Àṣẹ̀sẹ̀tẹ̀jáde ìròyìn látọwọ́ọ Simeon Ọ̀nàọlápọ̀
Ìdílé Kútì tí ń fẹ̀hónúhàn nípasẹ̀ orin àti àwọn ọmọ Nigeria mìíràn tí wọ́n kọrin táko ẹlẹ́yàmẹ̀yà
Àwọn ìdílé Kútì ti gbógun ti àwọn adarí burúkú nípasẹ̀ orin. Bákan náà, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria bí Sonny Okosun, Majek Fashek àti Onyeka Onwenu jà láti rí i pé wọ́n dá Nelson Mandela sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.