Ìròyìn nípa Ìròyìn Ọmọ-ìlú láti Èrèlé , 2019
Akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Tibet-Canada rí ìkọlu lórí ayélujára lẹ́yìn tí ó já ewé olú borí nínú ìdìbò àjọ-ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́. Ó rò pé, Beijing ló yẹ á bá wí.
Chemi Lhamo dojú kọ onírúurú èsì ìdáyàjáni ní orí ẹ̀rọ-alátagbà láti ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun tí ó ń gbé ní gbùngbùn orílẹ̀-èdè China.
Olórí orílẹ̀-èdè Azerbaijan tàkùrọ̀sọ àkọ́kọ́ ní orí amóhùnmáwòrán lẹ́yìn ọdún 15 ní orí àlééfà. Ó lè lo ọ̀nà mìíràn.
"Ọ̀rọ̀ ìparíì mi: ara ò rọ ìjọba rárá!"
#FreeAmade: Akọ̀ròyìn tí a mú tí a sì dá lóró lẹ́yìn tí ó kọ ìròyìn lórí ìwà jàgídí jàgan tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Àríwá Mozambique
Àwọn ọlọ́pàá Mozambique ju akọ̀ròyìn náà sí àhámọ̀ níbi tí ó ti ń jábọ̀ ìròyìn ní Cabo Delgado
Jẹ́ kí àwọn òkú ó sọ ìtàn nípa Hong Kong
"Ìrìnàjò afẹ́ ìpànìyàn" tí ó ń lépa láti ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí" ìtúmọ̀ ayé àti ìgbé-àyè" ní àyìkà agbègbè orílẹ̀-èdèe Hong Kong.
Ta ni yóò jáwé olúborí nínú Ayẹyẹ ijó ìta-gbangba orílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019?
Orin tí ó dùn ún gbọ́ létí, ègbè tí ó ṣòro láti gbàgbé ... jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ohun idán tí ó mú orin Ijó ìta-gbangba Ìwọ́de Ojúnà Trinidad àti Tobago yàrà ọ̀tọ̀.
Pẹ̀lú àìbalẹ̀-ọkàn tí ó ń pọ̀ sí i ní ìmúra ìbò ààrẹ ọdún-un 2019, Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń bẹ̀rùu pípa ẹ̀rọ-ayélujára
Lílo ẹ̀rọ-alátagbà fún pípe àkíyèsí sí ìrúfin ìjọba àti ìwà tí kò bá òfin mu ti fa ìbẹ̀rù wípé ìtẹríbọlẹ̀ ní orí ayélujára ní àsìkò ìbò tí ó ń bọ̀.
Òwìwí kan kọ̀ kò kúrò nínú ilé ìgbìmọ̀ ìjọba Tanzania. Àmìi kí ni èyí?
The owl appeared while signing a controversial amendment limiting opposition voices in Tanzania. Could the owl be an omen signaling the death of democracy in Tanzania?
Àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wọ̀yáàjà láti nípa lórí ètò ìdìbò ọdún-un 2019
Olusegun Obasanjo, former military head of state and later Nigeria’s democratically elected president, has consistently criticized successive governments in Nigeria.
Spiny Babbler, ẹyẹ orílẹ̀-èdè Nepal, fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ mọ́ra
Ẹyẹ Spiny Babbler, tí ó wà ní Nepal nìkan, ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ káríayé mọ́ra. Oko ríro fún iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìsọ̀gbẹ́dìgboro ti ń dá ẹ̀míi rẹ̀ ní ègbodò.
Ìjà láàárín ìràwọ̀ akọrin soca Trinidad àti Tobago jẹ́ àmì tí ó dára fún orin àtijọ́
ìforinjìjà tí kò dénú ni a ti rì bọ inú orin Calipso láti orísun, èyí kò yàtọ̀ nínú àdàlùu rẹ̀ tí í ṣe soca ìgbàlódé.