Ìròyìn láti Ẹrẹ́nà , 2020
Àwọn Iléèjọsìn ní Greece àti Àríwá Macedonia kọ̀ láti yí ọwọ́ àwọn ìlànà-ìsìn wọn padà k'ó ba má fàyè gba àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 t'ó ń ràn ká
Ìlànà ìsìn tí a mọ̀ sí Jíjẹara àti mímu ẹ̀jẹ̀ Olúwa tàbí Oúnjẹ Ìkẹyìn ní èyí tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Krístì tí ó ń tẹ̀lé ìlànà ìsìn àtijọ́ yóò máa pín wáìnì tí a ti sọ di mímọ́ mu pẹ̀lú ṣíbí kan náà, àwọn Ìjọ Àgùdàá máa ń jẹ ẹ̀bẹ àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi ẹnu gbà lọ́wọ́ àlùfáà.
Sísọnù sínú ògbufọ̀: Ìdí tí Atúmọ̀ Google ṣe ń kùnà — nínú títúmọ̀ èdè Yorùbá — àti àwọn èdè mìíràn
Bí àwọn iléeṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe ń gbìyànjú láti mú kí ògbufọ̀ èdè wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún onírúurú èdè lórí ayélujára, ni àríyànjiyàn àti ìpèníjà ń gbérí — pàápàá jù lọ ti àṣe déédéé àti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́pọ̀ ìtumọ̀.
Ọ̀rọ̀ àyálò nínú èdè Yorùbá: Bí èdè ṣe yí padà
Lílo àwọn ojúlówó ọ̀rọ̀ èdè Yorùbá pọ́nbélé máa ń mú kí àṣà — ó gbòòrò — tí yóò sí máa gbilẹ̀.
Olóyè yìí nírètí wí pé àwọn ọmọ Yorùbá yóò tẹ́wọ́ gba ‘alífábẹ́ẹ̀tì t'ó ń sọ̀rọ̀’ tí òun hu ìmọ̀ rẹ̀
Kíkọ Yorùbá nílànà Látíìnì yóò di àfìẹ́yìn láì pẹ́ nítorí ọmọ káàárọ̀-o-ò-jí-ire kan, Olóyè Tolúlàṣẹ Ògúntósìn, ti hùmọ̀ ìlànà ìṣọwọ́kọ tuntun fún kíkọ èdè Yorùbá