China fi ọwọ́ọ ṣìnkún òfin mú ayàwòrán eré orí ìtàgé nítorí pé ó tún àwòrán ìgò ọtí-líle kan tí ó ń tọ́ka sí Ìpanìyànnípakúpa Tiananmen pín

Àwọn ìgòo Baijiu ń ṣe ìrántí ìpànìyànnípakúpa Tiananmen náà.

Jennifer Creery ni ẹni tí ó kọ ìròyìn yìí, tí Ilé Iṣẹ́ Atẹ̀wé Olómìnira Hong Kong sì tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọjọ́ 24 oṣù Èbìbí ọdún-un 2019. Ohùn Àgbáyé ṣe ẹ̀dàa ìròyìn náà ní abẹ́ ìtọwọ́bọ̀wé àjọṣe pọ̀ ìkóròyìnjọ. 

Àwọn aláṣẹ ìjọba China ti fi ayàwòrán eré aṣakọ̀sílẹ̀-ìṣẹ̀lẹ̀ Deng Chuanbin sí àtìmọ́lé lẹ́yìn tí ó ṣe túwíìtì àwòrán ìgò ọtí-líle kan tí a sààmìi “64” sí lára – tí ó ń tọ́ka sí ọjọ́ burúkú Èṣù gbomi mu Ìpaninípakúpa tí ó wáyé ní Tiananmen Square ní ọjọ́ 4, oṣù Òkúdù ọdún-un 1989.

Ìgò ọtí-líle 64 

Ọdún-un 2016 ni a ṣe ìgòo ọtí-líle náà, ìyẹn ní ìrántí ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù wáyé. Orúkọ tí a pe ọtí-líle náà ni “8 wine 64″. Bí a ti ṣe ń pe “wine” ní èdèe Putonghua náà ni à ń pe “9”. Ààmì ara ìgò náà ní àwòrán “Ọkùnrin ọkọ̀-ogun” tí a kọ “Máà ṣe gbàgbé, máà ṣe sọ̀rètí nù”. Ó sì tún fi han gbangbagbàngbà pé Beijing ni a ti ṣe ọtíi wáìnì náà tí ó ní ìdá 64 iye ọtí-líle nínú tí ó sì ti wà nílé ìtajà fún ọdún mẹ́tadínlọ́gbọ̀n.

A fi ọwọ́ọ ṣìnkún òfin mú àwọn ọmọkùnrin orílẹ̀ èdèe China mẹ́rin, Fu Hailu, Zhang Jinyong, Luo Fuyu àti Chen Bing, ní ọdún-un 2016 fún ìṣẹ̀lẹ̀ ìgò ọtí-líle tí a sì fi ẹ̀sùn-un “rírú ìṣẹ́po agbáraiìlú sókè”.

Ìgbẹ́jọ́ Fu, Zhang àti Luo's wáyé ní ibìkan ní Ilé-ẹjọ́ Àwọn Ènìyàn Agbedeméjì Chengdu nínú oṣù Igbe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gba ìdájọ́ ìgbà ọdún mẹ́ta ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìdádúró ọdún mẹ́rin sí márùn-ún. Nítorí pé Chen kò gbà wípé òun dá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì wà lábẹ́ẹ ṣìgún òfin.

Pẹ̀lú ìdádúró ìrànlẹ́wọ̀n, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣì wà lábẹ́ ìṣọ́:

Ìfọwọ́ọ ṣìnkún òfin múni nítorí àtúnpín túwíìtì 

Ní ìpalẹ̀mọ́ ìsààmì ọgbọ̀n ọdún tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ 4, ayàwòrán eré orí ìtàgé Deng Chuabin ti di ẹni tí ọ̀rọ̀ ìgò ọtí-líle 64 ń dá sẹ̀ríà fún lọ́wọ́lọ́wọ́. Ọlọ́pàáa Sichuan fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú Deng ní ilée rẹ̀ ní Yibin ní ọjọ́ Ẹtì tí ó kọjá, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ó ṣe àtúnpín àwòrán-an Twitter kan tí ó jẹ́ ti ìgò ọtí-líle 64, gẹ́gẹ́ bí Iléeṣẹ́-tí-kìí-ṣe-tìjọba, Adáààbòbo Ẹ̀tọ́ Ọmọ ènìyàn ti China (CHRD).

Ayàwòrán náà gba ìpè àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn-in ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí ó túwíìtì àwòrán náà pẹ̀lú wípé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó mú un wálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni CHRD ṣe ti sọ. Àwọn ọlọ́pàá fi agbára gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká mẹ́ta, ẹ̀rọ ayárabíàṣá kọ̀mpútà kan, ẹ̀rọ ayárabíàṣá àgbélétan kan, iPad, ike pélébé ìrántí àti ẹ̀rọ ayàwòrán kékeré kan nígbà tí wọ́n wá sí ilée rẹ̀. Deng ti wà ní Àtìmọ́lé Agbègbè Nanxi nítorí wípé “ó ń bá ìjà bọ̀” – ẹ̀sùn tí wọ́n sábà máa ń kà mọ́ àwọn ènìyàn tí ó ń takò ìjọba lẹ́sẹ̀.

CHRD sọ wípé fún wákàtí kan gbáko, àwọn ọlọ́pàá padà láti yẹ ilée Deng wò, wọ́n sì kó àwọn ẹ̀rọ lóríṣiríṣi:

Ọ̀rọ̀ tí ó ń lọ nípa #Deng Chuabin: Ní ọjọ́ 20 oṣù Èbìbì ọdún-un 2019: Àwọn ọlọ́pàá àgọ́ọ Peizhi ránṣẹ́ sí bàbáa Deng. Àwọn kan tẹ̀lée padà sílé, wọ́n sì ya àwòrán nínú ilée wọn. Wọ́n tú yàráa Deng Chuabin wò fún bíi wákàtí kan, wọ́n sì gbé ẹ̀rọ 20 àti agbaná sí ara ẹ̀rọ. Wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n mú okùn ìkòkò ìse-ìrẹsì. Ní ọjọ́ 21, àwọn ọlọ́pàá sọ fún àwọn òbíi Deng láti máà gba agbẹjọ́rò fún un.

Deng, tí a tún mọ̀ sí Huang Huang, tí ó jẹ́ ayàwòrán aládàádúró tí ó ti bá òǹyàwòrán Beijing, Ai Weiwei ṣiṣẹ́ papọ̀. Ó sọ wípé òun ti ní ìdojúkọ ìjọba, pẹ̀lú àtìmọ́lé ní ọdún-un 2015 láti dénà dè é kí ó máà lọ sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní Geneva.

Oṣù tí ó ń bọ̀ ni ó sààmì ọgbọ̀n ọdún tí ìpaninípakúpa Tiananmen Square wáyé. Lọ́dọọdún, àwọn aláṣẹ China fi ọwọ́ agbára mú ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì fi àwọn agbọ̀rọ̀dùn sí àtìmọ́lé.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.