Ìròyìn láti Ṣẹẹrẹ, 2023
Bí ikọ̀ àgbábọ́ọ̀lù Atlas Lions ti Morocco ṣe fi ìtàn balẹ̀ nínú ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé 2022
Ikọ̀ àgbábọ́ọ̀lù Morocco, Atlas Lions ni ikọ̀ àgbábọ́ọ̀lù àkọ́kọ̀ ní ilẹ̀ Áfríkà àti ilẹ̀ Lárúbáwá tí yóò kọ́kọ́ dé ìpele tí ó kángun sí ìparí nínú ìdíje Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé.
‘Ìkòròdú bois’ ṣàfihàn bí àwọn gbàgede ẹ̀rọ-ayélujára ṣe ń ṣe ìgbélárugẹ àwọn eré àgbéléwò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà káàkiri àgbáyé
Pẹ̀lú irinṣẹ́ tí kò tó àti àwọn àmúlò irinṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, ikọ̀ ‘Ìkòròdù Bois’ ṣe ìsínjẹ àti àwàdà àwọn eré Hollywood àti Nollywood tí ó ti di èrò yà wá á wò ó kárí ayé lórí àwọn gbàgede ìbáraẹnidọ́rẹ̀ẹ́.
Ìdílé Kútì tí ń fẹ̀hónúhàn nípasẹ̀ orin àti àwọn ọmọ Nigeria mìíràn tí wọ́n kọrin táko ẹlẹ́yàmẹ̀yà
Àwọn ìdílé Kútì ti gbógun ti àwọn adarí burúkú nípasẹ̀ orin. Bákan náà, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria bí Sonny Okosun, Majek Fashek àti Onyeka Onwenu jà láti rí i pé wọ́n dá Nelson Mandela sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Olórin Calypso Trinidad àti Tobago, Black Stalin, àwòkọ́ṣe ‘ọkùnrin Caribbean,’ jáde láyé ní ẹni Ọdún 81
Ògbó aládàánìkàn ronú tó gbóná àti olùpilẹ̀sẹ̀ ọ̀rọ̀ orin, ní gbogbo ìlàkàkà rẹ Stalin gbìyànjú láti jẹ́ kí ohun gbogbo lọ déédé.
Orin ẹ̀hónú: àwọn ọ̀dọ́mọdé òǹkọrin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kọrin tako ìwà ìrẹ́jẹ láwùjọ
Àwọn ọ̀dọ́mọdé olórin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tẹ̀síwájú nínú àṣà kíkọ orin tako ìrẹ́jẹ láwùjọ. Èhónú #EndSARS ṣe ìtanijí ọkàn wọn sí ìkópa nínú ètò òṣèlú, eléyìí tí ó ti ń wòòkùn.