Pẹ̀lú ìdásílẹ̀ àwọn akọ̀ròyìn-in Reuters, ẹ̀ṣẹ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ṣì jẹ́ ní Myanmar

Akọ̀ròyìn Reuters méjì Wa Lone àti Kyaw Soe Oo rìnrìn òmìnira lẹ́yìn tí a dá wọn sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n Insein ní  Yangon.  Àwòrán àti ọ̀rọ̀ abẹ́-àwòrán láti ọwọ́ọ Myo Min Soe / Irrawaddy náà ń bá Ohùn Àgbáyé ṣiṣẹ́ ìròyìn.

Àwọn ẹgbẹ́ iléeṣẹ́ oníròyìn àti ajà-fún-ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ń ṣe àjọyọ̀ọ ti ìdásílẹ̀ lẹ́wọ̀n-ọn akọ̀ròyìn Reuters Wa Lone àti Kyaw Soe Oo tí ó lò ju ọjọ́ 500 ní àtìmọ́lé fún ipa tí wọ́n kó nínú ìwádìí òfíntótó ìṣẹ̀lẹ̀ ìpanípakúpa àwọn olùgbée Rohingya kan ní gúúsù Myanmar. Àmọ́ pẹ̀lú ìdásílẹ̀ tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, ipò yẹpẹrẹ ni òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ìlú náà nítorí wípé ìtìmọ́lé àti ìfìyàjẹ àwọn akọrin, akọ̀ròyìn, àti ajìjàǹgbara ṣì wà síbẹ̀ sẹpẹ́. Ka àwọn ọ̀ràn ìsàlẹ̀ yìí síwájú:

Ìfẹ̀sùn Ìbanilórúkọjẹ́ kan Irrawaddy Náà 

Ẹ̀ka ológun Agbègbè Yangon kọ ìwé ẹ̀sùn-un ìbanilórúkọjẹ́ sí olóòtú èdèe-Burmese U Ye Ni wípé ibùdó-ìtakùn-àgbáyé akọ̀ròyìn náà gbè lẹ́yìn ẹnìkan nínú ìròyìn ìkọlù láàárín-in ọmọ-ogun ìjọba àti àwọn adárúgúdù sílẹ̀ Ọmọ ogun  Arakan ní Ìpínlẹ̀ Rakhine tí ó tẹ̀ jáde. Irrawaddy Náà sọ wípé òun kò ṣe àṣemáṣe ju jíjábọ̀ọ ìwọ̀yáàjà tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní sàkání náà láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún-un 2019. Èsì tí U Ye Ni fún àwọn ọmọ ajagun rè é  :

Ó ká mi lára nípé iṣẹ́ẹ wa kò yé ikọ̀ ajagun yékéyéké. Nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn ni  ó ti fi lélẹ̀ wípé a gbọdọ̀ tànmọ́lẹ̀ sí ìjìyà àwọn ènìyàn ní ibi tí rògbòdìyàn bá wà. Èròńgbà wa tí a fi tẹ̀lé ìròyìn náà ó ju láti fa àkíyèsí àwọn tí yóò tán ìṣòro sí ìjìyà àwọn ènìyàn.

Àjọṣepọ̀ tí ó dán mọ́nrán ń bẹ ní àárín-in Ohùn Àgbáyé àti Irrawaddy.

Àjùsẹ́wọ̀n fún yẹ̀yẹ́

Ìyẹn bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ẹ ajótà Ìran Ọ̀kín Thangya márùn-ún di èrò ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní Insein títí di ìgbà tí wọn yóò lọ sí ilé ẹjọ́ fún ẹ̀fẹ̀ tí wọ́n fi ológun ṣe. Eré ìtàgé tí ó ní àkójọpọ̀ orin abínibí, ijó àti ewì ni a mọ Thangyat mọ́. Ẹ̀gbẹ́ alájòótà yìí ti tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin abala 505(a) tí ó ní wípé ọ̀daràn ni ẹni tí ó bá polongo ọ̀rọ̀, àyesọ, tàbí jábọ̀ irúu rẹ̀ pẹ̀lú èrò láti mú kí ikọ̀ ajagun ó máà ka ojúṣe rẹ̀ kún tàbí kùnà láti ṣe ojúṣee rẹ̀.

Ọ̀kan lára ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn, Zeyar Lwin, sọ pé:

 Gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá jẹ́ ti òṣèlú torí ìdí èyí ó yẹ kí wọ́n ṣe àtúnṣe gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ òṣèlú.  Bákan náà, mo máa sọ wípé gbogbo wa ní láti darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ àtúnṣe sí ìwé òfin ọdún-un 2008 tí ó ń lọ lọ́wọ́ nínú ìgbìmọ̀ ìjọba. Ní tèmi, gbogbo ọ̀ràn yìí pátá yóò jẹ́ yíyẹ̀ lulẹ̀ bí a bá le è ṣe iṣẹ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ ti àtúnṣe sí ìwé òfin.

Zeyar Lwin ń tọ́ka sí ìwé òfin ọdún-un 2008 tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn atúnǹkanká gbàgbọ́ wípé a ṣe é to láti fi agbára fún ìṣèjọba ikọ̀ ajagun pàápàá lẹ́yìn tí alágbáda gba ìjọba.

Aya-eré-ìtàgé aláàárẹ̀ nínú àtìmọ́lé 

Ọ̀ràn aya-eré-ìtàgé Min Htin Ko Ko Gyi tún fi ìrísí ìhámọ́ tí a há àwọn akọrin pàtàkì mọ́. Ìwé ẹ̀sùn tí ọ̀físà jagunjagun kọ nípa àwọn àtẹ̀jáde ‘ìbanilórúkọjẹ́’ tí aya-eré-ìtàgé gbé sí orí Facebook tí ó fà á tí a fi fi òfin mú un. Min Htin Ko Ko Gyi ni olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Àjọ̀dún Eré Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Iyì Ọmọnìyàn àti ìlúmọ̀nánká alátakò ìlọ́wọ́sí ikọ̀ ajagun nínú òṣèlú. Àwọn alátìlẹ́yìn-in rẹ̀ ń pè fún ìtúsílẹ̀ẹ rẹ̀ lóríi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, látàrí wípé a ti yọ àbọ̀ ẹ̀dọ rẹ̀ nítorí àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn àti ìṣòro kíndìnrín. Àjọṣe Eré Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, tí ó jẹ́ àjọṣepọ̀ àjọ̀dún eré ajàfẹ́tọ̀ọ́  ọmọnìyàn 40 kárí ayé, fi lẹ́tà ṣọwọ́ sí ìjọba:

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ajìjàǹgbara àgbáyé tí ọ̀rán kàn, a tọrọ ìdánilójú ìjọba Myanmar láti ríi dájú wípé Abala 66 (d), tí ó yẹ kí ó sún ìtẹ̀síwájú ẹ̀rọ ayárabíàṣá síwájú, tí kò ní jẹ́ lílò fún ìpalẹ̀mọ́ ọmọ ìlúu Myanmar tí ó fẹ́ sọ èròo ọkàn-an wọn àti lọ́wọ́ sí ètò ìṣèlú ìjọba àwa-arawa ní Myanmar.

Lẹ́tà náà tọ́ka sí ti àríyànjiyàn Abala 66(d) tí ó sọ nípa òfin ìbánilórúkọjẹ́ tí àwọn aláṣẹ ń lò láti to fi ẹ̀sùn ìtakò, ìjìjàgbara, àti akọ̀ròyìn.

Ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ kọ ìwé ẹ̀dùn tí Min Htin Ko Ko Gyi kọ fún béèlì. Ìgbẹ́jọ́ọ rẹ̀ tún di ọjọ́ 9, oṣù Èbìbì ọdún-un 2019.

“Kò yẹ kí wọ́n di èrò ẹ̀wọ̀n ní ìbẹ̀rẹ̀.” 

A rán Wa Lone àti Kyaw Soe Oo sí ẹ̀wọ̀n ọdún  méje fún rírú òfin Ìkọ̀kọ̀ sáà-akónilẹ́rú. Ilé Ẹjọ́ Àgbà di ìdálẹ́jọ́ tí wọ́n ṣe ní oṣù Igbe tí ó kọjá àmọ́ a dá wọn sílẹ̀ lẹ́yìn ìdáríjì ààrẹ ní àsìkò Ọdún Tuntun ìbílẹ̀ orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn ẹgbẹ́ bíi Southeast Asian Press Alliance kí Wa Lone àti Kyaw Soe Oo káàbọ̀ lẹ́yìn-in tí a dá wọn sílẹ̀ àmọ́ wọ́n sọ ìyànjẹ tí ó kojú àwọn akọ̀ròyìn méjèèjì:

Kò yẹ kí wọ́n di èrò ẹ̀wọ̀n ní ìbẹ̀rẹ̀, nítorí wọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Nígbàtí a gba ìdàgbàsókè yìí wọlé, ẹjọ́ọ Wa Lone àti Kyaw Soe Oo jẹ́ ẹ̀rí wípé ẹ̀mí àwọn akọ̀ròyìn tí ó ń ṣe àyẹ̀wò sí ìṣèlú wà nínú ewu ìgbẹ̀san òṣèlú.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.