Ọjọ́ ìtàn ni ọjọ́ yìí: ojú yìí ni ogunlọ́gọ̀ ọmọ-ìlú Mozambique fi wo ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ 14, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018 nígbà tí, fún ìgbà àkókọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé ètò ọkọ̀ òfuurufú ìlú náà, tí obìnrin jẹ́ atukọ̀.
Ikọ̀ bàlúù TM112/3, tí ó rin ìrìn àjò láti olú ìlú, Maputo, àti Manica — tí jíjìn sí ara wọn tó máìlì 442 — ni a tí rí atukọ̀ Admira António, atukọ̀ kejì Elsa Balate, olóyè ọkọ̀ Maria da Luz Aurélio, àti òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ Débora Madeleine.
Àwọn obìrin wọ̀nyí wà nínú ẹgbẹ́ MEX, ilé-iṣẹ́ tí a dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àkànṣe LAM — Linhas Aéreas de Moçambique. Ní 1995, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bíi ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú aládàáni , Mozambique Express.
Àtẹ̀jáde ìkíni orí Facebook láti ọwọ́ ajàfúnẹ̀tọ́ obìrin Eliana Nzualo, ti ní ìsọsí tí ó tó 450, tí a ti pín tó ìgbà 460, àti pé ọ̀pọ̀ èsì tí ó tó 2,000 ni ó gbà:
UM DIA NA HISTÓRIA – Vôo totalmente tripulado por mulheres
Vôo TM112/3 MPM- VPY- MPM (Maputo- Chimoio- Maputo)
Parabéns MEX!
Parabéns tripulação!
Parabéns Moçambique!Por mais mulheres em todos os sectores.
ỌJỌ́ ÌTÀN – Ikọ̀ ọkọ̀ òfuurufú TM112/3 MPM-VPY-MPM (Maputo-Chimoio-Maputo)
MEX kú oríire!
Ikọ̀ ẹ kú oríire!
Mozambique, kú oríire!Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìrin nínú iṣẹ́ gbogbo.
Àjàfúnẹ̀tọ́ ìkẹ́gbẹ́ Mauro Brito sọ ní tirẹ̀ wípé obìrin gbọ́dọ̀ ní ìgbéraga “nígbàtí [wọ́n] bá jẹ́ aṣojú nínú iṣẹ́ gbogbo”:
Na aviação há muito poucas mulheres, poucas mesmo, isto não é aqui apenas mas em todo mundo. Imagino as mulheres por aí a fora que julgavam ser esta profissão apenas para homens, devem sentir se orgulhosas.
Obìrin kò pọ̀ nínú iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe rí káríayé. Mo rò ó wípé àwọn obìrin tí ó ronú láti ṣe iṣẹ́ tí ọkùnrin máa ń ṣe, gbọdọ̀ gbéraga.
Mozambique nìkan kọ́. Ní oṣù Ògún ọdún 2018, nínú ọkọ̀ òfuurufú ìlú apá Gúúsù Ilẹ̀-Adúláwọ̀ SAA, ìrìnàjò ìlú dé ìlú pẹ̀lú ikọ̀ olóbìrin fò ní ojú sánmà wọ́n sì kó èrò láti Johannesburg sí Sao Paulo, Brazil.
Oṣù méjìlá sẹ́yìn, ní oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2017, Ilé-iṣẹ́ Ọkọ̀ òfuurufú Ethiopia fún ìgbà àkókọ́ gbé ikọ̀ òṣìṣẹ́bìrin fò. Awọn atukọ̀ títí kan òṣìṣẹ́ gbogbo, ọkọ̀ òfuurufú láti Addis Ababa ní Ethiopia sí Èkó ní Nàìjíríà — jẹ́ obìrin pátápátá porongodo.