Ìròyìn nípa Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara láti Ṣẹẹrẹ, 2020
Ilẹ̀-Adúláwọ̀ rí àbọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owóo dollar láti ọ̀dọ̀ Ilé-ìfowópamọ́sí ńláńlá fún ìgbéfúkẹ́ Iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá
“Nítorí àìtó ìdókoòwò ń'nú iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá àti àṣà, Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò sí ń'nú ọjà iṣẹ́ ọpọlọ, àti ìdáraáwò ní àgbáyé," Benedict Oramah, ààrẹ Afreximbank ló sọ bẹ́ẹ̀.
Twitter di pápá ìròyìn ayédèrú lásìkò Ìdìbò ọdún-un 2019 ní Nàìjíríà
Twitter di pápá ayédèrú ìròyìn ìtako ẹ̀yà kan àti ìsọkiri ṣáájú ìdìbò, lásìkò ìdìbò àti lẹ́yìn ìdìbò ti ọdún-un 2019 lórílẹ̀-èdèe Nàìjíríà
Kíni ìdí irẹ̀ tí Donald Trump ṣe l'ókìkí ní Nàìjíríà?
Ratings for US President Donald Trump’s handling of world affairs are largely negative around the world. But not in Nigeria.
Ní Kenya àti Ethiopia, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ríran ‘àwòrán-ìtọ́nà’ àt'ọ̀run wá láti gbẹ́ ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀
Láti ayébáyé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti ní kò sí ẹ̀rí tí ó dájú wípé ìran àt'ọ̀run wá ni àwọn irú àlá báwọ̀nyí, tí wọn ń dẹ́jàá ìlera ọpọlọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ tó pé òún ríran lójú àlá. Àmọ́ àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn Ìmàle, Júù àti Onígbàgbọ́ gbogboó ti jẹ́rìí sí ìran láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ent tí ó wá lójú àlá fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.
Ẹ̀rọ Alátagbà ni a fi gbé àwọn ìròyìn irọ́ àti ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹyà jáde lásìkò ìdìbò orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà
Ìbò ọdún-un 2019 orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà rí àwọn ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹ̀yà tẹ̀gbintẹ̀gbin láìròtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ẹ ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ àti ọ̀nà ìtànkálẹ̀ ìròyìn lórí ayélujára, pabambarì lóríi gbàgede Twitter.