#FreeAmade: Akọ̀ròyìn tí a mú tí a sì dá lóró lẹ́yìn tí ó kọ ìròyìn lórí ìwà jàgídí jàgan tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Àríwá Mozambique

Àwọn ẹni-orí-kó-yọ tí wọ́n pàdánù ẹbí àti ilé ń sinmi níta gbangba lẹ́yìn ìkọlù ọjọ́ 5 oṣù Òkúdù ní abúlé Naunde ní Cabo Delgado nílùú Mozambique. Àwòrán láti ọwọ́ Borges Nhamira pẹ̀lú àṣẹ ìlò.

Wọ́n mú akọ̀ròyìn Mozambique kan ní ọjọ́ 5 oṣù Ṣẹẹrẹ níbi tí ó ti ń jábọ̀ ìròyìn nípa ìkọlù tí ó ń dé bá àwọn abúlé kéréje ní ìgbèríko Cabo Delgado ní Mozambique.

Cabo Delgado wà ní àríwá orílè-èdè Mozambique, ó kún fún àwọn ohun àlùmọ́nì bí i òkúta iyebíye, èédú àti afẹ́fẹ́ gáàsì tí wọ́n rí ní Rovuma, ilẹ tí omí yí ká. Àwọn olùkíyèsí sọ pé ẹgbẹ́ tí ó ń darí ìkọlù yìí ní i lọ́kàn láti máa jí àwọn ohun àlùmọ́nì yìí kó.

Láti oṣù Ọ̀wàrà 2017, àìmọye ìkọlù ni ó ti wáyé ní oríṣiríṣìí ìgbèríko ní Cabo Delgado láti ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ jàndùkú kan náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ni wọ́n ti jábọ̀ lórí àwọn ìkọlù yìí ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ wu àwọn ìjọba láti sọ̀rọ̀ lé e tàbí kí wọ́n fi ìdí àrídájú ẹ̀rí múlẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí.

Ní 2018, èèyàn tó lé lọ́gọ́rùn-ún ni wọ́n bá ṣẹjọ́ lórí àwọn ọ̀ràn yìí. Ó yẹ kí ẹjọ́ọ wọn ó parí lọ́dún yìí.

#FreeAmade: Ìpolongo láti gba Akọ̀ròyìn Mozambique sílẹ̀

Amade Abubacar ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Mozambican Social Communication Institute, ó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn pẹ̀lú ibùdó ìròyìn orí ayélujára Zitamar àti iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìbílẹ̀ Nacedje.

Àwọn ọlọ́pàá ìjọba àpapọ̀ Mozambique mú akọ̀ròyìn náà ní ọjọ́ 5 níbi tí ó ti ń ya àwòrán àwọn ẹni-orí-kó-yọ nínú ìkọlù kan ní Cabo Delgado, wọ́n sì tì í mọ́lé.

Lẹ́yìn náà, wọ́n mú Amade lọ sí ibùdó àwọn ológun Mozambique ní ìgbèríko Mueda láìjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ológun. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, wọ́n gbé e lọ sí ẹ̀wọ̀n gbogboògbò láti mú kí àtìmọ́lé rẹ̀ bá òfin mu ní Pemba, olú ìlú Cabo Delgado.

Lẹ́yìn tí ó dé ẹ̀wọ̀n gbogboògbò, Amade pe ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò Mozambique tí ó sì sọ bí ó ṣe ti jìyà tó lọ́wọ́ àwọn ológun Mozambique tí ó ní wọ́n na òun tí wọ́n sì fi ebi pa òun.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn àti ẹgbẹ́ ajàfómìnira ti sọ̀rọ̀ síta láti gbèjà Abubacar tí wọ́n sọ pé mímú tí wọ́n mú un àti àtìmọ́lée rẹ̀ ti dẹ́rùba òmìnira ẹni láti sọ̀rọ̀.

Ìfilọ́lẹ̀ Agbéròyìn Sáfẹ́fẹ́ ti Gúúsù Ilẹ̀ Adúláwò, tí ó ń ṣe àbójútó ẹ̀tọ́ agbéròyìn sáfẹ́fẹ́ àti iṣẹ́ wọn ní agbègbè náà sọ̀rọ̀ tako àtìmọ́lé Amade:

Títì tí àwọn ológun ti Abubacar mọ́lé jẹ́ ìpalára fún ẹ̀tọ́ rẹ pẹ̀lú mímú tí wọ́n mú un láìsí ìdí tí wọ́n fi ìdí ẹ múlẹ̀. Ìjọba Mozambique ti ń ṣe àfihàn ìṣáájú burúkú nípa ṣíṣe ìdíwọ́ ẹ̀tọ́ ẹni láti sọ̀rọ̀ àti rírí ọ̀nà gbọ́ ìròyìn ní agbègbè náà.

Amnesty International náà sọ̀rọ̀:

Amade Abubacar é um respeitado jornalista que estava a gravar depoimentos de pessoas que fugiram de ataques mortais em Cabo Delgado quando foi preso pela polícia. Esta é a mais recente demonstração de desprezo pela liberdade de expressão e liberdade de imprensa por parte das autoridades moçambicanas, que veem os jornalistas como uma ameaça e os tratam como criminosos.

Amade Abubacar Amade Abubacar jẹ́ gbajúgbajà akọ̀ròyìn tí ó ń gba ẹ̀rí sílẹ̀ lẹ́nu àwọn ẹni tí wọ́n bọ́ nínú ìkọlù ní Cabo Delgado nígbà tí àwọn ọlọ́pàá mú un. Èyí jẹ́ àfihàn àìkàsí àwọn aláṣẹ Mozambique sí òmìnira láti sọ̀rọ̀ àti òmìnira àwọn oníròyìn… [àwọn aláṣẹ] rí akọ̀ròyìn gẹ́gẹ́ bí alátakò wọn [fún ìdí èyí] wọ́n ń ṣe wọ́n bí ọ̀daràn.

Ìpolongo náà ti tàn lórí Twitter, pẹ̀lú ìṣẹ̀dá àwọn àsopọ̀ ọ̀rọ̀ bí i #FreeAmade láti jà fún ìdásílẹ̀ Amade.

Angela Quintal, olùṣàkóso ètò àwọn adúláwò fún Ẹgbẹ́ Tí ó ń Dáàbò Bo Akọ̀ròyìn, dá ààrẹ orílẹ̀-èdè Mozambique lẹ́bi:

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.