Àwọn Ilé Iṣẹ́ ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ní Mozambique àti Cape Verde tẹ́ pẹpẹ ètò ẹ̀dínwó fún ayélujára lórí ẹ̀rọ alágbèéká láti mú kí àwọn ọmọ-ìlú ó dúró sílé

Ojú ọ̀nà Santa Maria, Cape Verde. Àwòrán láti ọwọ́ọ Miccaela, Wikimedia Commons. CC-BY 3.0

Yẹ àkànṣe iṣẹ́ tí Ohùn Àgbáyé’ ti ṣe lórí ipa tí kòkòrò àìfojúrí kòrónà COVID-19 ń kó lágbàáyé

Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ kónílégbélé ṣe ń múlẹ̀ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ látàrí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19, àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ti Ìpínlẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Mozambique àti Cape Verde ń fún àwọn ará ìlú ní ẹ̀dínwó lórí owó-ìlò-ayélujára ní orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká.

Di àsìkò yìí, Orílẹ̀-èdè Mozambique ti ní àkọsílẹ̀ ènìyàn 10 tí ó ti kó àrùn COVID-19, ṣùgbọ́n tí kò tí ì sí ẹni tí ó ti bá àìsàn náà lọ, àmọ́ ẹni 6 ló ti kó àrùn náà ní Cape Verde tí ẹnìkan sì ti di ẹni ẹbọra ń bá jẹun. Ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá, Orílẹ̀-èdè méjèèjì ti pàṣẹ òfin pàjáwìrì ìlú-ò-f'ara-rọ olóṣù kan látàrí àjàkálẹ̀ àìsàn tó gbayé kan, ó sì ṣe é ṣe kí wọ́n ṣe àfikún-un rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ oníròyìn kan ti Orílẹ̀-èdè Portugal Lusa ti ròyìn:

  As duas operadoras cabo-verdianas de telecomunicações móveis, CV Móvel e Unitel T+, anunciaram hoje uma campanha conjunta disponibilizando gratuitamente um pacote de 2.000 MB de Internet para apelar à permanência em casa, como prevenção da covid-19.

Denominada de pacote “Fica em Casa”, a campanha foi anunciada em conjunto pelas duas operadoras, numa mensagem divulgada nas redes sociais na qual assumem que “uniram forças” para que os cabo-verdianos fiquem “bem em casa”.

A campanha oferece aos clientes das duas operadoras, além de um pacote de 2.000 Mega Bytes (MB) de dados, 15 minutos de comunicações para todas as redes nacionais, para serem consumidos até o dia 30 de Abril.

Lónìí Ilé Iṣẹ́ ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ti Cape Verde méjèèjì, CV Móvel àti Unitel T+, ṣe ìfilọ̀ ìpolongo alájúmọ̀ṣe tí yóò mú kí MB ẹgbẹ̀rún 2 ó jẹ́ ti àwọn ará ìlú fún ìwúrí láti leè mú wọn dúró sílé lójúnà ìdíná ìtànká àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 láwùjọ.

Tí àkọ́lée rẹ̀ jẹ́ “Fica em Casa” (“ẹ̀bùn ìdúró sílé” ní èdè Yorùbá), ìpolongo náà ni àwọn ilé iṣẹ́ méjèèjì gbé jáde sórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé tí a kọ báyìí pé àwọ́n ti f'oríkorí láti “ṣiṣẹ́ àjàmọ̀ṣe” tí yóò mú kí àwọn ará orílẹ̀ Cape Verde “ó jókòó sílé”.

Ẹ̀bùn pàtàkì yìí wà fún oníbàárà ilé iṣẹ́ méjèèjì, àti pé ní àfikún sí MB ẹgbẹ̀rún 2 tí wọ́n yóò fún wọn, owó ìpè ọ̀fẹ́ fún ìsẹ́jú 15 yóò wà lófò fún pípe èyíkéyìí òpó ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè náà tí ó sì gbọdọ̀ jẹ́ lílò kí ó tó d'ọjọ́ 30, Oṣù Kẹrin.

COVID-19: Ìpolongo àǹfààní ìrànwọ́ MB ẹgbẹ̀rún 2 láti mú kí àwọn ará ìlú Cape Verde ó jókòó kalé kí òfin kónílégbélé ó bá f'ẹsẹ̀rinlẹ̀.

Ọ̀gọ̀rọ̀ ará ìlú Cape Verde ti yọ ṣùtì ẹnu sí ìpolongo yìí, nítorí ségesège ni afẹ́fẹ́ ẹ̀rọ ayélujára náà máa ń ṣe:

Àwàdà ńlá ni!!! Ẹni mélòó nínú ará ìlú Cape Verde l'ó ní afẹ́fẹ́ ẹ̀rọ ayélujára tó já geere? Rádaràda!!!

Ní Cape Verde, agbègbè erékùṣù tí ó ní èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún 560, tí idà 57 wọn ń lo ẹ̀rọ-ayélujára, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí Ilé Ìfowópamọ́ Àgbáyé ṣe ní ọdún 2017 ti ṣe fi hàn. Lọ́dún náà, ìdá 50 ni ìdá àwọn tó ń lo ayélujára tó pọ̀jù lágbàáyé.

Ní Mozambique, níbi tí àwọn ènìyàn tí ó ń lo ayélujára ò ti tó nǹkan – Ilé Ìfowópamọ́ Àgbáyé kan yìí náà fi hàn nínú ìwádìí pé ìdá 10 àwọn ará ìlú nínú èèyàn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ní ẹ̀rọ-ayélujára ní àrọ́wọ́tó – ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ TmCel tí ó jẹ́ ti ọmọ onílùú náà ti se ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo “kónílégbélé” yìí kan náà.

Ìpolongo náà kún fún àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan àǹfààní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ láti GB 1 sí GB 5, tí owóo rẹ̀ jẹ́ 25 sí 100 meticals (0.37 sí 1.50 owó US).

Mú àǹfààní ẹ̀bùn #StayAtHome yìí lò fún 25 meticals láàárín oṣù kan.

Tẹ *219# láti se àṣàyàn ẹ̀bùn tí ó fẹ́, kí o sì dúró sílé pẹ̀lú TmCel. Fún àlàyé lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́ kàn sí: :https://t.co/dKoUI0E0wT

Bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-pé àǹfààní ẹ̀bùn jẹ́ ohun àtẹ́wọ́ gbà láwùjọ, díẹ̀ lára àwọn òǹṣàmúlò gbàgede Twitter se àgbéjáde àwọn ìbéèrè kan:

Ìgbésẹ̀ tí ó dáa ni.

Sé ó jẹ́ ojúlówó bákan náà?

Dídúró sílé yìí kì í se ohun tó bá àwọn onísẹ́ ọwọ́ àti oníṣẹ́ ìgbẹ́mìíró tí ó ń gbé ní Mozambique àti Cape Verde lára mú rárá. Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ-ènìyàn Tomás Queface túwíìtì:

Àìsàn #coronavirus yìí ti ṣípayá ìwà àìdọ́gba tí ó wà láwùjọ wa. Bí òfin kónílé ó gbélé #StayAtHome ṣe jẹ́ oore ọ̀fẹ́ fún àwọn kan, níṣe l'ó ń mú àwọn tí ò rọ́wọ́họrí láwùjọ fajúro látàrí fi f'ọwọ́ múkan: nínúu dídúró sílé láì rí oúnjẹ jẹ, tàbí ṣíṣiṣẹ́ kí àlàáfíà ara ó di fíafìa tàbí fífi ìlera àwọn ará ìlú tó kù wéwu.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.