
Àwọn ọmọ ikọ̀ Èdè Ohùn Àgbáyé (Global Voices) ní ibi Ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn ará ìlú ní Cebu, Philippines. 2015. Àwòrán láti ọwọ́ Jer Clarke. CC BY-NC 2.0.
Àwọn àfinúfẹ́dọ̀ tí ó ń fi àkókò wọn sílẹ̀ láti ṣe òǹgbifọ̀ ìròyìn wa, nípasẹ̀ mímú kí àwọn ènìyàn ó ní ìmọ̀ nípa onírúurú orílẹ̀-èdè, èdè, àti àṣà ni wọ́n ń mú gbogbo àwọn ibùdó-ìtakùn wa ṣiṣẹ́.
Kí ni ìdí tí ó fi yẹ kí o darapọ̀ mọ́ wa?
Fífi inú fún ẹ̀dọ̀ ṣe atúmọ̀ àkànṣe-iṣẹ́ Lingua ní èrè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn tí ó ń finúfíndọ̀ ti sọ ní pé ọkàn àwọn máa ń balẹ̀ nítorí pé àwọn ń dá sí nǹkan rere tí ó ń mú ayé dára sí i.
Ní àfikún, àkànṣe-iṣẹ́ Èdè ń fa àwọn òǹgbifọ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè tàbí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lọ́wọ́ sókè, tí wọ́n á sì ní ẹ̀rí iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe rí, àti ìmọ̀ọ́ṣe títúmọ̀ èdè ní ìlànà àjọṣepọ̀ ọ̀pọ̀-àṣà, àrògún, ọgbọ́n àtinúdá àti àmúlò ohun-èlò bí i WordPress.
“Títúmọ̀ èdè fún [Ohùn Àgbáyé] dà bí i ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣí àwọn fèrèsé tuntun sí àgbáyé àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó pọ̀ yamùrá inú rẹ̀.” —Anna Kokkinidou, ẹni tí ó ti ṣe ògbufọ̀ fún Ohùn Àgbáyé ní èdè Greek
Àwọn òǹgbifọ̀ wa máa ń yan ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí tàbí àkórí ohun tí wọ́n kúndùn fi yan ìròyìn tí wọ́n máa tú ìmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa. Àwọn mìíràn kàn fẹ́ràn láti máa tú ìmọ̀ èdè – àkókò tí wọ́n fi ń kọ́ ọgbọ́n kún ọgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ògbufọ̀ ìròyìn. Gbogbo ìgbà tí o bá ń ṣe ògbufọ̀ ni wà á kọ́ nǹkan tuntun!
Ní àkótán, bí o bá di òǹgbifọ̀ fún àkànṣe-iṣẹ́ Èdè, o darapọ̀ mọ́ àjọ àwọn ènìyàn jákèjádò orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé àti onírúurú iṣẹ́, tí wọ́n fẹ́ fi ọgbọ́n kún ọgbọ́n nípa ilé-ayé àti ìwù láti ṣe rere. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùdásí wa ni ọ̀nà là fún nípasẹ̀ ìbáṣepọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ọmọ àjọ Ohùn Àgbáyé, irú èyí tí ì bá ti má wàáyé.
“Mo fẹ́ràn ojúṣe láti máa fi ìròyìn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ìgbèríko, tí kì í sábà bọ́ sí etígbọ̀ọ́ àwọn ènìyàn, nípa bẹ́ẹ̀, mò ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn o ní òye nípa orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé.” —Samantha Deman, ẹni tí ó ti ṣe òǹgbifọ̀ fún Ohùn Àgbáyé ní èdè Faransé

Ìpàdé Ohùn Àgbáyé 2024 ní Kathmandu.Àwòrán láti ọwọ́ Jer Clarke. CC-BY-NC
Ohun tí o gbọdọ̀ ní fún ìkópa
O ò nílò ìwé ẹ̀rí òǹgbifọ̀ tàbí ìrírí iṣẹ́ tí ó kéré jù gẹ́gẹ́ bí i òǹgbifọ̀ kí o tó darapọ̀ mọ́ wa. Bákan náà ni ó rí fún àwọn ìmọ̀ọ́ṣe ajẹmọ́ ìlò ẹ̀rọ: WordPress ni àwọn atúmọ̀ máa ń lò, nítorí náà ìmọ̀ díẹ̀ nípa bí a ṣe ń lo WordPress wúlò. Síbẹ̀, kò burú bí o ò bá mọ WordPress lò — níwọ̀n ìgbà tí o bá ti ṣe tán láti kọ́ ìmọ̀ kún ìmọ̀, a máa ń ṣe ìrànlọ́wọ́ àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́.
Ǹjẹ́ mo lè yan irú àwọn ìròyìn tí mo bá fẹ́ ṣe ògbufọ̀ rẹ̀?
Bí ó bá jẹ́ iṣẹ́ àtiléṣe, ǹjẹ́ ẹ máa ń pàdé ní ojúkorojú?
È é ṣe tí à ń tú ìmọ̀ èdè fún ara wa, nígbà tí àwọn ènìyàn lè ṣe àmúlò ohun-èlò ìfẹ̀rọṣògbufọ̀ bí i Google Translate?
Yẹ ojú ewé Àwọn Ìbéèrè Ìgbàogbo (FAQs) wa wò kí o ní òye kíkún nípa àwọn ìdí àti ọ̀nà tí o lè gbà kópa nínú àkànṣe-iṣẹ́ Èdè.
Ó kéré jù, o gbọdọ̀ ní òye èdè méjì. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni a fi ń tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìròyìn wa, torí ìdí èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àfinúfẹ́dọ̀ ni ó máa tú ìmọ̀ èdè láti Gẹ̀ẹ́sì sí èdè tí kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà mìíràn àwọn àfínnúfíndọ̀ ṣiṣẹ́ máa ń tú ìmọ̀ èdè ìròyìn tí a kọ ní èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, tàbí láti èdè mìíràn sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn bí irúfẹ́ ìròyìn bẹ́ẹ̀ bá wà.
Bí ó bá ṣe hùn ẹ́ ni o lè dá sí ìròyìn títú, kì í pọ̀ jù. A rọ̀ ẹ́ kí o tàkúrọ̀sọ pẹ̀lú Alákòóso Ògbufọ̀ rẹ, kí o sì rí i dájú wí pé gbèdéke tí ó yẹ kí o fi tú ìmọ̀ èdè ìròyìn kò kọjá, kí o sì fi àyè sílẹ̀ fún ìtọ́ni àti èsì àyẹ̀wò iṣẹ́. O gbọdọ̀ hùwà ní ọ̀nà tí ó bá Ìlànà iṣẹ́ Àjọ Ọmọ ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé mu láì yọ ẹnikẹ́ni nínú àjọ lẹ́nu.
Fi ìfẹ́ hàn wí pé o fẹ́ di àfinúfẹ́dọ̀ ṣe ògbufọ̀
Bí ó bá hùn ẹ́ láti máa tú ìmọ̀ èdè ìròyìn sí èdè Yorùbá, jọ̀wọ́ fi ọ̀rọ̀ sílẹ̀ sórí ìwé ìgbọ̀rọ̀sílẹ̀ tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Bí o bá sì jẹ́ èdè mìíràn ni o nífẹ̀ẹ́ sí láti máa finúfíndọ̀ túmọ̀ rẹ̀, jọ̀wọ́ lọ sí ibùdó-ìtakùn àkànṣe-iṣẹ́ Èdè fún àlàyé lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́.
