Àlàálẹ̀ Ètò Global Voices

A nígbàgbọ́ nínú òmìnira ọ̀rọ̀-sísọ: dídáààbò bo ẹ̀tọ́ ọ̀rọ̀ sísọ – – àti ẹ̀tọ́ ọ̀rọ̀ gbígbọ́. A gbàgbọ́ nínú rírí àwọn irinṣẹ́ ọ̀rọ̀-sísọ lò.

Torí ìdí èyí, à ń pèsè ọ̀nà fún àwọn ènìyàn tí ó fẹ́ sọ̀rọ̀ láti wí – àti ọ̀nà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn, láti gbọ́ ọ.

A dúpẹ́ fún irinṣẹ́ tuntun, ọ̀rọ̀-sísọ ò sí lábẹ́ àkóso àwọn t'ó ní agbára ìtẹ̀ròyìn síta, tàbí ìjọba tí ń tẹrí èròǹgbà àti ìtàkùrọ̀sọ ẹni bọlẹ̀ mọ́. Ní báyìí, ẹnikẹ́ni ní agbára láti ṣe bíi oníròyìn. Ẹnikẹ́ni lè sọ ìtàn-an rẹ̀ fún aráyé gbọ́.

A fẹ́ kọ́ afárá gorí odò t'ó ń pín àwọn ènìyàn níyà, kí ọ̀rọ̀ ara wa ó ba yéra wa. A fẹ́ ṣiṣẹ́ takuntakun àti gbégbèésẹ̀ t'ó lààmìlaka.

A gbàgbọ́ nínú agbára àjọṣe. Ìfẹ́ tó so ènìyàn kọ̀ọ̀kan pọ̀ dé ọkàn, ó jẹ́ ti ìṣèlú àti pé ó sì l'ágbára. A nígbàgbọ́ wípé ìtàkùrọ̀sọ ìlú-sí-ìlú ṣe pàtàkì fún ọjọ́ iwájú olómìnira, aláìláburú, onílọsíwájú àti alágbèéró fún gbogbo ọmọ-ìlú àgbáyé.

Bí a ṣe ń tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ àti ìsọ̀rọ̀ ẹnìkànkan, a fẹ́ mọ ohun tí ó kàn wá àti bí a ṣe lè ṣ'àgbélárugẹ ìpinnu wa. A ṣe ìlérí láti bọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn, ṣe ìrànlọ́wọ́, kọ́ ara wa, àti fetí sílẹ̀ gbọ́ ara wa.

Àwa ni Ohùn Àgbáyé.