Àwọn Iléèjọsìn ní Greece àti Àríwá Macedonia kọ̀ láti yí ọwọ́ àwọn ìlànà-ìsìn wọn padà k'ó ba má fàyè gba àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 t'ó ń ràn ká

“Àjọ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa,” àwòrán tí a kùn lódà ní 1442 láti ọwọ́ Fra Angelico. Àwòrán tí kò ní olóhun láti orí Wikipedia.

Bí àwọn tí ó ti kó àrùn COVID-19 ṣe ń pọ̀ọ́ sí i ní Balkans, àwọn ilé ìjọsìn kan kò yí ọwọ́ àwọn ìlànà ìsìn tí ó lè mú kí àrùn Coronavirus ó ràn bí i pápá inú ọyẹ́ padà.

Ìlànà ìsìn tí a mọ̀ sí Jíjẹara àti mímu ẹ̀jẹ̀ Olúwa tàbí Oúnjẹ Ìkẹyìn ní èyí tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Krístì tí ó ń tẹ̀lé ìlànà ìsìn àtijọ́ yóò máa pín wáìnì tí a ti sọ di mímọ́ mu pẹ̀lú ṣíbí kan náà, àwọn Ìjọ Àgùdàá máa ń jẹ ẹ̀bẹ àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi ẹnu gbà lọ́wọ́ àlùfáà.

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) rọ̀ wá láti jìnà gbégbérégbé sí ibi tí àwọn èròó bá pitì sí, kí a sì káràmásíkì sí ìlera ara wa kí á ba dín àrànká àrùn ẹ̀jẹ̀ tí ènìyàn lè kó nípasẹ̀ ìfọwọ́kàn, ìfarakan omi tó sun lára ẹlòmíràn, àti láti inú afẹ́fẹ́.

Nínú àtẹ̀jáde ọjọ́ 9, Iléèjọsìn Àtijọ́ Greek sọ wí pé òun kò ní yí ọwọ́ ìlànà-ìsìn padà kí ó bá ìgbésẹ̀ ààbò mu. Bákan náà ni ó sọ wí pé “a kò leè kó ààrùn coronavirus láti ara Jíjẹ ara-àti-mímu-ẹ̀jẹ̀ Olúwa, àti pé kí àwọn ọmọ Ọlọ́run ó gbàdúrà gidi nítorí ààrùn apànìyàn náà.”

Bíṣọ́ọ̀pù ti GOC Klimis, ti Àárín gbùngbùn Peristeri, lábẹ́ agbègbè tó sún mọ́ Athens, sọ wí pé ọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa ni bí ẹnikẹ́ni bá sọ pé ìlànà ẹ̀sìn lè mú kí ààrùn ó ràn:

Ìyè ni Ara-jíjẹ àti ẹ̀jẹ̀ mímu. Iṣẹ́ ìyanu ni. Ọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa ni láti ní ìgbàgbọ́ wí pé ènìyàn lè tara Jíjẹ ara-àti-mímu-ẹ̀jẹ̀ Olúwa kó ààrùn.

Ènìyàn 89 ló ti lùgbàdì COVID-19 ní Greece, láìsí ẹni tó kù.

Àwọn aláṣẹ Greek, tí ó ti ṣán àwọn iléèwé pa, tí ó sì ti f'òfin de àpéjọ lójú ọ̀nà àti dènà àjàkálẹ̀, rọ Iléèjọsìn náà láti ṣe àtúnwò.

Àmọ́ àwọn aṣojú ìjọba tìkarawọn ń tàpá sí òfin ìdènà ààrùn yìí. Lọ́jọ́ ìsinmi ajẹmẹ́sìn kan lọ́jọ́ Ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ààrẹ àti àwọn onípò nínú ìṣèjọba rẹ̀ lọ sí ìsìn kan.

Ní ìlú tó múlé gbe Greece, ó jọ pé North Macedonia, Iléèjọsìn Àtijọ́ ti Macedonia – Ohrid  Archbishopric náà ń tọ ipasẹ̀ kan náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Iléèjọsìn náà kò tíì ṣe ìfilọ̀ kankan nípa àjàkálẹ̀ náà, ó sì ń fún àwọn ọmọ ìjọ ní Ara jẹ àti ẹ̀jẹ̀ mu bí ó ti máa ń ṣe.

Ìròyìn kàn nígbà tí ojúlé ibùdó ìtakùn Prespa-Pelagonia Diocese ṣe àtẹ̀jáde ògbufọ̀ article àrọko ibùdó ìtakùn tó jẹ́ ti Russia ìyẹn Pravoslavie.ru (ìtumọ̀ “Ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ Àtijọ́”) tó ń sọ wí pé “kò lè ṣe é ṣe kí àwọn onígbàgbọ́ ó k'árùn láti ara ìlànà-ìsìn ìjọ.”

Àlùfáà Sergey Adonin ti Russia ló buwọ́ lu àpilẹ̀kọ náà, ẹni tó sọ pé òun ní ìmọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ẹ̀dá oníyè àìfojúrí pẹ̀lú ìrírí iṣẹ́ ní iléèwòsàn. Ó sọ síwájú sí i nínú àpilẹ̀kọ náà wí pé lílo ṣíbí kan náà bí wọn ti ṣe fi lọ́lẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kéje ayé Bizantium ò fa ìpalára, nítorí “ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ààbò bo àlùfáà àti ọmọ ìjọ.”

Ní North Macedonia, àwọn tí ó ń mú ṣe ti ìlànà-ìsìn náà ní kò sí aburú nínú ìlànà iléèjọsìn náà. Fún àpẹẹrẹ, atọ́kùn ètò lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán tó jẹ́ adàṣà-àtijọ́-mú-ṣinṣin — ajìjàǹgbara ẹni tó ti fi ìgbà kan rí ṣe ìpolongo ìtako ìbupá — fúnnu lórí Twitter wí pé òun ti kópa nínú àwọn ìlànà-ìsìn ajẹmẹ́sìn tó léwu:

Túwíìtì: Mo jẹ Ara Olúwa mu ẹ̀jẹ̀ Olúwa lọ́jọ́ Àìkú tó kọjá nínú Iléèjọsìn Holy Annunciation tí ó wà nínú Iléèwòsàn ti Skopje tí n ó sì tún ṣe é! Kí ni ìṣòro rẹ̀?
Àkọlé adarí: Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀bẹ̀ àjọ tó ń rí sí ètò ìlera: Àwọn onígbàgbọ́ jẹ Ara mu ẹ̀jẹ̀ Olúwa láì fòyà fún ààrùn coronavirus.

Sladjana Velkov, ẹni tó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí alátakò-ìbupá tó ń ṣiṣẹ́ ní Serbia àti Àríwá Macedonia, sọ láì pẹ́ yìí wí pé nǹkan kò “le tóyẹn” àti pé “ọ̀fìnkìn lásán ni, èyí tí kò yàtọ̀ sí ọ̀fìnkìn tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, tó máa ń ṣe àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn tí ìlera ara wọn kò pé tó.”

Ní orílẹ̀-èdè Italy, níbi tí 631 ẹ̀mí èèyàn 631 ti bọ́ tí àwọn tí ó tó 10,000 ti lùgbàdì àrùn náà, aṣàmúlò kan túwíìtì:

Bí á bá kà á ní méníméjì, ó ti tó ẹni méje tí ó ti kó àrùn COVID-19 ní North Macedonia; 25 ní Slovenia; 13 ní Croatia; mẹ́fà ní Albania; fi márùn-ún ní Serbia; márùn-ún ní Bosnia; òdo ní Montenegro.

Ó ti tó ẹni 28 tó ti kó o ní Romania, mẹ́fà ní Bulgaria.

Onígbàgbọ́ níbi gbogbo

Ilé ayé ti rí bí coronavirus àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ṣe lè ràn níbi ìpéjọ ajẹmẹ́sìn.

Lóṣù tó kọjá, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó tó 7,400 ni a gbọ́ wí pé ó ti ní àrùn apànìyàn COVID-19 ní South Korea — orílẹ̀-èdè tí ó jọ pé ó ti ń gbá àrùn náà mọ́lẹ̀ — rí àrùn náà lára Iléèjọsìn ẹgbẹ́ Shincheonji ti Jésù.

A fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan ẹgbẹ́ náà — tí wọ́n máa ń pè ní igbẹ́-ìmùlẹ̀ — olórí ẹgbẹ́ náà tí í ṣe ẹni 8-ọdún wá síta láti ṣe ìtọrọ àforíjì.

Ní tirẹ̀, Àjọ Ìlànà-ìsìn Àtijọ́ ti Korea ṣe ìfilọ̀ nípa àwọn àyípadà tó dé bá ìsìn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àfilélẹ̀ Iléeṣẹ́ Ètò Ìlera:

1. Gbogbo onígbàgbọ́ yóò wọ ìbomúbẹnu lásìkò tí ìsìn bá ń lọ lọ́wọ́.

2. Kí wọ́n ó wọ Iléèjọsìn, wọ́n yóò fi apakòkòrò tó wà lẹ́nu àbáwọlé Iléèjọsìn ra ọwọ́ wọn.

3. Wọn kò ní gba ẹnìkan lọ́wọ́. 

4. Wọn kò ní f'ẹnu ko Àlùfáà ìjọ lọ́wọ́. 

5. Wọn kò ní fẹnu ko àwọn Ère, àmọ́ wọn ó tẹríba níwájú wọn. 

6. Wọn kò ní lo àwọn ìwé àdúrà nígbà ìsìn. 

7. Wọn kò ní gba Àkàrà lọ́wọ́ Àlùfáà ìjọ, àmọ́ fúnra wọn bí wọ́n bá ń jáde kúrò nínú iléèjọsìn. 

8. Oúnjẹ Àpèjẹ Ifẹ̀ kò ní jẹ́ pínpín lọ́jọ́ Àìkú.

9. Àwọn ìpàdé ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àti ti àwọn tó ń kọ́ ìsìn Ọlọ́run kò ní wáyé. 

Àwọn ilé ìjọsìn kan ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ń ṣe àyípadà sí ìlànà ìsìn wọn, bí i ìjọ Àgùdà ti Italy.

Àjọ ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ Croatia náà en ti ṣ'òfin tó dá lé àrùn náà, ní France, ibi ìrìnàjò mímọ kan ní ìlú Lourdes ti di títì pa.

Iléèjọsìn Ìlànà-ìsìn Àtijọ́ ti Romania fi òfin kan síta “tó jẹ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí ènìyàn yóò tẹ̀lé bí àjàkálẹ̀ bá dúkokò:”

Àwọn onígbàgbọ́ tíbẹ̀rùbojo àrùn apànìyàn náà ti sojo s'ọ́kan wọn yóò pa ìfènuko àwọn ère inú ilé ìjọsìn lára. Bí ó bá wù wọ́n, wọ́n leè sọ fún àlùfáà wí pé ṣíbí ti wọn ni àwọn fẹ́ lò fi gba Ẹ̀jẹ̀ Olúwa mu.

Lẹ́yìn tí Italy pàṣẹ pé kí gbogbo orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlú ó di sísé pa, àwọn alámùúlégbè, bí i Ilẹ̀ Olómìnira Czech náà gbé àwọn àgbékalẹ̀ kan lọ́jọ́ 10, oṣù Ẹrẹ́nà tí wọ́n ṣán àwọniiléèwé pa.

Ìjọba North Macedonia kéde ipò ìlú ò f'ara rọ, ó sì ti àwọn jẹ́léósinmi, iléèwé, títí kan iléèwé gíga jù lọ Ifásitìi pa fún ọ̀sẹ̀ méjì.

Check Yẹ àwọn iṣẹ́ àkànṣe Ohùn Àgbáyé lórí arapa COVID-19 lágbàáyé. 

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.