Ṣètọrẹ

Combination of many photos of GV contributors

Àkíyèsí: Bí ó bá ṣe é ṣe, abala ìfọwọ́sí ìṣètọrẹ owó tí ó wà ní ìsàlẹ̀ leè ṣètúmọ̀ fúnra rẹ̀ kí ó bá àtò èdè aṣàwáríkiriì rẹ dọ́gba. A tọrọ gáfárà bí kò bá tíì bá èdèe rẹ ṣiṣẹ́. O ṣeun fún àgbọ́yé.

Ṣètọrẹ lónìí

Láti ọdún-un Ohùn Àgbáyé ti ń gbéṣẹ́ ribiribi ṣe gẹ́gẹ́ bí afárá tí ó ń sọ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbogbo pọ̀, kí ohun gbogbo ba ṣe dọ́gba-ń-dọ́gba nípasẹ̀ ti èdè àti ìdáàbò bo ẹ̀ka agbéròyìn jáde tí ó sì lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba, àìpamọ́ àwọn ohun tí ó wúlò fún ọmọ aráyé lórí Ẹ̀rọ-ayélujára, ẹ̀tọ́ oníkálukú, níbi gbogbo, títí kan òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.

A ní ìgbàgbọ́ wípé iṣẹ́ pàtàkì tí a ní láti ṣe ti wá jẹ́ ohun tí a ò gbọdọ̀ fi falẹ̀, tí a gbọdọ̀ mójútó kíákíá ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Jọ̀wọ́ ṣe ìtọrẹ owó lónìí kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí.

Àwọn iléeṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìkó-èrè-jọ wa 501(c)3 ń gba ìtọrẹ, Àwọn Ọ̀rẹ́ẹ Ohùn Àgbáyé, tí kì í sanwó orí fún ìjọba U.S. PayPal máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ike ìsanwó oríṣiríṣi (o kò ní láti ní aṣàmúlò pẹ̀lú PayPal kí o tó sanwó).

Ọrẹ Tabua, Onígbọ̀wọ́ Iléeṣẹ́ Ńlá, Ìbéèrè?

Bí ó bá hùn ọ́ láti kówó tabua sílẹ̀ tàbí o fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa àwọn ọ̀nà mìíràn tí o leè gbà sanwó, jẹ́ onígbọ̀wọ́, tàbí àwọn ìtìlẹ́yìn mìíràn, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Olùdarí Àgbàa wa Ivan Sigal lóríi ivan@globalvoices.org.