Ìròyìn nípa Ìròyìn Ọmọ-ìlú láti Èbìbì , 2019
‘Ohùn-un Jamaica fún Àyípadà Ojú-ọjọ́’ fi orin jíṣẹ́ẹ wọn
Iléeṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba ń ṣe ìgbélárugẹ àwọn ọ̀nà tí a lè gba jẹ́ iṣẹ́ yìí nípa lílo iṣẹ́ ọpọlọ orin láti kéde nípa àyípadà ojú-ọjọ́.
Pẹ̀lú ìdásílẹ̀ àwọn akọ̀ròyìn-in Reuters, ẹ̀ṣẹ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ṣì jẹ́ ní Myanmar
"...ẹjọ́ọ Wa Lone àti Kyaw Soe Oo jẹ́ ẹ̀rí wípé ẹ̀mí àwọn akọ̀ròyìn tí ó ń ṣe àyẹ̀wò sí ìṣèlú wà nínú ewu ìgbẹ̀san òṣèlú."
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀
Ìlépa alájọpín-ìdókòòwòo wọn kì í ṣe fún ti èrè ìdókòòwò, àmọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwòo iléeṣẹ́ náà.
Ìjọba Tanzania fi Ajìjàgbara Ọmọ Orílẹ̀-èdèe Uganda sí àtìmọ́lé, wọ́n sì lé e kúrò nílùú
Human Rights Watch sọ wípé Orílẹ̀ èdèe Tanzania ti rí "ìrésílẹ̀ ìbọ̀wọ̀ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìkẹ́gbẹ́ àti àpéjọ dé ojú àmì" lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba tí ó ń tukọ̀.