Ìròyìn nípa Òfin
Pẹ̀lú ìdásílẹ̀ àwọn akọ̀ròyìn-in Reuters, ẹ̀ṣẹ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ṣì jẹ́ ní Myanmar

"...ẹjọ́ọ Wa Lone àti Kyaw Soe Oo jẹ́ ẹ̀rí wípé ẹ̀mí àwọn akọ̀ròyìn tí ó ń ṣe àyẹ̀wò sí ìṣèlú wà nínú ewu ìgbẹ̀san òṣèlú."
Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Brazil, ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin di ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba
Joenia ni ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil, òun sì ni agbẹjọ́rò tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ tí yóò gbejọ́rò ní Ilé-ẹjọ́ Gíga jùlọ.
Àfilé iye owó fún gbígba ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà mú àwọn ọmọ Angola fi ẹ̀hónú hàn
Iye owó ìwé ẹ̀rí náà fò sókè láti owó dollar orílẹ̀-èdè US 8 sí 97.
Jẹ́ kí àwọn òkú ó sọ ìtàn nípa Hong Kong

"Ìrìnàjò afẹ́ ìpànìyàn" tí ó ń lépa láti ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí" ìtúmọ̀ ayé àti ìgbé-àyè" ní àyìkà agbègbè orílẹ̀-èdèe Hong Kong.
‘Ẹ Yé é Pa Àwọn Òbìnrin’ – ìpolongo tuntun tí ó ń tako ìjìyà inú ìgbéyàwó ní Angola
"Violence against women is real, it really is. It is not something in the heads of feminists, it is not an invention or empty speech: IT IS REAL!"
Ìwọ́de afẹ́ àwọn abódiakọ-akọ́diabo àkọ́kọ́ lè tú èrò nípa wọn ní Pakístánì ká
The first transgender pride march seeks to change stereotypes and demand rights.
Kí ló dé tí ìjọba Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ń f'òfin de ọ̀rọ̀ sísọ orí-ayélujára? Nítorí wọ́n bẹ̀rù agbára rẹ̀.

The noise we make on digital platforms scares oppressive regimes. In some cases, it can even force them to rescind their actions.