Boji rè é, Ajá tí ó máa ń jayé orí i rẹ̀ kiri ìgboro Istanbul nínú ọkọ̀ èrò

Àwọn èrò ọkọ̀ sọ pé ara rẹ̀ balẹ̀

Àwòrán láti orí móhùnmáwòrán Istanbul Metropolitan Municipality (IBB)

Boji, ajá àdúgbò kan láti ìlú Istanbul máa ń wọ ọkọ̀ èrò láti rin ìrìn-àjò káàkiri Istanbul lójoojúmọ́.

Boji tilẹ̀ ní ìkànnì Twitter àti Instagram. Ní kòpẹ́kòpẹ́ yìí, ó kí Olórí ìlú Istanbul  Ekrem Imamoglu nítorí pé ìyẹn tẹ̀ lé e lórí gbàgede Twitter.

Orúkọ rẹ̀, Boji jẹyọ láti ara ẹ̀rọ tí ó ń ti ẹsẹ̀ ọkọ̀ sí ìrìn, tí í ṣe ibi tí ó sábà máa ń fara tì, tí ó bá ti wà nínú ọkò èrò.

Ẹka ìjọba tó ń bójú tó ìlú náà, Istanbul Metropolitan Municipality (IMM) ti rí i dájú wí pé ó gba gbogbo abẹ́rẹ́ ìdèènà ààrùn tó yẹ. Kí ó tó di pé wọn ó jọ̀wọ́ọ rẹ̀ láti padà wọ àárín ìgboro, wọ́n sì ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ GPS tí ó ń mú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ka náà mọ ibi tí ó bá wà.

Gẹ́gẹ́ bí IMM ṣe sọ, ìrìn-àjò àrìn kẹ́yìn Bójì ní Istanbul tó ọgbọ̀n ibùsọ̀.

Gbajúgbajà Ajá Ìgboro Istanbul, Boji máa ń lo gbogbo àwọn ọkọ̀ ìrìnnà ti ó wà ní ìgboro ìlú náà bí i Ọkọ̀ ojú-irin abẹ́ ilẹ̀, ọkọ̀ orí ilẹ̀, ọkọ̀ orí ilẹ̀ ọlọ́pọ̀-èrò, àti ọkọ̀ ojú-omi.

Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ìlú tí ó ti agbègbè jínjìn wá ni ó máa ń ṣe alábàápàdé Boji nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n sì máa ń pín àwọn àwòrán-an rẹ̀ sórí ẹ̀rọ alátagbà.

Boji ti ní àwọn alátẹ̀lé tí ó ju 50,000 lọ lórí Twitter. Àwọn àtẹ̀jáde rẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan bóyá lórí Twitter tàbí Instagram ni ó máa ń ní àwọn kókó tí ó ń gba àwọn tí wọn ń wọ ọkọ̀ èrò níyànjú láti máa tẹ̀lé àwọn òfin ààbo ìlú.

Fún ti ààbò, Mi ò kọjá ìlà àwọ̀-ìyeyè rí. Ìwọ náà kò gbọdọ̀ kọjá rẹ̀.

Àwọn olùgbé Istanbul tí wọ́n ti pàdé Bojì, bákan náà ti sọ ìrírí wọn pẹ̀lú ajá náà:

Díẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi àsọdá, díẹ̀ awon ẹyẹ-àkẹ.

Ojúu wa dí lónìí díẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ láti Fatih, a rin ìrìn-àjò gba Bayrampasa, Basaksehir, a pàpà dé Uskudar. Àwọn ènìyàn díẹ̀ dá mi mọ̀. Nítorí náà, mo ya àwòrán-àyàfúnraẹni pẹ̀lú wọn.

Àwọn èrò ọkọ̀ tí wọ́n ti ṣe alábàápàdé Boji sọ pé ara rẹ̀ balẹ̀, kì í sì í kọjá àye rẹ̀.

Exit mobile version