Ìròyìn láti Ọ̀pẹ, 2022
Fún Ayẹyẹ Àìsùn Ọdún Tuntun àwọn Ilé-Ìwé ní Moscow, àwọn orin kan ò bójúmu
Ní àpapọ̀, àtòjọ náà ní àwọn olórin àti ẹgbẹ́ eléré 29. Díẹ̀ nínú wọn, bíi Little Big àti Manizha, ti ṣojú orílẹ̀-èdè Russia rí ní ìdíje Eurovision fún ọdún púpọ̀ látẹ̀yìnwá. Gbogbo wọn pata ni wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù orílẹ̀-èdè Russia sí Ukraine ní gbangba
Àwọn àjòjì tí wọ́n gba òmìnira sọ ìrírí wọn ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Myanmar
"Mà á fẹ́ láti ṣàtẹnumọ́ pé àwọn tí kò nífọ̀n-léèékánná lọ̀pọ̀ àwọn olùfaragbá ìyà àwọn ológun, èyí tí ó sì ń tẹ̀síwajú."