
Gbàgede Nyerere Square ní Dodoma, olú-ìlú orílẹ̀-èdè Tanzania, àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ”Bunge.” Àwòrán láti ọwọ́ọ Pernille Bærendtsen, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.
Ní ọjọ́ 29 oṣù Ṣẹrẹ, nígbà tí àwọn àjọ ìjọba Tanzania (Bunge) péjọ ní Dodoma fún ìjókòó ìpàdé tí ó ṣáájú nínú ọdún-un 2019, ẹyẹ òwìwí kan fò wọ inú ilé ìpàdé, ó sì bà sí orí ajá, níbi tí ó ti ń wo ìpéjọ láti òkè téńté.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà di ìròyìn tí ó sì tàn kálékáko, tí ó sì ń mú àwọn ènìyàn ṣe onírúurú ìbéèrè láti orí ẹ̀rọ-alátagbà àti ìwé ìròyìn. Àpẹẹrẹ wo ni ti òwìwí nínú ilé ìgbìmọ̀?
https://twitter.com/MwananchiNews/status/1090514205105680384
Ẹyẹ òwìwí náà ti jẹ́ rírí nínúu gbọ̀ngan ilé ìgbìmọ̀ ìlú Dodoma ní ẹ̀rìnmejì. Àpẹẹrẹ wo ni èyí túmọ̀ sí?
‘’Àmì burúkú?’’ ìwé ìròyìn ẹkùn-ìlú ọlọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀, Ìlà-oòrùn Afrika, dá ìmọ̀ràn.
Akọbúlọ́ọ̀gù ọmọ Gẹ̀ẹ́sì àti onímọ̀ kíkún nípa iṣẹ́ ìròyìn, Ben Taylor, sọ síwájú sí i:
https://twitter.com/mtega/status/1090568305776250881

Àwòrán-ẹ̀fẹ̀ láti ọwọ́ọ Samuel Mwamkinga (Joune), a lòó pẹ̀lú àṣẹ.
Ayàwòrán-ẹ̀fẹ̀ ọmọ bíbíi Tanzania, Samuel Mwamkinga (Joune), lẹ́yìn wá, ya àpẹẹrẹ àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà pẹ̀lú ìtọ́ka sí ìsọlọ́rúkọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ‘’àkójọpọ̀ àwọn òwìwí’’ látàrí ìmọ̀ àwọn Gíríìkì tí ó ní wípé ọlọ́gbọ́n ni ẹyẹ òwìwí (pẹ̀lú àṣẹ ni a fi lo àwòrán àpẹẹrẹ).
Síbẹ̀, ojú nǹkan búburú, àmì ikú àti òfo ní Tanzania ni àwọn ènìyàn fi wò ó.
Àti pé — òwìwí náà ti pinnu láti dúró sí Bunge, gẹ́gẹ́ bí Ọmọọ̀lú Náà ti wí:
Òwìwí, ẹyẹ òru, kò le è kúrò … pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà tí àwọn àjọ ọba gbà láti lé e jáde.
Ẹyẹ òwìwí kì í ṣe ẹyẹ rere ní Tanzania, àti pé, bẹ́ẹ̀ ni Tanzania kì í ní ìgbàgbọ́-asán. Ìwò káàkiri ọdún-un 2010 kan fi hàn wípé ìdá 94 ọmọ bíbí Tanzania ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Àjẹ́.
Ìpàdé ìgbìmọ̀ lásán kọ́
Fún ti ìpàdé yìí, ẹyẹ òwìwí nínúu ìpàdé ní ìtúmọ̀ tí ó ní àpẹẹrẹ, pàápàá fún àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́-asán, tí ó le pátápátá láti mú ojú kúrò.
Ní orí ìlànà ètò ìpàdé àkọ́kọ́ ìgbìmọ̀ọ Tanzania ọdún-un 2019 ni ìdámọ̀ràn àtúnṣe sí Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú, tí ó ti ní àríyànjiyàn lemọ́lemọ́ nínúu ìṣèlú tí nǹkan kò ṣe ẹnu re.
Tanzania wọ ìwé ìtàn ní ọdún-un 1992 gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ní Ilẹ̀-adúláwò tí yóò dá ètò ẹgbẹ́ òṣèlú púpọ̀ sílẹ̀, èyí tí ó fi àyè gba ẹgbẹ́ ìkọjúsí. Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú náà (rè é níbi pẹ̀lú àtúnṣe tí a gbà ní ìmọ̀ràn) bákan náà di lílò ní ọdún-un 1992, ó sì ti rí àtúnṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà bíi àtúnṣe ti ọdún-un 2009.
Pẹ̀lú wípé òwìwí wọ̀ sí òkè téńté nínúu ìpàdé, kò dí ìpinnu àwọn ìgbìmọ̀ lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe sí òfin — ìgbésẹ̀ tí àwọn atàbùkù ní wípé ó sọ ètò ẹgbẹ́ òṣèlú púpọ̀ Tanzania, àti ìjọba tiwantiwa bákan náà di yẹpẹrẹa step that critics regard as a serious weakening of the multiparty system in Tanzania, and thus also democracy.
Gẹ́gẹ́ bí Reuters ti ṣe wí, ìsọdituntun òfin náà ti fi agbára tí ó pọ̀ sí ọwọ́ àwọn akọ̀wé ìrántí tí ìjọba-yàn láti da ìwé àṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú nù àti láti fi ìyà ìfisẹ́wọ̀n jẹ ẹgbẹ́ olóṣèlú tí ó bá ṣẹ̀ sí òfin, ní àpẹẹrẹ, bí ó bá ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìlú tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìforúkọsílẹ̀ òǹdìbò àti àgbékalẹ̀ ètò mìíràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣèlú.
Ọ̀pọ̀ ilé-ìròyìn ni ó ṣe àtúnwí ọ̀rọ̀ Zitto Kabwe, olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ACT-Wazalendo, ẹni tí ó jẹ́ wípé nínú oṣù Ògún ọdún-un 2017 bu ẹnu àtẹ́ lu ìdámọ̀ràn àtúnṣe òfin náà, wípé ó ṣe é ṣe kí ó rọ́ ẹ̀tọ́ òṣèlú sẹ́yìn. Kabwe wá fi wé Àbádòfin Iṣẹ́ Ìròyìn ọdún-un 2016, èyí tí ó fi òmìnira fún ilé iṣẹ́ ìròyìn tí ó sì dá ilé ìròyìn aládàánialáìgbáralé-ìjọba padà. Wàyí, Kabwe pe àkíyèsí sí ìjì lẹ́sẹ̀ tí àtúnṣe Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú dá sílẹ̀:
A kò le è ní ìwé-òfin tí ó fi ẹ̀tọ́ fún òmíràn ìkẹ́gbẹ́ kí ó tún wá fún ẹnìkan ní agbára láti mú ẹ̀tọ́ òmìnira ìkẹ́gbẹ́ kúrò.
Ìjọba àwa-arawa tí ó ń kú lọ?
Ìjọba tiwantiwa tí ó ń fi ìdí rẹmi ní abẹ́ ìṣàkóso Ààrẹ Magufuli ti di fòníkú-fiọ̀ladìde nínú ìròyìn, ó sì ti di ọ̀rọ̀ àwàdà.
Ní ọjọ́ 30 oṣù Ṣẹrẹ, Fatma Karume, Alága Ẹgbẹ́ Òfin Tanganyika, túwíìtì àwòrán-ẹ̀fẹ̀ kan láti ọwọ́ọ ayàwòrán-ẹ̀fẹ̀ ọmọ bíbíi Kenya, Gado (Ọjọ́ 22, oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún-un 2017) tí ó ń tọ́ka sí ọwọ́ Ààrẹ orílẹ̀-èdè Tanzania Magufuli nínú ikúu ìjọba àwa-arawa:
https://twitter.com/fatma_karume/status/1090469532655853568
Ní ẹnu ọdún mélòó kan sẹ́yìn, òfin orílẹ̀-èdè Tanzania ti ń yí padà di aláfagbára ṣe, arapa rẹ̀ sì ń fa àìrí àyè fún ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn àti ilé iṣẹ́ ìròyìn aláìgbáralé-ìjọba láti ṣe bí ó ṣe ní abẹ́ òfin. Ní báyìí, àwọn aṣàyẹ̀wò fínnífínní ti sọ wípé àtúnṣe Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú kò ní mú un rọrùn fún ètò ìṣèlú tí ó jẹ́ pàtàkì fún Ààrẹ àti Chama Cha Mapinduzi (Ẹgbẹ́ Àyípadà Náà), tí ó ti wà ní orí àlééfà láti ìgbà tí òmìnira dé ní ọdún-un 1961.
Ìtakò jẹ́ dandanàndan nínú ìjọba tiwantiwa tí ó yé kooro. Alátakò gidi yóò ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí ètò ìjọba, yóò sì pè é ní ìjà. Bí kò bá sí alátakò, ó ṣe é ṣe kí ojú àwọn onírúurú ìyàtọ̀ ohun tí ọmọ-ìlú nílò ó máa jẹ́ ṣíṣe bí ó ti ṣe tọ́.
Nínú túwíìtì 15, akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn Rachel McLellan la àwọn ènìyàn ní òye nípa èrèdíi òfin tuntun náà, àti irú ibi tí ìtako tí ó mú ọpọlọ dání yóò ti wúlò :walked readers through possible consequences of the new act, and characterizes a situation where a critical opposition will find itself cornered:
https://twitter.com/RachaelMcLellan/status/1090331155465949189
Ìgbàgbọ́-asán ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ – àwọn tí ó ń ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣèjọba àfagbáraṣe orílẹ̀-èdè Tanzania rí ìdánilójú awuyewuye wọn pẹ̀lú ti ẹyẹ òwìwí tí ó wọ inú ilé ìgbìmọ̀ àti ìgbésẹ̀ gbogbo láti lé e dánú àmọ́ tí kò bọ́ sí i.
Òwìwí náà ta kété. Agbẹnusọ Ìgbìmọ̀, Job Ndugai, gbìyànjú láti yí ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀ padà pẹ̀lú àlàyé tí ó ní iyè nínú:
Ẹ̀yin Ọmọ Ìgbìmọ̀ Ọlọ́lá, a ti ń rí ẹyẹ òwìwí kan nínú Ilé yìí láti òwúrọ̀ àmọ́ nínú ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀ Dodoma, òwìwí tí a bá rí ní ojú-ọjọ́ kò ní ohunkóhun ń ṣe fún ẹnikẹ́ni. Èyí jásí wípé kò sí ìbẹ̀rù.
Fún àwọn tí ó ń wá àṣìṣe, síbẹ̀, kò sí ohun tí ó ní iyè nínú nípa òfin tuntun náà.