Ìròyìn nípa Ìròyìn Ọmọ-ìlú láti Ògún , 2020
Àwọn ìdílé l’órílẹ̀-èdè Kenya fi ara kááṣá látàrí ipa ìfọjọ́-kún ilé-ìwé tí ó wà ní títì pa
Látàrí títì pa àwọn ilé-ìwé ní orílẹ̀-èdè Kenya, àìdọgba ti kọjá bẹ́ẹ̀. Àwọn amòye nídìí ètò-ẹ̀kọ́ fẹ́ kí ìjọba tún iná ètò-ẹ̀kọ́ dá látì lè jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ó kárí tẹrútọmọ
Ní orílẹ̀-èdè Turkey, ẹgbẹẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n jókòó ṣe ìdánwò ìgbaniwọlẹ́ sí Ifásitì
Awuyewuye wà lórí ìdáwò ọdún yìí -- kò sì kín ṣe látàri àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19.
Ní àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Assad ní ilẹ̀ Syria, àwọn alákòóso sọ báyìí pé ‘kò sí èni tí ó ní àrùn kòrónà’
Láti tẹnpẹlẹ mọ́ ìṣàkóso, sáà Assad ṣe ohun gbogbo tí ó lè ṣe ní ti ìkọ̀jálẹ̀ wí pé kò sí COVID-19 ní àwọn agbègbè tí ó wà lábẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀.