Ẹ̀san òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ: Ohùn àwọn ọ̀dọ́ ní Mozambique

A group of men during a peaceful protest; one of them holds a microphone and a banner.

Àgbáríjọ àwọn ọkùnrin ní àsìkò ìfẹ̀hónúhàn àláìfawàhálà; ọ̀kan nínú wọn mú gbohùngbohùn àti àsíá dání. Ẹni tí ó ya àwòrán ni Stephanie Douglas. Nàìjíríà. Láti orí Pexels. Àṣẹ ẹ̀dà Pexels.

Ní Mozambique, òfin lórí Ẹ̀tọ́ sí Ìwífún No. 34/2014 ni ó ń ṣàkóso òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ̀tọ́ kan tí ó wà ní Abala 48 nínú Ìwé Òfin Orílẹ̀-èdè Olómìnira Mozambique. Síbẹ̀, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́, sísọ́ ọ̀rọ̀ ní gbangba nípa ìwà ìbàjẹ́, àìdọ́gba ará ìlú, ìwà ipá àwọn ọlọ́pàá, tàbí wíwẹ̀-mọ́-yán-kànkàn sí iṣẹ́ ẹni ṣì túbọ̀ ń mú ewu wá, èyí tí ó fi àlàfo tí ó wà láàárín ìlérí ìjọba tiwa-n-tiwa àti ìrírí ojoojúmọ́ hàn.  

Nínú orin, fún àpẹẹrẹ, ìtakora yìí hàn kedere. Ní nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn, orin tàkasúfèé ti di àyè pàtàkì fún àwọn ọ̀dọ́ ìgboro ń lò láti sọ̀rọ̀ ìbáwí nípa ohun tí ó ń lọ láwùjọ, pàápàá ní Maputo, tí ó jẹ́ olú-ìlú. Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ oríṣi orin, lápá kan, orin tàkasúfèé ti di ọ̀nà láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àníyàn ìran kan tí ó gbọ́njú bá ìṣèlú ìjẹgàba ìjọba tiwa-n-tiwa àti ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú púpọ̀ láti bí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, ṣùgbọ́n tí a bá wò ó lọ́nà mìíràn, àìríṣẹ́ṣe tí ó pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́, àìdọ́gba nínú ọrọ̀-ajé, àti àìgbẹ́kẹ̀lé tí ó ń peléke sí i nínú àwọn iléeṣẹ́ ìjọba tí ẹgbẹ́ òṣèlú FRELIMO tí ó wà lórí ipò lọ́wọ́ ń darí. 

Nípasẹ̀ àwọn ìtàn inú orin, àwọn ẹgbẹ́ bí i GPRO àti àwọn olórin bí i Azagaia ṣẹ̀dá èdè kan tí ó ṣàfihàn ìrírí ojoojúmọ́ àwọn ènìyàn ní ibi gbangba àti àwọn ibi ilé-iṣẹ́ ìjọba. Bóyá ìbéèrè tí Azagaia béèrè nínú orin “O ciclo da Censura” (Òbìrìkìtì Ìkánilọ́wọ́kò Ọ̀rọ̀ Sísọ) ṣì bá ìgbà mu: “Ta ni ó sọ pé òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ wà ní orílẹ̀-èdè yìí?” Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí ó rú inú ti iṣẹ́-ọnà lásán. Ó jẹ́ àfihàn ipò ọrọ̀-ajé àti ti ìṣèlú ti ó ń pinnu ẹni tí ó lè sọ̀rọ̀, nípa kí ni, àti pẹ̀lú ohun tí yóò jẹ́ àbájáde.

Àwọn ọ̀nà tuntun ìjẹ́ ọmọ-ìlú

Àwọn ọ̀dọ́ Mozambique tún ti ń wá àwọn ọ̀nà tuntun láti kópa nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, jíjẹ ọmọ-ìlú ní àsopọ̀ tó nípọn pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn àjọ ìjọba, lónìí ó tún ń jẹ yọ káàkiri àwọn àjọ mìíràn bí i àwọn ẹgbẹ́ obìnrin ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin bíi Ẹgbẹ́ àwọn Obìnrin (Woman’s Forum), ojú òpó orí ẹ̀rọ ayélujára fún ṣíṣe àbójútó ìṣàkóso ìjọba ìbílẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ àṣà, àti àwọn ètò iṣẹ́ ọnà. Àyípadà yìí fi ìran kan hàn tí kò gbà pé kí òṣèlú dúró lórí ìdìbò nìkan, tí ó sì béèrè fún ẹ̀tọ́ láti máa kópa nígbà gbogbo nínú ṣíṣe àgbékalẹ̀ àwọn àyè gbogbo ènìyàn.

Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà ìkópa tuntun yìí má ń forígbárí lọ́pọ̀ ìgbà pẹ̀lú àwọn aláṣẹ tí wọ́n ṣì ń wo ìfẹ̀hónúhàn gẹ́gẹ́ bí ìdínà ìfararọ àwùjọ. Ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ málegbàgbé tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2016, nígbà tí àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin gba ìgbòrò kan láti fẹ̀hónúhàn lòdì sí ìfòfinde síkẹ́ẹ̀tì péńpé ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba. Wọ́n gbé ìgbésẹ̀ náà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn sí ìfìyàjẹni ní ọ̀nà ìbálòpọ̀, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pe aṣọ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin yàn láti wọ̀ ni ohun tí ó ṣokùnfà ìpalára tí wọ́n ń rí.

Nípa nína ìka àléébù sí àwọn ọmọbìnrin náà dípò àwọn tí wọ́n hu ìwà ipá sí wọn, àríyànjiyàn náà tú ohun kan tí ó jinlẹ̀ síta: ìjà nípa ìṣàkóso ara obìnrin àti ẹ̀tọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti ṣàláyé ẹni tí àwọn fúnra wọ́n jẹ́. Nígbà àwọn ìfẹ̀hónúhàn náà, wọ́n ti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ Spain, Eva Anadón Moreno mọ́lé, lẹ́yìn náà wọ́n sì lé e kúrò ní Mozambique fún kíkópa nínú ìfẹ̀hónúhàn náà. 

Ìdákẹ́jẹ́ náà jẹ́ ti òṣèlú

Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìkálọ́wọ́kò ọ̀rọ̀ ní Mozambique kì í sábàá wá ní ìrísí àwọn ìdínà tó hàn gbangba. Síbẹ̀síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé kò sí ìbẹ̀rù àti ìkálọ́wọ́kò ara ẹni rárá. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ní ọdún 2010, Azagaia ṣe àkíyèsí pé ìdínà ńlá sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní Mozambique kì í ṣe ti ìhàlẹ̀ ti àwọn ọlọ́pàá, bí kò ṣe àìṣedéédéé ètò ọ̀rọ̀ ajé. Nígbà tí ọ̀pọlọpọ̀ àǹfààní iṣẹ́ bá gbára lé, ganran tàbí láì ṣe ganran, ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n ní agbára tó ti fìdí múlẹ̀, ìtakò ẹni ní gbangba lè fi àwọn ènìyàn sínú ewu.

Èyí ń yọrí sí ohun tí a lè pè ní “A kì í dákẹ́ ká ṣì wí”. Àwọn akọ̀rọ̀yìn ń yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ kan, àwọn olórin ṣẹnu wọn ní déédéé ṣíbí, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba fi èrò wọn sínú, tí àwọn ajìjàgbara ọ̀dọ́ sì kọ́ pé ẹyin lohùn. Òmìnira kúrò ní ọ̀rọ̀ òfin lásán ó sì di ọ̀rọ̀ ìwàláàyè. Ní irú àsìkò báyìí, orin ìfẹ̀hónúhàn jẹ́ ohun ìkojú ìjà sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú kan. Ó fòpin sí ìdákẹ́jẹ́jẹ́ gbogbogbòò ó sì ń ṣe ìdàgbàsókè àwọn àwùjọ tó mọ iyì ìdámọ̀ ara ẹni, níbi tí àwọn tí ó ni1 ìrírí àìṣòdodo ti rí ìpèdè, ìrántí, àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀.

Ìrújú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ

Ìwé òfin orílẹ̀ èdè Mozambique fìdí ẹ̀tọ́ gbogbo ọmọ-ìlú sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti èrò ọkàn múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀tọ́ tí ó wà nínú ìwé lásán kọ́ ní a fi ń ṣe òṣùwọ̀n ìjọba tiwa-n-tiwa, bí kò ṣe ọ̀nà gigi tí a lè gbà lo àwọn ẹ̀tọ́ náà. Ìrújú òmìnira wà nínú ìtakora yìí: a ń sọ fún àwọn ọmọ-ìlú pé kí wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn lè sọ̀rọ̀ fàlàlà-falala, nígbà tí àwọn ọ̀nà tí ó jẹ́ ti abẹ́ òfin fún amí ṣíṣe, ìdẹ́yẹsí, àti ìyasọ́tọ̀ ń dín iye ẹni tí ó lè kópa nínú ibi ìta gbangba kù. Kò pọndandan ni láti pa gbogbo ènìyàn lẹ́nu mọ́; ipa ìpohùn mọ́ ẹni lẹ́nu tó láti mú kí ìbẹ̀rùbojo ó gba ọkàn gbogbo ènìyàn po láti má lè sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn, bí i, fún àpẹẹrẹ, kí owó ìlo ìbánisọ̀rọ̀ gbówó lórí ju bí ó ti yẹ lọ. 

Ní irú ipò yìí, ìjàgbara àwọn ọ̀dọ́ ṣàpẹẹrẹ ìdàrúdàpọ̀ ìrònú méjì yìí. Wọ́n ń fún àwọn ti a pohùn mọ́ lẹ́nu lóhùn, wọ́n sì ń jẹ́ kí wọ́n hànde. Bí agbára olórin, ajìjàgbara, tàbí ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ láti kó àwọn ènìyàn jọ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni agbára ìdẹ́rùbà, ìròyìn irọ́, tàbí ìyasọ́tọ̀ ọ̀rọ̀-ajé ṣe ń pọ̀ sí i.

Gbígbé ohùn àwọn ọ̀dọ́ sókè

Pẹ̀lú àwọn ìpèníjà náà, àwọn ọ̀dọ́ ń tẹ̀síwájú láti ṣẹ̀dá àwọn ọ̀nà ìrètí òṣèlú tuntun. Iṣẹ́ ọnà, orin, àti ìjàgbara orí ẹ̀rọ ayélujára fi hàn pé ìjẹ́ ọmọ-ìlú kì í ṣe ipò abẹ́ òfin nìkan, bí kò ṣe ìṣe ojoojúmọ́ ti ìkópa, ìfojúinúwò, àti ìkọjú-ìjà-sí. Ìpènijà dídá ààbò bo àwọn ọmọ Mozambique kì í ṣe òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìwé òfin nìkan, bí kò ṣe ṣíṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ìlànà fún gbogbo ènìyàn láti lè lò ó láì bẹ̀rù ẹ̀san ọ̀rọ̀-ajé, ti àwùjọ, tàbí ti òṣèlú. Ìbéèrè pàtàkì fún Mozambique kì í ṣe bóyá àwọn ọ̀dọ́ lè sọ̀rọ̀ nìkan, bí kò ṣe bóyá wọ́n lè sọ̀rọ̀ láì fi ààbò wọn, iṣẹ́ wọn, tàbí agbára wọn láti kópa nínú ìgbésí ayé gbogbo ènìyàn sínú ewu.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.