Ìròyìn nípa Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn
Ní Burundi, àwọn akọ̀ròyìn mẹ́rin tí a fi sátìmọ́lé ń dúró de ìpinnu ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
A fi ẹ̀sùn ìlọ́wọ́sí ìdúkokò mọ́ ààbò ìlú ni a fi kan àwọn akọ̀ròyìn mẹ́rin náà látàrí iṣẹ́-ìjẹ́ ẹ̀fẹ̀ lásán tí wọ́n fi ṣọwọ́ nígbà tí wọ́n kó ròyìn ẹgbẹ́ ọlọ́tẹ̀ kan jọ.
COVID-19 ṣe àgbéǹde ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tó burú jáì nípa ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀
Ilẹ̀-Adúláwọ̀ 'kì í ṣe yàrá ìṣàyẹ̀wò' fún egbògi àjẹsára COVID-19. Àríyànjiyàn tí ó dá lóríi ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí ó burú jáì nípa fífi ọmọ ènìyàn ṣe ìdánwò àti fífọwọ́ọlá gbá ọmọ Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lójú.
Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ aṣẹ̀wùtà orílẹ̀-èdè Cambodia daṣẹ́sílẹ̀ látàrí àìsan owó ọ̀yà wọn lásìkò àjàkálẹ̀ COVID-19
"A kò leè jẹ́ k'áwọn agbanisíṣẹ́ ó wí àwáwí tí yóò f'àfàsẹ́yìn fówó ọ̀yà àwọn òṣìṣẹ́, nítorí àwọn òṣìṣẹ́ ti jẹ gbèsè, wọn kò sì gbọdọ̀ jáfara láti san owó wọn."
Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́-ẹ wọn láti sààmì ayẹyẹ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ọdún-un 2020
Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀-ọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lágbàáyé láti sààmì Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé lọ́jọ́ 13 oṣù Èrèlé ọdún-un 2020 àti láti fọn rere iṣẹ́ ìdàgbàsókè àgbà-ńlá ayé tí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ń ṣe.
Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà yóò pa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára ní Nàìjíríà
Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà yóò pa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára, sọ ìtakò ìjọba d'ẹ̀ṣẹ̀ àti sọ ìṣánpa ẹ̀rọ ayélujára ní Nàìjíríà dòfin.
Ilé ẹjọ́ gíga Tanzania pa á láṣẹ fún ìfòpinsí ìsoyìgì láàárín àgbàlagbà àti ọmọdé láì wo ti ìgbésẹ̀ ìmúpadàa rẹ̀
Nínú oṣù Ọ̀wàrà 2019, Ilé-ẹjọ́ Gíga Tanzania ṣe ìdímú ṣinṣin ìdájọ́ láti fòpin sí ìgbéyàwó ọmọdé. Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà jẹ́ atọ́ka sí ìfòpinsí àwọn àṣà tí ó ń mú ìpalára bá àwọn ọmọdébìnrin àti onírúurú ẹlẹ́yàmẹyà tòun ìfọwọ́rọ́sẹ́yìn àwọn ọmọdébìnrin.
Ìrọ́lù ọlọ́pàá tí í mú ikú bá ‘ni ní Guinea bí Ààrẹ Alpha Condé ṣe kọ̀ láì gbé’ jọba sílẹ̀
Ìwà ipá ọlọ́pàá tí ó ń ṣekú pani ní Guinea bí ààrẹ ṣe gbèrò láti yí ìwé-òfin padà kí ó bá wà lórí ipò. Àwọn afẹ̀hónúhàn pa ẹni mẹ́fà àti ọlọ́pàá kan, ọ̀pọ́ sì fara pa.
Ìṣọdẹ-àjẹ́ ṣì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ìgbèríko India
Ìṣọdẹ-àjẹ́ jẹ́ ìwà tí kò bójúmu tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn apá kan ní India níbi tí àwọn ènìyàn, tí a n pe ọ̀pọ̀ jẹ́ obìnrin, ni àjẹ́ tí a sábà máa ń fìyà jẹ láì dá wọn lẹ́jọ́
Àyájọ́ Ọjọ́ Òmìnira ní Trinidad àti Tobago — àmọ́ ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè náà ní òmìnira bí?
"Òmìnira yìí faramọ́ ẹni tí o jẹ́, ibi tí o ti ṣẹ̀ wá, ẹ̀jẹ̀ àti ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìwá tí ó wà nínú iṣan-ẹ̀jẹ̀ rẹ"
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀
Ìlépa alájọpín-ìdókòòwòo wọn kì í ṣe fún ti èrè ìdókòòwò, àmọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwòo iléeṣẹ́ náà.