Spiny Babbler, ẹyẹ orílẹ̀-èdè Nepal, fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ mọ́ra

Spiny Babbler

Spiny Babbler, ẹyẹ tí a kò le è rí níbòmìrán àyàfi ní Nepal. Àwòrán láti ọwọ́ọ Sagar Giri. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Bí-ó-ti-lẹ-jẹ́-pé ẹ̀yà ẹyẹ orílẹ̀ èdè Nepal ju 800 lọ, ẹyẹ Spiny Babbler (Turdoides nipalensis) jẹ́ ẹ̀dá tí kò sí ní ibòmíràn àyàfi orílẹ̀ èdè náà. Ẹyẹ aláwọ̀ eérú-àti-pupa-rẹ́súrẹ́sú náà, tí à ń pè ní Kaande Bhyakur ní èdè ìbílẹ̀ Nepali, ń fi igbó ṣe ìtẹ́ a sì lè fi ojú bà á bí ó bá ń fò lókè lálá láti ìwọ̀n mítà 500 sí mítà 2135. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé Spiny Babbler náà ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àgbáyé mọ́ra fún ọdún pípẹ́, ìbàjẹ́ àyíká ti ń ṣe ìdẹ́rùbà àkàndá, ẹyẹ tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn yìí.

Nepal ní ọ̀wọ̀ ẹyẹ oríṣi 876, tí ọ̀kan ṣoṣo nínúu wọn sì jẹ́ irú èyí tí kò sí ní ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé (Spiny Babbler). #AsianBirdFair

Ẹyẹ náà tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi jẹ́ alárédè nínú ìṣẹ̀dáa rẹ̀ kò sì rọrùn láti rí, bíkòṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àkókò ìtọ́jú ọmọ bíbí tí àwọn akọ máa ń kọrin kiri agbègbè.

View this post on Instagram

Finally, a sight of the Spiny Babbler – a bird that occurs only in Nepal! Though they are Babblers, they sing a variety of rather loud & melodic songs from their hideouts amongst thick bushes, which resounds across the hills nearby – waking you up the possibility of seeing them. However, the amount of activity seems quite subdued in Winter. Spring & Summer season is probably the best time to catch a glimpse of this special bird which is recorded only in a few spots in Nepal. Makes one wonder what came to be that these birds have restricted themselves to only this geographical & political region. Thanks to @tharu_hunk & @nikitakhamparia for this. #spinybabbler #endemic #endemicbirds #nepal #chitwan #birdsofnepal #birdsoftheindiansubcontinent #birdsoftheworld #uperdangadi #nepaltourism #nuts_about_birds #birdingenthusiast #natureinfocus #nepalphotography #nepalphotoproject @insta.nepal #nepalnature

A post shared by Varun Mani (@bombaywhite) on

Ìwée nì The Status of Nepal’s Birds: The National Red List Series sọ wípé:

It seeks insects almost entirely on the ground among low bushes, appearing only occasionally. Spiny Babbler mounts branches of bushes or small trees to sing, bill pointed upward and tail down. It is a good mimic, with squeaks, chuckles and chirps. It is most easily located by its song and occasionally sings as late as September and October. The species is subject to seasonal altitudinal movements.

Ó máa ń wá kòkòrò nínú koríko ilẹ̀, ẹ̀kànànkan ni a sì máa ń rí i. Spiny Babbler máa ń bà lé ẹ̀ka koríko àti igi kéékèèké láti kọrin, àgógó ẹnu ẹyẹ yóò wà ní òkè irú ní ìsàlẹ̀. Ó dára ní wíwò, iké oríṣiríṣi. Orin rẹ̀ ni a fi ń mọ ibi tí ó wà, àárín oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ àti Ọ̀wàrà. Ẹ̀dá ẹyẹ yìí máa ń fò sókè lálá nínú àwọn àkókò kan nínú ọdún.

Ẹyẹ Spiny Babbler, tí a lè rí ní Nepal nìkan, ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ káríayé mọ́ra. Don Messerschmidt kọ nípa  àkọsílẹ̀ tí onímọ̀-nípa-ẹyẹ S. Dillon Ripley ṣe nípa ẹyẹ náà nínú ìwée rẹ̀ Ìṣàwárí ẹyẹ Spiny Babbler:

“It was a species that had defied scientists for years, since 1843 or 1844. At that time Brian Hodgson’s Nepali collectors working for him in the unknown vastnesses of Nepal had secured several specimens,” he writes. The Spiny Babbler “had remained a mystery ever since, one of the five species of Indian birds, which, along with the Mountain Quail, had apparently vanished from the face of the earth. But not quite, for if my guess was right, here it was hopping about large as life on the wooded slopes above Rekcha.”

“Ó jẹ́ ọ̀wọ̀ ẹyẹ tí kò ka àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì sí fún ọdún gbọgbọrọ, láti ọdún 1843 tàbí 1844. Ní ìgbà yẹn  àwọn aṣiṣẹ́ fún Brian Hodgson tí ó jẹ́ aṣèwádìí Nepali tí ṣe àkójọ onírúurú àpẹẹrẹ, ”ó kọ. Ẹyẹ Spiny Babbler “ti jẹ́ ẹranko tí ó ju ìmọ̀ ènìyàn lọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́, ọ̀kan nínú ọ̀wọ̀ ẹyẹ márùn-ún ní India, pẹ̀lú Àparò Òkè gíga, kò sí lórílẹ̀ ayé mọ́n. Ṣùgbọ́n bí èrò mi bá jẹ́ òtítọ́, ó ń fò kiri níbi ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Rekcha.”

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ikọ̀-ọba orílẹ̀-èdè America tẹ́lẹ̀ sí ìlú Nepal Scott DeLisi fi ọ̀pọ̀ ọdún wá ẹyẹ yìí  àti láti ya àwòrán-an rẹ̀.

Birder David Walsh túwíìtì:

Ẹyẹ náà ti ń dínkù látàrí ìgbẹ́ pípa fún iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìtẹ́lọ ìgbèríko di ìgboro. Bí a bá yọ ti agbègbè ààbò kúrò, nígbà mìíràn pípa ẹyẹ yìí fún oúnjẹ, ní òkè kékeré tí ó yí àfonífojì Kathmandu ká ti mú kí ẹyẹ Spiny Babbler dínkù ni iye. Síbẹ̀, ohun tí ó ń fa àdánù ní agbègbè kan náà lè mú wọn pọ̀ ní agbègbè mìíràn. Bí igbó ṣe ń dínkù látàrí ìgbẹ́ pípa àti igi gẹdú gígé jákèjádò orílẹ̀ èdè náà, igbó tí wọ́n fi ṣe ilé ti di ti nǹkan mìíràn. Àmọ́ ṣá ìgbà àti àkókò ni yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹyẹ ìlú Nepal tí kò sí ní ibòmíràn.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.