 2019, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ló ṣẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ló ṣú yọ tó sì fi àwùjọ ilẹ̀ Chinese làkàlàkà tí ó sì tún dojú ìpèníjà kọ ìdúróṣinṣin ètò ìṣèlú Beijing.

Kíkúndùn ìṣàkóso ìròyìn ti fún ìjọba lọ́rùn, àti ìjọba ìbílẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀ ní àárín gbùngbùn, ló máa ń fa ìdádúró fún àgbéjáde ìròyìn tí yóò ṣe ará ìlú láǹfààní fún ọ̀sẹ̀ pípẹ́. Nígbà tí wọ́n wá sọ jí láti ṣe ìkéde lórí àwọn ọ̀nà tí yóò dẹ́kun ìtànká àjàkálẹ̀ náà, ó ti bọ́ sórí, nítorí ayẹyẹ ọdún tuntun ìran Chinese ọlọ́dọọdún ti gbérasọ.

Àwọn Dókítà àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sì ń ṣe ìwádìí àti ìfọ̀rọ̀jomitoro-ọ̀rọ̀ lórí ohun tí ó lè jẹ́ orísun àrùn tí wọ́n mọ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún gẹ́gẹ́ bí kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan, tí ó padà wá ṣe okùnfà COVID-19, kòkòrò àìfojúrí tó ń mú kí ènìyàn má leè mí sókèsódò tí ó sì ń fa àrùn ẹ̀dọ̀fóró. Ìdámọ̀ràn ohun tí ó lè fa sábàbí àrùn náà kan fi yé wí pé kòkòrò àìfojúrí kòrónà jẹ yọ látàrí ẹran ejò tàbí ẹran àdán tí àwọn ará China máa ń jẹ l'óúnjẹ, tí wọ́n ń tà ní ọjà Huanan wet ní agbègbè Wuhan níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní èrò wí pé ibẹ̀ ni orísun kòkòrò àìfojúrí yìí.    

Ìbéèrè kan tí ó nílò ìdáhùn ni ti ọ̀nà ìtànkálẹ̀ àrùn yìí: bóyá ó leè rànká láti ara èèyàn kan sí ìkejì, àti ìyè èèyàn mélòó ló leè kó àìsàn yìí látara ẹni tí ó bá ti ní i. Ẹ̀rí láti ìmọ̀ ìlera tó fẹsẹ̀múlẹ̀ ṣe ìṣípayá àrànkán láti ara ènìyàn kan sí ìkejì, tí ó fi jẹ́ wí pé kòkòrò náà yóò ti wà lágọ̀ọ́ ara fún ìgbà díẹ̀ kí ẹni tí ó kó o ó tó máa rí àwọn ààmì rẹ̀ lára, tí èyí ò sì mú mímọ ẹni tí ó bá ti lu gúdẹ àrùn náà rọrùn.  

Ní ti bí àrùn náà ti ń ràn, èyí tí àwọn onímọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn ń pè ní “òǹkà ìpìlẹ̀ ìbísí“, gbà pé ó wà láàárín 2 sí 3 ní ìparí Oṣù Kìn-ín-ní, ẹni tí ó ní i yóò kó o ran ẹni méjì sí mẹ́ta, ṣùgbọ́n ìfikùnlukùn àti ìwádìí kò dúró, ìyẹn bí àwọn ìwífún-alálàyè tí ó wúlò bá wà ní àrọ́wọ́tó. 

Bí òǹkà àwọn tí wọ́n ti ní kòkòrò yìí ṣe ń lọ sókè sí i lójoojúmó, àáríngbùngbùn Orílẹ̀-èdè China tí i ṣe Hubei àti Olú-ìlú rẹ̀ tí í ṣe Wuhan ti ní ìdojúkọ tó gogò lórí ètò ìlera, tí àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ń gbé lágbègbè yìí sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ́rùn ní ìlọ́po 60. Bí iye àwọn tí ó ti kó àrùn yìí ṣe ń pọ̀ káàkiri Orílẹ̀-èdè China, àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ti wà digbí, tí wọ́n sì tún kóná mọ́ ètò ìlera tí kò sùwábọ̀ tó fún ìtọ́jú àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye arúgbó tó kún ìlú.  

Ṣùgbọ́n àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà Wuhan náà kì í ṣe ìkọlù ètò ìlera lásán, ó jẹ́ àkókò òtítọ́ ètò ìṣèlú tí ó lákaakì. Ìgbẹ́kẹ̀lé ìjọba tí ó sọ fún àwọn ará ìlú wí pé kò s'éwu l'óko àfi gìrì àparò ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, títí tí ẹ̀pa ò fi bóró mọ́, tí àwọn ará ìlú kò sì ní ìfọkàntán nínú àwọn ìjọba wọn mọ́, àti pé, kì í ṣe ní agbègbè Hubei nìkan ni èyí ti ṣẹlẹ̀. Àwọn ará ìlú bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba Beijing fún ọwọ́ yẹpẹrẹ tí wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn èémí SARS tó ṣú yọ ní ọdún 2002 sí 2003, bí ó ti ṣe fi ìròyìn tó péye lórí rẹ̀ pamọ́ fún Àjọ Elétò Ìlara Lágbàáyé (WHO). Olórí Orílẹ̀-èdè China àgbà Xi Jinping dákẹ́ rọrọ lórí àjàkálẹ̀ àrùn yìí àyàfi ìgbà tí ó di ọjọ́ 20, Oṣù Kìn-ín-ní Ọdún, tí ó kéde fún ará ìlú lẹ́yìn oṣù kan tí àrùn náà ti ń ṣọṣẹ́, pé ọ̀ràn náà ti kọjá àfẹnusọ. Agbára lórí ìṣàkóso àtẹ̀jáde ìròyìn fẹsẹ̀ múlẹ̀ rìnrìn ní orílẹ̀-èdè China, àti pé, ìwọ̀yáàjà ètò káràkátà pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àti bí ọrọ̀-ajé wọn ṣe ń dẹnukọlẹ̀, bí wọ́n bá ṣe yanjú ìṣòro kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan náà ni yóò forí lé ní ọdún 2020.

Bí a ṣe ń tẹ̀síwájú láti fi àwọn àkànṣe ìròyìn kún ojú ìwé yìí, kà síwájú sí i pẹ̀lú àwọn ìròyìn wọ̀nyí:

Ìpolongo tó ń rọ àwọn olùgbé Wuhan pé kí wọ́n ṣe ìmọrírì olórí Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Communist fún ìgbógunti COVID-19 tí ó lẹ́yìn

Ọ̀nà tí àwọn gbàgede ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé ti orílẹ̀-èdè Chinese ń gbà kó ara wọn níjàánu bí wọ́n bá ń gbé ìròyìn jáde lórí COVID-19.

Orílẹ̀ Èdè China ṣe ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ìròyìn tí ó jínyìn bí àwọn aláṣẹ ìjọba China ṣe fi ọ̀rọ̀ pamọ́ lórí àbájáde àyẹ̀wò ìtọ̀lẹ́yìn ẹ̀dá COVID-19 fún ọjọ́ Mẹ́rìnlá.

Ìbú-ẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣojú Àjọ Elétò Ìlara Lágbàáyé (WHO) látàrí ‘ìwà àìtètè bìkítà’ àti ‘ìwà ìkọ̀yìnsí ìtìlẹ́yìn China’ bí àrùn COVID-19 ṣe ń tàn ká gbogbo àgbáyé.

Ìkáni-lọ́wọ́-kò lórílẹ̀-èdè China fihàn wí pé òun leè f'ara gba ìparun tí yóò bá ilé iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde. 

Ìfòfinde ìwọléjáde ní Orílẹ̀-èdè China túbọ̀ ń dúkokò mọ́ ẹ̀ka ètò ìrìnàjò ìgbafẹ́, ẹ̀kọ́ àti ìṣòwò orílẹ̀-èdè Australia.

Agbára ọ̀tun gba orí ẹ̀rọ alátagbà Orílẹ̀-èdè China kan nígbà tí àwọn ènìyàn ó lé ní ẹgbẹ̀rún 60 kó àrùn COVID-19.

Ǹjẹ́ àjàkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí kòrónà ni ‘ìgbà Chernobyl’ ti orílẹ̀-èdè China?

Ìṣémọ́lé ìgbà péréte: Gbígbé pẹ̀lú àjàkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí ní Hong Kong

Kíké gbàjarè síta látàrí àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan ti dá aáwọ̀ ìdánilẹ́bi sílẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè China.

Ikú kòkòrò àìfojúrí kòrónà tí ó pa Li Wenliang tí ó jẹ́ ẹni tí ó tú àṣírí nípa àrùn náà ti fa ìkérora ẹ̀dùn ọkàn lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé. 

Ìlàkàkà lórí òǹkà ìtànkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí ti Wuhan.

Chen Qiushi: Oníròyìn Ọmọ-ìlú tó ń léwájú ní ti àgbéjáde ìròyìn lórí àjàkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan

Ìdí pàtàkì méje tí àwọn ará ìlú Hongkong se ń bínú sí àwọn ìjọba wọn látàrí àìbìkítà lórí ọ̀rọ̀ kòkòrò àìfojúrí kòrónà.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti Orílẹ̀ Èdè Pakistan tí wọ́n wà lábẹ́ òfin kó-nílé-gbélé pè fún ìrànwọ́.

Àwọn olólùfẹ́ ìlú China ní tòótọ́ gbẹ̀san lórí ayélujára lẹ́yìn ìgbà tí gbàgede Danish fi ‘àsíá oníkòkòrò àìfojúrí Chinese’ ṣe yẹ̀yẹ́.

Ní Taiwan, ìjà ọgbọ́n ìṣèlú ni àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan jẹ́.

Àwọn onímọ̀ ìlera ti Hong Kong banújẹ́ lórí ìṣiyèméjì ìjọba nípa ti àtìpa ojú ilẹ̀ ìlú fún àìfàyè gba àlejò. 

Ìpalára fún ọrọ̀-ajé ni àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan yìí tún jẹ́ fún Orílẹ̀-èdè China 

Àwọn Ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè China lábẹ́ òfin kó-nílé-gbélé kérora pé “Beijing ti pa Wuhan tì.”

Ní ìpalẹ̀mọ́ ìṣíláti-ibìkan-lọ-sí-ibòmìíràn fún ayẹyẹ Ọdún Tuntun Òṣùpá àpapọ̀, Orílẹ̀ China ti wá jáwé sóbì ìgbìyànjú wọn lórí kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.