Ìjọba Tanzania fi Ajìjàgbara Ọmọ Orílẹ̀-èdèe Uganda sí àtìmọ́lé, wọ́n sì lé e kúrò nílùú

Dókítà Wairagala Wakabi [Àwòrán láti CIPESA tí a fi àṣẹ lò]

Wairagala Wakabi, àgbà ọ̀jẹ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹ̀rọ ayárabíàṣá tí ó wá láti Uganda, di ẹni àtìmọ́lé ní Pápákọ̀ òfuurufú Julius Nyerere International Airport ní Dar es Salaam, Tanzania lọ́jọ́ 25 oṣù Igbe.

A fi ìwé pe Wakabi kí ó wá á sọ̀rọ̀ níbi ètò Àyájọ́ Àwọn Olùgbèjà Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Tanzania ọlọ́dọọdún tí Àgbáríjọ Olùgbèjà Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Tanzania (THRDC) jẹ́ olùgbàlejò. Wakabi ni Olùdarí Àgbà Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ètò-ìmúlò Ìmọ̀-ẹ̀rọ Gbogboògbò fún Ìlà-Oòrùn àti Gúúsù Ilẹ̀ Adúláwò (CIPESA), ọ̀kan gbòógì nínú ilé-iṣẹ́ tí ó ń ṣe ètò tí ó dá lórí ètò-ìmúlò ẹ̀rọ ayélujára àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní orí ayélujára ní ilẹ̀ Adúláwò.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tí a fi ọ̀rọ̀ wá Wakabi lẹ́nu wò, tí wọn kò sì jẹ́ kí ó rí agbẹjọ́rò, a dá a padà sí Uganda.

Àwọn aṣojú láti Àgbáríjọ Olùgbèjà Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn gbìyànjú láti jà fún un, àmọ́ a sọ fún wọn wípé fún “àǹfààní ìlú” ni a fi dá Wakabi padà sí ìlúu rẹ̀:

Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò ju wákàtí díẹ̀ lọ, ó mú ìjáyà ńlá bá àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ní agbègbè náà, tí ọ̀ràn ìwà àìtọ́ tí orílẹ̀-èdèe Tanzania ń wù sí àwọn ajìjàgbara àti oníṣẹ́-ìròyìn ń peléke sí i. Nínú oṣù Belu ọdún tí ó ré kọjá, àwọn òṣìṣẹ́ Ìgbìmọ̀ tí ó ń Dáàbò bo Oníṣẹ́-ìròyìn, Angela Quintal àti Muthoki Mumo di ẹni àtìmọ́lé fún ọ̀pọ̀ wákàtí ní Dar es Salaam, Tanzania, tí ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnàa wọ́n di gbígbà lọ́wọ́ọ wọn.

Human Rights Watch sọ wípé lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Ààrẹ John Magufuli Tanzania ti rí “ìrésílẹ̀ ìbọ̀wọ̀ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìkẹ́gbẹ́ àti àpéjọ dé ojú àmì”

Ní ọdún-un 2015, Orílẹ̀èdè Olómìnira Ìṣọ̀kan Tanzania kéde Ìgbésẹ̀ Ìrúfin Orí Ẹ̀rọ Ayélujára. Ní àárín ọdún kan tí a kéde òfin yẹn, ó ti tó bí ọmọ orílẹ̀ èdèe Tanzania 14 tí òfín ti mú tí a sì ti dálẹ́jọ́ lábẹ́ òfin fún pé wọ́n sọ̀rọ̀ mọ́ṣààsí sí ààrẹ lórí ẹ̀rọ alátagbà. Pẹ́pẹ́yẹ gbé ọmọ pọ̀n nínú oṣù Ẹrẹ́nà ọdún-un 2018 nígbàtí a gba Ìlànà Ẹ̀rọ Ayárabíàṣá (Ohun orí ayélujára) àti Ìtàkùrọ̀sọ Ìfìwéránṣẹ́ wọlé tí ó mú un ní túláàsì fún àwọn akọbúlọ́ọ̀gù láti fi orúkọ sílẹ̀ tí wọ́n á sì san owó orí tí ó tó bíi US $900 lọ́dún kí wọn ó tó lè gbé àtẹ̀jáde sí orí ayélujára. Èyí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ búlọ́ọ̀gù aládàádúró ó wọ òkùnkùn.

Ìpalẹ́numọ́ iléeṣẹ́ akọ̀ròyìn aládàádúró  nípasẹ̀ àwọn àdàlù ìṣíwèé fún ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn àti ìrókẹ́kẹ́ mọ́ oníṣẹ́-ìròyìn ti di ìdẹ́rùbà, ìkóra-ẹni-ní-ìjánu àti ìbẹ̀rù láti sọ èrò ọkàn ẹni nípa àwọn olórí orílẹ̀ èdè náà.

Àtìmọ́lé àti ìdápadà Wakabi sí Uganda jẹ́  ìtẹ̀síwájú ìdojú-ìjà-kọ òmìnira ọ̀rọ̀ tòun èrò ọkàn ẹni ní Tanzania.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.