Àṣẹ̀sẹ̀tẹ̀jáde ìròyìn látọwọ́ọ Àlàbí Orítóókẹ́
Òṣìṣẹ́ wà lóòrùn, ẹni tí ó jẹ ẹ́ wà níbòji ni ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wá ìwòsàn sí ìpèníjà ara àti àwọn olórí ẹ̀sìn ní Nàìjíríà.
“Ṣàdédé ni àwọn ọkùnrin méjì kan wọ́ mí lọ sí orí pèpele láti jẹ́rìí pé ojú mi ti là, wọ́n fi ipá mú mi pa irọ́ .”
Àwọn Obìnrin ti ní àǹfààní sí ogún jíjẹ lábẹ́ òfin o, síbẹ̀ ẹnu àwọn obìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà kò tólẹ̀ lóri níní ìpín nínú ilẹ̀ pínpín.
"Àwọn ìjọba ò ní ẹ̀tọ́ látí fi ipá mú wa pé kí a máa fún àwọn ọmọbinrin wà ní ilẹ̀ nìtorí pe ọmọbìnrin á lọ sílé ọkọ..."