Ìròyìn nípa Ìròyìn Ọmọ-ìlú láti Igbe , 2020
COVID-19 ṣe àgbéǹde ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tó burú jáì nípa ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀
Ilẹ̀-Adúláwọ̀ 'kì í ṣe yàrá ìṣàyẹ̀wò' fún egbògi àjẹsára COVID-19. Àríyànjiyàn tí ó dá lóríi ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí ó burú jáì nípa fífi ọmọ ènìyàn ṣe ìdánwò àti fífọwọ́ọlá gbá ọmọ Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lójú.
Àwọn Ilé Iṣẹ́ ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ní Mozambique àti Cape Verde tẹ́ pẹpẹ ètò ẹ̀dínwó fún ayélujára lórí ẹ̀rọ alágbèéká láti mú kí àwọn ọmọ-ìlú ó dúró sílé
Àwọn tó ń lẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká ní Cape Verde yóò jẹ àǹfààní ọ̀fẹ́ MB 2 fún oṣù kan gbáko, lẹ́yìn tí àwọn ti Mozambique lè ra GB 5 ní 1.50 iye owó US.Cape Verdeans mobile users will have 2 MB of free data on the next 30 days, while Mozambicans could purchase up to 5 GB for 1.50 USD.Cape Verdeans mobile users will have 2 MB of free data on the next 30 days, while Mozambicans could purchase up to 5 GB for 1.50 USD.
Ọ̀nà wo ni àrùn COVID-19 ń gbà ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣèlú àti ẹ̀yìn-ọ̀la Orílẹ̀-èdè China lágbàáyé?
Àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà Wuhan náà kì í ṣe ìkọlù ètò ìlera lásán, ó jẹ́ àkókò òtítọ́ ètò ìṣèlú tí ó lákaakì.
Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà fi òfin de ìrìn-àjò lójúnà ìṣàmójútó àwọn tó ti kó kòkòrò àìfojúrí COVID 19
Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ayélujára béèrè fún ìfòfindè arìnrìnàjò láti orílẹ̀-èdè tí COVID-19 ti gbilẹ̀. Èyí á ró ojúṣẹ́ orílẹ̀-èdè sí ìtànkálẹ̀ yìí lágbára.
Ìgbàgbọ́ ọba kan nínú ewé àtegbó fún ìwòsàn COVID-19 f'ara gbún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí nígbàgbọ́ nínú ewé àtegbó fún àwòtán COVID-19. Àmọ́ fífi Ògún gbárí láìfẹ̀rìílàdìí lórí Twitter fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbárìn lè ṣini lọ́kàn — ó sì léwu — fún àwọn ènìyàn.
Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ aṣẹ̀wùtà orílẹ̀-èdè Cambodia daṣẹ́sílẹ̀ látàrí àìsan owó ọ̀yà wọn lásìkò àjàkálẹ̀ COVID-19
"A kò leè jẹ́ k'áwọn agbanisíṣẹ́ ó wí àwáwí tí yóò f'àfàsẹ́yìn fówó ọ̀yà àwọn òṣìṣẹ́, nítorí àwọn òṣìṣẹ́ ti jẹ gbèsè, wọn kò sì gbọdọ̀ jáfara láti san owó wọn."