Ojúṣe láti ṣe ìrántí: ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn Tiananmen

Òǹyàwòrán ọmọ bíbí Taiwan Shake ni aṣàgbékalẹ̀, àwòrán Ọkùnrin Ọkọ̀ Ogun tí ó wà ní àárín gbùngùn-un Taipei ni ìmísí àgbékalẹ̀ náà. Filip Noubel ni ó ya àwòrán èyí, a fi àṣẹ lò ó.

Ó ti tó 30 ọdún sí ìgbà ìgbérí sókè àti ìṣubú Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Ìjọba Àwa-ara-wa 89 (八九民运) ní China tí ó kóra jọ di Ìpaninípakúpa Gbàgede àìlókìkí Tiananmen Square ní ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù, 1989.

Ní ọjọ́ yẹn, ikọ̀ ogun orílẹ̀-èdè China ṣíná bolẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn àtúnṣe ètò ìjọba àwaarawa. Àjọ Alágbèélébùú Pupa ní yóò tó ọmọ orílẹ̀ 2,700 tí wọ́n pa, àmọ́ àwọn mìíràn nípé ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àkọpamọ́ kan tí ó jẹ́ ti ìjọba US jábọ̀ ní ọdún-un 2014 wípé àyẹ̀wò tí ó wáyé nínú China sọ wípé yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ orílẹ̀ 10,454 tí wọ́n pa.

Ẹgbẹ́ Olóṣèlú The Communist Party ti China kò fi ìgbà kan sọ ọ́ ní gbangba rí wípé òún mọ̀ wípé ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣẹ̀ tàbí ṣe ìwádìí fínnífínní síwájú sí i. Kò sí ìtọ́ka kankan sí Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Ìjọba Àwa-ara-wa 89 nínú ìwé àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá kankan, àwọn ọmọ ilé ìwé tí ó ga jù lọ ní China kò gbọ́ nípa ìpaninípakúpa náà, kò ta sí wọn létí rí.

Ohùn Àgbáyé ti ń jábọ̀ ìròyìn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fún ọdún mẹ́wàá. Ní ọdún yìí ni a sààmì ọgbọ̀n ọdún ohun tí ó fa sábàbí ìpaninípakúpa ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù àti láti ṣe ojúṣe wa láti rán àwọn ènìyàn létí, pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà àgàbàgebè tí Beijing ń gbà láti fi eérú bo òtítọ́ mọ́lẹ̀.

Ìpinnu Beijing kò ju láti pa ohun gbogbo tí ó bá tan mọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù rẹ̀ lórí ayélujára. Ní oṣù Igbe, ìpolówó òkè òkun kan tí ó ní àwòrán Ọkùnrin Ọkọ̀ Ogun fọ́nká sí orí ẹ̀rọ alátagbà orílẹ̀ èdèe China kí a tó mú un wálẹ̀. Òmíràn nínú àwọn ìròyìn-in wa ṣàlàyé bí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdèe China tí ó wà lórí ayélujára ṣe máa ń fi ìpalẹ́numọ́ ṣeré àti wá ọ̀nà àrà tí wọ́n máa ń gbà sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà láì dárúkọ rẹ̀, bí wọ́n bá sì fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú wọn, ìjìyà ojú ẹsẹ̀ tí ó kọjáa kékeré ni onítọ̀hún yóò jẹ ní agodo ọba. Èyí ni àyíká tí ó mú ìkóròyìnjọ nira àti di ohun tí kò ṣe é ṣe nítorí gbogbo ìròyìn ní láti gba Asẹ́ Ńlá ìpalẹ́numọ́ orílẹ̀ èdèe China kọjá.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ìfojúṣùnnùnkùn wo ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ alátagbà ní ẹ̀yin odi orílẹ̀ èdèe China náà mú ewu tirẹ̀ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe kà nínú ìròyìn yìí.  Àtìmọ́lé àti ifipámúni ni èrè ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tí ó bá sọ èròńgbà tirẹ̀ tí ó yàtọ̀ sí ti Ẹgbẹ́ olóṣèlú ìjọba, bí a ṣe ṣàpèjúwe níbí.  Irú ìpalẹ́numọ́ onísànánjúpa Beijing báwọ̀nyí ti ń kárí ayé, títí kan Hong Kong.

Síbẹ̀ ojúṣe láti rántí kò dẹ́kun fífi ìmísí sí ọkàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé. Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojúu wọn fọ ohun tí ó ń gbé wọn lọ́kàn síta nínú ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀, bí àwọn akọni òǹkọ̀ròyìn ní Hong Kong ṣe ń kọ ìròyìn nípa ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù. Níṣe ni Hong Kong kún fún àwòrán ìdánimọ̀ ẹgbẹ́ náà, òrìṣà abo ti Àwaarawa ní ìta gbangba. Ní Taiwan, àgbékalẹ̀ẹ ọnà alágbára kan tí a gbé sí àárín gbùngbùn Taipei ń ṣe ìrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún-un 1989. Àwọn ọmọ orí ayélujára Àgbáyé, títí kan àwọn tí ó ń lo Reddit, náà ń lo ẹ̀fẹ̀, ọnà àti àwòrán orí ayélujára tí a fi àyọkà sínúu rẹ̀ rán ni létí nípa ìjàgbara ọ̀rọ̀ ìjọba àwaarawa.

A óò máa fi ọ̀rọ̀ tí ó ń lọ kún ojúewé yìí, o lè kà síwájú sí i:

China fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú ayàwòrán eré orí ìtàgé nítorí pé ó tún túwíìtì àwòrán ìgò ọtí kan tí ó ń ṣe ìtọ́ka sí Ìpànìyàn nípakúpa Tiananmen pín

Ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn-in Ìpaninípakúpa Tiananmen: ìyọnu ìtàn àná ti Òrìsà abo Àwaarawa 

Ère Ọkùnrin Ọkọ̀ Ogun onífèèrè jẹ́ rírí ní Taiwan ní ìpalẹmọ́ Àyájọ́ Ìpaninípakúpa Tiananmen

Iṣẹ́ àmúṣepọ̀ ohùn àti àwòrán ń sààmì ọgbọ̀n ọdún tí ìpaninípakúpa ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù tí ó ṣẹlẹ̀ ní Beijing wáyé.

30 ọdún lẹ́yìn tí Ìpaninípakúpa Tiananmen náà wáyé: Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ẹni orí kó yọ Zhou Fengsuo

Ìpolongo Leica tí ó ń tọ́ka sí Ìpànìyàn nípakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbàgede Tiananmen Square tí ó gba gbogbo ìgboro orí ẹ̀rọ alátagbà kan ní China. Kí ó tó pòórá. 

Ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ àná China nípa ìpanilẹ́nunọ́: ìrántí ọgbọ̀n ọdún tí ìpaninípakúpa ṣẹlẹ̀ ní Tiananmen Square 

Àwọn aláṣẹ China ń lépa ọmọ ìlú fún lílo VPN láti fi fo ìpalẹ́numọ́ orí ayélujára dá 

Ayàwòràn ọ̀ràn òṣèlú Badiucao ṣàì déédéé fagi lé àfihàn tí ó fẹ́ ṣe ní Hong Kong — ó sì lọ pa lọ́lọ́.

Àwọn aṣàmúlò Reddit ṣe àtẹ̀jáde àwọn àwòrán tí ó ní àyọkà nípa ìpanilẹ́numọ́, pẹ̀lú ìdókòòwò tí ó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún 150 owó dọ́là láti Tencent 

 

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.