Ìtọ́jú àwọn erin aláìlóbìíi Myanmar

Òṣìṣẹ́ àgọ̀ kan ń rọ Ayeyar Maung ní oúnjẹ. / Aung Kyaw Htet / The Irrawaddy

Àpilẹ̀kọ jẹ́ ti Aung Kyaw Htet tí ó kọ́ fún The Irrawaddy, iléeṣẹ́ oníròyìnin orí ayélujára ní Myanmar, tí Ohùn Àgbáyé ṣe àtúntẹ̀jádée rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàárín wọn. 

Nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ alábòójútó igbó rí i nínú ijù tí ó sún mọ́ Etí-omi Irrawaddy, oṣù mẹ́ta ni Ayeyar Sein nígbà náà. Ẹsẹ̀ẹ rẹ̀ kan ti lu páḿpẹ́ àwọn ajérangbépa. Àwọn onígẹdú ìjọba ló dóòlà ẹ̀míi rẹ̀, wọ́n sì gbé e lọ sí àgọ́ erin kan ní Agbègbèe Bago fún ìtọ́jú. Òhun ni ọ̀dọ̀ erin kẹjọ tí yóò rí ààbò ní Wingabaw, ibi ààbò fún àwọn erin Myanmar tí kò lóbìí.

Ọ̀dọ́ erin mìíràn, Ayeyar Maung náà rí nǹkan. Kí ó tó di èròo àgọ́ náà, erin oṣù mẹ́fà náà ti lu okùn. Ó sì há sí àárín àwọn òkúta nínú ijù kan náà tí a ti rí Ayeyar Sein, àwọn ọ̀wọ́ọ rẹ̀ tó kù fi í sílẹ̀ lọ. Síbẹ̀, àwọn alábòójútó ijù tú u sílẹ̀, ó sì di aráa àgọ́ náà ní ọdún tó kọjá.

Àwọn méjèèjì ni erin aláìlóbìíi tí ó kéré jù lọ nínú àgọ́ náà; ọdún mẹ́rin ni erin tí ó dàgbà jù gbà lọ́wọ́ọ wọn. Gbogbo wọn ni ó ní ìtàn kan tàbí òmíràn tí ó jẹ mọ́ ìjìyà láti ọwọ́ ẹ̀dá ọmọ ènìyàn adáríhununrun. Àwọn kan kò rí ọ̀wọ́ọ wọn tí wọ́n jọ ń jẹ̀ mọ́, àwọn mìíì di aláìlóbìíi lẹ́yìn tí àwọn tí ó ń pa ẹran nínú ìgbẹ́ nípakúpa pa òbíi wọn. Ní àgọ́ tí ó wà ní Wingabaw, àwọn ọ̀dọ́ erin tí kò ní òbí náà gbẹ́kẹ̀lé oúnjẹ ọmọ ìkókó tí àwọn alábòójútó ijù ń pèsè fún wọn lójoojúmọ́. Ààyé gbà wọ́n láti jẹ̀ nínú ijù ní òwúrò, wọn yóò sì wẹ̀ nínú odò kékeré kan nítòsí kí wọn ó tó padà sí àgọ́.

Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, Myanmar yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ ní tó erin ẹgàn 1,500. Àmọ́ ó jẹ́ ohun tí ó bani lọ́kàn jẹ́ nítorí pé àwọn tí ó ń dá ẹ̀míi wọn légbodò kò jẹ́ kí wọn ó gbé ayé, erin kan lọ́sẹ̀ kan ni wọ́n ń pa.

Àsìkò láti wẹ̀/ Aung Kyaw Htet / The Irrawaddy

Ọ̀dọ́ erin gun òkè etídò kékerée tí ó wà ní ìtòsíi àgọ́ọ Wingabaw lẹ́yìn ìwẹ̀. / Aung Kyaw Htet / The Irrawaddy

Òṣìṣẹ́ àgọ́ kan ń yẹ ìwọ̀n ìgbónára Ayeyar Sein’ wò pẹ̀lú ẹ̀rọ òṣùwọ̀n-ìgbóná. / Aung Kyaw Htet / The Irrawaddy

Òṣìṣẹ́ kan ní àgọ́ọ Wingabaw tí ó wà ní Agbègbèe Bago ń fún ọ̀dọ́ erin kan tí kò ní òbí, Ayeyar Sein, ní oúnjẹ. / Aung Kyaw Htet / The Irrawaddy

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.