Nígbà tí rédíò rí ohùn orí ayélujára tuntun: Mímú àṣà àti ìṣe Romani wá sí orí afẹ́fẹ́ ní Kosovo.

 

Radio Romano Avazo

Rédíò Romano Avazo. Ìṣẹ̀dá nípasẹ̀ Canva Pro.

Durmish Aslano ni ó ṣe àpilẹ̀kọ yìí jáde láti Rédíò Romano Avazo nípasẹ̀ ètò ìrànwọ́ Digital Spark, gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ àkànṣe Ètò Àtìlẹyìn Ìgbèríko EECA, tí Àjọ Metamorphosis àti TechSoupń ṣe, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀  CIVICUS lábẹ́ Ètò Àwarawa Orí ayélujára (DDI) fún àwọn orílẹ̀ èdè Gúúsù Àgbáyé. À ń tẹ̀ ẹ́ jáde lórí Global Voices gẹ́gẹ́ bí ara àdéhùn pínpín-àkóónú.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Rédíò Romano Avazo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àyè díẹ̀ tí a ti lè gbọ́ èdè àti àṣà Romani léraléra ní Kosovo. Nínú ṣíṣe ìgbohúnsáfẹ́fẹ́ láti Prizren, iléeṣẹ́ rédíò àgbègbè náà tí ṣètò àkóónú ètò fún àwọn olùgbọ́ Roma tí kò fi bẹ́ẹ̀ ni àǹfààní sí ayélujára ní èdè abínibí wọn.

Ṣùgbọ́n bí ìkànnì ìgbéròyìn jáde ṣe ń gbèrú sí i lórí ayélujára, ìbéèrè kan tí kò ṣé fojú fò di dandan: Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àkóónú ètò lédè Romani tí ìgbohúnsáfẹ́fẹ́ orí rédíò bá pin?

Nípasẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe “Ohùn Ayélujára Romani: Àká Fọ́nránhùn fún Ìkópa gbogbo-gbòò”,  Rédíò Romano Avazo gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì láti dáhùn ìbéèrè yẹn nípa ṣíṣe ètò àṣà tí ó ti ní tẹ́lẹ̀ sí àká fọ́nránhùn, léyìí tí ó sì ń ṣe ìfarahàn orí ayélujára fún àwọn àkóónú ohùn lédè Romani lórí Spotify, Apple Podcasts, YouTube àti ojú òpó tirẹ̀.

Iṣẹ́ àkànṣe yìí ju àgbéga ìmọ̀ ẹ̀rọ lásán lọ. Ó jẹ́ akitiyan láti dí àlàfo tí ó ti sọnù ní agbègbè Roma ní Kosovo: Àyè orí afẹ́fẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ níbi tí èdè Romani, àṣà, àwọn ìtàn, àti àwọn ohùn yóò máa wà tí àwọn ènìyàn yó sì máa rí àyè sí i nígbàkúùgbà àti níbi gbogbo.

Láti ìgbohúnsáfẹ́fẹ́ orí rédíò sí ibi ìpamọ́ orí ayélujára tí kò ní parẹ́

Látilẹ̀ ètò orí rédíò má ń dálé àkókò kan pàtó. Tí àwọn olùgbọ́ kò bá ráyè nígbà tí ètò ń lọ lọ́wọ́, ètò náà le fò wọ́n ru. Ìdíwọ́ yìí kan ètò  “Gjuha dhe Kultura” (Èdè àti Àṣà) ti iléeṣẹ́ náà ní pàtó, èyí tí àkóónú rẹ̀ jẹ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àti àwọn ìtàn tí ó yẹ kí a máa rí àǹfààní sí i ju ìgbohúnsáfẹ́fẹ́ ẹ̀ẹ̀kan lọ. Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni ó mú àyípadà bá ìlànà yẹn.

Wọ́n yan ìpín ètò mẹ́ta tí ó ṣe kókó, wọ́n sì ṣe àtúngbékalẹ̀ wọn ni àká fọ́nránhùn, èyí tí ó fún àwọn olùgbọ́ láyè láti gbọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́. Ìyípadà pàtàkì ni èyí jẹ́ fún iléeṣẹ́ ìròyìn agbègbè kékeré: Láti ṣíṣe ètò tó ń parẹ́ lẹ́yìn ìgbéròyìnjáde sí ṣíṣẹ̀dá ibi ìpamọ́ ayélujára tí gbogbo ènìyàn lè rí àyè sí, fún ohùn àti ìmọ àṣà àwọn ará Romani.

Ìtàn mẹ́ta, ẹni mẹ́ta, èdè kan

Ní ààrin gbùngbùn iṣẹ àkànṣe náà ni àwọn ìjíròrò pẹ̀lú àwọn gbajúgbajà ènìyàn mẹta, tí ẹnì kọọkan wọn sì ti dá sí èdè, àṣà àti ìgbé ayé Romani ní oríṣiríṣi ọ̀nà.

Ìpín ètò àkọ́kọ́, “Skolatar ani Bibloteka”(Láti inú Yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ sí Yàrá ìkàwé), tí Urma Menekshe, olùkọ́ èdè Romani ní Prizren àti olùdásílẹ̀ Yàrá Ìkàwé kékeré Roma jẹ́ àlejò. Ó tún jẹ́ ọ̀ǹkọ̀wé àti atúmọ̀ èdè.

Ìtàn rẹ̀ ṣe àsopọ̀ ẹ̀kọ́, àwọn ìwé, àti ìdábòbò èdè, ó sì ń ṣàfihàn pé èdè kò kàn wá láti ara ibì kan, nítorí pé ó ń jẹyọ nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, ní àwọn yàrá ìkàwé, láàrin ẹbí, àti ìjíròrò ojoojúmọ́.

Ìpín ètò kejì, “Artesta ani Politika”(Láti Iṣẹ́ ọnà sí Ìṣèlú), jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu Sejnur Veshall, ẹni tí ó jẹ́ olóṣèlú àti igbákejì mínísítà tẹ́lẹ̀ rí ní ẹ̀ka tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ àṣà, bákan náà ó sì tún jẹ́ òṣèré àti akéwì.

Ìrírí rẹ̀ fún ní àǹfààní láti ṣe àgbéyèwò ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin àṣà àti ìgbé ayé, tí ó sì tún mẹ́núba àwọn ìṣòro tí ó ń kojú àgbègbè Roma, kò sì sàì sọ̀rọ̀ lórí pàtàkì ṣíṣe àtìlẹyìn tó nípọn fún àṣà àti èdè Romani ní Kosovo.

Ìpín ètò kẹta, “Kulturatar ani Televizia”(Láti Àṣà sí Orí amóhùnmáwòrán), tí Daut Qulangjiu ti jẹ́ àlejò. Òun ni olótùú yàrá ìròyìn èdè Roma ní RTK, bákan náà ó tún jẹ́ oníjó nígbà kan rí, olùpamọ́ àṣà àti ìṣe, àti òṣèré sì ni.

Ìrìnàjò ayé rẹ̀ jẹ́ àdàpọ̀ àṣà ìbílẹ̀, iṣẹ́ ọnà ìdárayá, ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀, àti amóhùnmáwòrán, èyí tí ó fún àwọn olùgbọ́ ní àǹfààní láti mọ bí àṣà Roma ti ṣe gbèrú sí i àti bí yóò ṣe máa rí àyè gbilẹ̀ sí i ní ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tòní.

Ọ̀kan lára àǹfààní ohùn orí afẹ́fẹ́ náà ni ìhà ènìyàn tí wọ́n gbé wọ̀ ọ́.

Àwọn ìjíròrò náà kò fi mọ lórí ìbéèrè lásán nípa èdè, àṣà tàbí àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ nìkan. Ó tún fún àwọn olùgbọ́ ní àǹfààní láti mọ̀ nípa ìwà àwọn ènìyàn tí wọ́n di ipò ìlú mú.

Ọ̀nà yìí tún bá wọn yí àwọn abala ètò náà padà kúrò ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìgbà gbogbo sí ìjíròrò tí àwọn olùgbọ́ ní òye rẹ̀.

Bákan náà, àwọn àlèjò náà wá sọ ìwòye àti àbá wọn lórí bí ìyípadà ṣe lè dé bá ipò tí àwọn Roma wà, pàápàá jùlọ lórí ọ̀rọ̀ èdè àti àṣà.

Àyè orí afẹ́fẹ́ tí àwọn èèyàn ti ń gbáradì fún 

Ẹ̀rí tí ó fi pàtàkì iṣẹ́ àkànṣe náà hàn jù farahàn ní kété tí a gbé àwọn àkóónú náà jáde.

Wọ́n ṣe ìpolówó àwọn àká fọ́nránhùn náà pẹ̀lú àwọn àwòrán tí a fẹ̀rọ yà, tí wọ́n sì pín wọn káàkiri àwọn ọnà ìbánisọ̀rọ tí àwùjọ Roma ti ń lò tẹ́lẹ. Àbájáde rẹ̀ sì lágbára ju bí wọ́n ti lérò lọ.

Àwọn olùgbọ́ Roma láti àwọn ìgbèríko yòókù yàtọ̀ sí Prizren bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè bí àwọn náà ṣe le rí ọ̀nà láti máa gbọ́ àwọn abala àká fọ́nránhùn náà.

Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ní àpẹẹrẹ.

Wọ́n fi hàn pé ìṣòro náà kì í ṣe àìnífẹ̀ẹ́ sí ètò orí afẹ́fẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, wọn kò tíì ri ètò èdè Romani tí ó gbéwọ̀n tó ni.

Wọ́n tún ṣe àwọn àká fọ́nránhùn nàá lọ́nà tí yóò fi máa kọjá Kosovo. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti wà lóri àtẹ àgbáyé, àwọn tí ó ń sọ èdè Romani ní òkè òkun — láti ilẹ̀ Yúróòpù àti ju bẹ́ẹ̀ lọ — lè rí àyè sí àwọn ìtàn àti ìjíròrò ní èdè wọn.

Fún àwùjọ tí èdè wọn kò mọ sí ààlà orílẹ èdè kan, èyí ṣe àǹfààní láti jẹ́ kí ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán wà láàrin olùgbé Roma ní Kosovo àti àwọn ẹniyan Roma tí ó ń gbé ní ibòmíràn.

Òṣùwọ̀n ipa tí ó kọjá òǹkà  

Iṣẹ́ àkànṣe náà ṣe àlàkalẹ̀ fún ìdàgbàsókè àwọn olùgbọ́, kí ó lè kọ́já gbígbọ́ tí ó kọjá ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbà àti àwọn olùtẹ̀lé tuntun tí ó kọjá igba, bí wọ́n ṣe ń gbèrò láti ṣe ìdásílẹ̀ ẹ̀ka àká fọ́nránhùn alálòpẹ́ ni ojú òpó Rédíò Romano Avazo.

Èsì tí wọ́n ti gbà tẹ́lẹ̀ fihàn pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí i gidi, bí ètò náà ṣe ń ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún wíwò/gbígbọ́ káàkiri àwọn ìkànnì orí afẹ́fẹ́ wọn dí àsìkò yìí.

Bẹ́ẹ̀, a kò lè ṣe òṣùwọn ipa iṣẹ́ àkànṣe yìí nípasẹ̀ òǹkà lásán.

Èèyàn tuntun tí ó bá ń ṣe àwárí àká fọ́nránhùn èdè Romani jẹ́ ọ̀nà mìíràn fún èdè náà láti di gbígbọ́ káàkiri. Ènìyàn kọ̀ọ̀kan tí ó bá ń pin abala ètò kan pẹ̀lú ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ ń ṣe ìrànwọ́ fún ìtànkálẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni, èyí ń jẹ́ ìrántí fún ọ̀dọ́ Roma kọ̀ọ̀kan tí ó bá ń ṣe alábàápàdé èdè àti àṣà rẹ̀ ní ìlànà ìgbàlódé orí afẹ́fẹ́ pé èdè Romani náà ní àyè lórí àwùjọ ayélujára.

Ìrírí yìí fihàn pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìyípadà ọ̀tun ma ń nílò ohun amáyédẹrùn olówó iyebíye tàbí ọ̀nà àbáyọ tí ó le. Fún ẹ̀ka ìbánisọ̀rọ̀, ó lè bẹ̀rẹ̀ nípa mímú ètò tí ó wúlò tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì fún ní ìgbà pípẹ́ sí í. Iṣẹ́ àkànṣe náà tún fi hàn pé àwọn olùgbọ́ wà fún ètò èdè Romani lórí ayélujára.

Ìṣòro tí ó tún kàn ní ìmúró-kárinkése.

Ẹ̀ka àká fọ́nránhùn náà ní ojú òpó Rédíò Romano Avazo lè di ilé ayérayé fún àwọn ìpín ètò ọjọ́ iwájú, ìjíròrò lórí àṣà, àti àwọn ìgbéjáde èdè Romani mìíràn. Àká fọ́nránhùn mẹ́ta ti tẹ́lẹ̀ le dàbí ìpìlẹ̀ fún ibi ìpamọ́ ńlá lórí ayélujára, ó sì jẹ̀ ọ̀nà tí ó gbòòrò fún bíbá àwọn ọ̀dọ́, obìnrin, ìgbèríko agbègbè Roma àti àwọn Roma tí ó wà lẹ́yìn odi sọ̀rọ̀.

Ní pàtàkì jùlọ, iṣẹ́ àkànṣe náà ti ṣàfihàn pé dídá ààbò bo èdè àti ìkópa orí ayélujára lè kọ́wọ̀ọ́ rìn.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.