Ìròyìn nípa Ìròyìn Ọmọ-ìlú
Ọ̀nà wo ni àrùn COVID-19 ń gbà ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣèlú àti ẹ̀yìn-ọ̀la Orílẹ̀-èdè China lágbàáyé?

Àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà Wuhan náà kì í ṣe ìkọlù ètò ìlera lásán, ó jẹ́ àkókò òtítọ́ ètò ìṣèlú tí ó lákaakì.
Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ aṣẹ̀wùtà orílẹ̀-èdè Cambodia daṣẹ́sílẹ̀ látàrí àìsan owó ọ̀yà wọn lásìkò àjàkálẹ̀ COVID-19
"A kò leè jẹ́ k'áwọn agbanisíṣẹ́ ó wí àwáwí tí yóò f'àfàsẹ́yìn fówó ọ̀yà àwọn òṣìṣẹ́, nítorí àwọn òṣìṣẹ́ ti jẹ gbèsè, wọn kò sì gbọdọ̀ jáfara láti san owó wọn."
Àwọn Iléèjọsìn ní Greece àti Àríwá Macedonia kọ̀ láti yí ọwọ́ àwọn ìlànà-ìsìn wọn padà k'ó ba má fàyè gba àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 t'ó ń ràn ká
Ìlànà ìsìn tí a mọ̀ sí Jíjẹara àti mímu ẹ̀jẹ̀ Olúwa tàbí Oúnjẹ Ìkẹyìn ní èyí tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Krístì tí ó ń tẹ̀lé ìlànà ìsìn àtijọ́ yóò máa pín wáìnì tí a ti sọ di mímọ́ mu pẹ̀lú ṣíbí kan náà, àwọn Ìjọ Àgùdàá máa ń jẹ ẹ̀bẹ àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi ẹnu gbà lọ́wọ́ àlùfáà.