Bí àpamọ́ àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe mú ọ̀rọ̀ àyíká di mímọ̀ ní Mekong

Adágún omi Mekong. Àwòrán tí a mú láti Ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé iṣẹ́ Ìtàn Àwọn Ènìyàn. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Ní ọdún 2014, ogunlọ́gọ̀ ìbílẹ̀ ní Mekong bẹ̀rẹ̀ sí ní í ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹgbẹ́ aṣèwádìí kan tí ó ń ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí bí ìtàn wọ̀nyí ṣe lè ṣe ìrànwọ́ tí yóò tú àṣìírí ìmúdìbàjẹ́ àyíká tí àwọn iṣẹ́ ńláǹlà ń fà ní agbègbè náà.

Mekong jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn odò ńlá Ásíà tí ó ṣàn gba orílẹ̀-èdè mẹ́fà: China, Myanmar, Thailand, Laos, Cambodia, àti Vietnam. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ìṣẹ̀dá abẹ̀mí àti ewéko tí ó jẹ́ ohun ìsayéró fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbẹ̀ àti apẹja.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ńláǹlà bíi kòtò ìdarí-omi ṣíṣàn fún Ìpèsè Iná Mànàmáná ti lé àwọn olùgbé jìnà ó sì ń ṣe àkóbá fún nnkan ìṣẹ̀dá odò náà. Ọ̀kanòjọ̀kan ìfẹ̀hànnúhàn kò ṣe nǹkan kan, àwọn iṣẹ́ ìdarí-omi ṣíṣàn ṣì ń lọ, pàápàá jù lọ ní Laos àti Thailand.

Pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Mekong Watch, ẹgbẹ́ kan ní Jápáànì ń jà fún ìdàgbàsókè ní agbègbè náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbà ní Mekong ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn tí ó ní íṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀dá. Mekong Watch gbàgbọ́ wípé  àwọn ìtàn wọ̀nyí “ti kó ipa ribiribi ní ti ìdáàbò ìṣẹ̀dá nípa dídẹ́kun ìwà àìbìkítà fún ọrọ̀ ìṣẹ̀dá.”

Mekong Watch sọ wípé ohun ìṣẹ̀dá nìkan kọ́ ni a ní láti dáàbò bò àmọ́ àti àwọn “nǹkan àjogúnbá tí-a-kò-le-è-rí-dìmú” tí a lè pín àti rí lò. Toshiyuki Doi, olùdámọ̀ràn àgbà fún Mekong Watch, ní èyí láti sọ:

Ó pọn dandan fún wa láti ka ìtàn àwọn ènìyàn Mekong kún, kí a dá wọn mọ̀, àti bọ̀wọ̀ fún wọn, papàá jù lọ ní òde òní tí wọ́n ti ń pàdánù àyè wọn ní ìrọ́pò ilé iṣẹ́ oníròyìn ìgbàlódé, tí wọn kò sì fi àjogúnbá lé ìran tí ó ń bọ̀ lọ́wọ́.

Àwọn agbègbè ní Mekong níbi tí àwọn oníṣẹ́-ìwádìí ti ṣe iṣẹ́. 1. Kmhmu’ ní àríwá àti àárín gbùngbùn Laos;; 2. Siphandon  ní gúúsù Laos; 3. Akha ní àríwá Thailand; 4. Thai So atí  Isan ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand; 5. Bunong ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Cambodia. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Ẹgbẹ́ náà ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà kí ó tó kó oríṣiríṣi ìtàn 102 jọ ní Cambodia, Laos, àti Thailand. A ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìtàn wọ̀nyí, dà á kọ sílẹ̀ sínú ìwé, àti ìtúmọ̀ ìtàn sí àwọn èdè orílẹ̀ Thailand, Laos, àti Cambodia kí ó tó kan ẹ̀da ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Mekong Watch tẹ àwọn ìtàn wọ̀nyí jáde sórí ìwé ìròyìn pélébé àti sórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá, wọ́n sì tún ó ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa àyíká ní àwọn ìlú náà.

Láti ìparí ọdún 2016, a ti fi ìtàn àwọn ènìyàn ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àyíká fún àwọn èwe ní ìgbèríko Laos àti Thailand. A ti ṣe àgbékalẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé àti ní ìlú ìbílẹ̀ láti tọ́ àwọn èwe sọ́nà, àti àwọn àgbà nígbà mìíràn, láti ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn ẹnu àwọn àgbàlagbà, fi ìtàn náà kọ́gbọ́n, àti láti sọ wọ́n di kíkà.

Àpẹẹrẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ni ìtúnsọ àlọ́ ‘Òwìwí àti Àgbọ̀nrín‘ àwọn aráa Kmhmu ní àárín gbùngbùn àti àríwá Laos. Àlọ́ náà dá lóríi òwìwí tí kò ríran ní ọ̀sán nítorí ó yan àgbọ̀nrín jẹ.

Níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan, a bi àwọn èwe tí ó kópa: “Irúfẹ́ ẹranko wo ni a bá nínú àlọ́ náà?”, “Ǹjẹ́ a lè rí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní abúlée yín bí?”, àti”bóyá àwọn ẹranko wọ̀nyí ti dínkù sí ti ìgbà kan, kí ni ìwọ rò wípé ó ti ṣẹlẹ̀?”

Lẹ́yìn èyí, a gba àwọn akópa ní ìyànjú láti so àlọ́ náà mọ́ ìdìbàjẹ́ àyíká ní ìlúu wọn.

Ní agbègbè Champasak, gúúsù Laos, ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ ẹranko omi tí ó ti ń dínkù Irrawaddy dolphin àti ẹyẹ Sida ni a ń lò fi ṣe àpèjúwe bí iṣẹ́ ìdarí-omi-ṣíṣàn ṣe ń ṣe àkóbá fún ẹja inú odò Mekong.

Àlọ́ mìíràn láti gúúsù Laos ní àwọn ìlànà tí ó kọ́ni nípa ìmọrírìi ìbójútó ọrọ̀ ìṣẹ̀dá:

A ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ Orí Erinmi ní ọjọ́ 16, oṣù Belu, ọdún 2014, ní etídò  Songkran ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand. Mun Kimprasert, ẹni ọdún  68. ni asọ̀tàn. Mekong Watch ló ni àwòrán, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Ní ìgbà kan, ológun kan wọ inú igbó iwin kan. Ó ṣe alábàápàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewé kátabá níbẹ̀ ó sì ṣẹ́ wọ́n. Àmọ́ ṣá, bí ó ti fẹ́ẹ́ jáde nínú igbó náà, ọ̀nà dí mọ́n ọn ní ojú, kò sì mọ ọ̀nà mọ́. Nítorí wípé ó ṣẹ́ ewé kátabá tí ó pọ̀ ju èyí tí ó lè lò lọ ni kò fi mọ ọ̀nà mọ́n. Ó wá ọ̀nà títí kò rí. Ẹ̀rí-ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ́ ẹ fún ohun tí ó ṣe, ó pinnu láti dá àwọn ewé kátabá náà padà sí ibi tí ó ti gbé ṣẹ́ ẹ. Wéré tí ó sọ ọ́ sílẹ̀, logan ni ó rí ọ̀nà ní iwájúu rẹ̀.

Ní àríwá Thailand, àlọ́ àwọn aráa Akha kan nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ swing tí ó sọ iṣẹ́ takuntakun ìfaraẹnisílẹ̀ t'ẹ̀gbọ́ntàbúrò tí ó mú ayé rọrùn.

Ní àríwá ìwọ-oòrùn Thailand, àlọ́ kan tí ó dá lórí Ta Sorn tí Tongsin Tanakanya sọ ṣe ìgbélárugẹ ìṣọ̀kan láàárín aládùúgbò ní ìlú iṣẹ́ àgbẹ̀. Ìtàn mìíràn ṣe ìrántí bí pípa àgbànrere kan ṣe fa iyọ̀ títà ní apá orílẹ̀-èdè yìí.

Ní Bunong, tí ó wà ní àríwá ìwọ-oòrùn Cambodia, àwọn àlọ́ tí ó sọ nípa ètùtù fún àtúnṣe sí ìgbéyàwó tí kò ní adùn àti ètùtù ìfọ́nrúgbìn àti ìkórè tí Khoeuk Keosineam jẹ́ asọ̀tàn. Bákan náà ni ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ erin tí Chhot Pich sọ ṣe àfihàn bí àwọn òrìṣà ṣe sọ àwọn ará abúlé tí ó fi májèlé sí inú odò di erin. Ó sọ ìdí tí ó fi rọrùn fún erin láti máa gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, wọ́n gbàgbé ìpìlẹ̀ wọn, wọ́n lọ ń gbé nínú igbó.

 

Hea Phoeun ti abúlé   Laoka, Senmonorom, agbègbè Mondulkiri ní Cambodia ń ṣàlàyé ètùtù ìgbéyàwó tí kò ládùn ní abúlé. Àwòrán láti ọwọ́ọ Mekong Watch, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Fún Mekong Watch àti àwọn agbègbè ní ìlú náà tí àkóbá ti bá, ìpamọ́ àwọn ìtàn wọ̀nyí ṣe kókó nínú ìpolongo ìkọjú-ìjà sí àwọn iṣẹ́ tí yóò lé ẹgbẹẹgbẹ̀rún  olùgbé Mekong kúrò ní ilée wọn:

Ìtàn wọ̀nyí lè di ìdánimọ̀ọ wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú àti ìbáṣepọ̀ t'ó dán mánrán pẹ̀lú àyíká. Nípasẹ̀ẹ ìtàn, ìlú yóò wá ọ̀nà ìgbàmọ́ra àti/tàbí ìkọjú-ìjà sí ìyípadà tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní odò Mekong.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.