Ìròyìn nípa Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn láti Èrèlé , 2019
Akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Tibet-Canada rí ìkọlu lórí ayélujára lẹ́yìn tí ó já ewé olú borí nínú ìdìbò àjọ-ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́. Ó rò pé, Beijing ló yẹ á bá wí.
Chemi Lhamo dojú kọ onírúurú èsì ìdáyàjáni ní orí ẹ̀rọ-alátagbà láti ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun tí ó ń gbé ní gbùngbùn orílẹ̀-èdè China.
Pẹ̀lú àìbalẹ̀-ọkàn tí ó ń pọ̀ sí i ní ìmúra ìbò ààrẹ ọdún-un 2019, Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń bẹ̀rùu pípa ẹ̀rọ-ayélujára
Lílo ẹ̀rọ-alátagbà fún pípe àkíyèsí sí ìrúfin ìjọba àti ìwà tí kò bá òfin mu ti fa ìbẹ̀rù wípé ìtẹríbọlẹ̀ ní orí ayélujára ní àsìkò ìbò tí ó ń bọ̀.
Ilé-iṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ìbílẹ̀ Fagilé Ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn ajìjàǹgbara LGBT lẹ́yìn ìhalẹ̀mọ́ sí olóòtú
Èébú ìkórìíra-ìbálòpọ̀-láàárín-akọ-àti-akọ ní orí ayélujára kò ṣí ọkàn-an olóòtú kúrò, àmọ́ ìpè ẹni àjèjì ń dá ẹ̀ru ìwà ìkà bá àwọn àlejòo rẹ̀.